Àìsáyà 41:1-29

  • Aṣẹ́gun kan láti ìlà oòrùn (1-7)

  • Ọlọ́run yan Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ òun (8-20)

    • “Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi” (8)

  • Ó pe àwọn ọlọ́run míì níjà (21-29)

41  “Ẹ dákẹ́, kí ẹ sì fetí sí mi,* ẹ̀yin erékùṣù;Kí àwọn orílẹ̀-èdè pa dà ní agbára. Kí wọ́n sún mọ́ tòsí; kí wọ́n wá sọ̀rọ̀.+ Ẹ jẹ́ ká kóra jọ fún ìdájọ́.   Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,*Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+ Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?   Ó ń lé wọn, ohunkóhun ò sì dí i lọ́wọ́Lójú ọ̀nà tí kò fẹsẹ̀ tẹ̀ rí.   Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni,Tó ń pe àwọn ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi Jèhófà, ni Ẹni Àkọ́kọ́;+Èmi kan náà ni mo sì wà pẹ̀lú àwọn tó kẹ́yìn.”+   Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù sì bà wọ́n. Àwọn ìkángun ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wárìrì. Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì bọ́ síwájú.   Kálukú ń ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́,Wọ́n ń sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.”   Torí náà, oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun;Ẹni tó ń fi òòlù irin* lu nǹkan di pẹlẹbẹŃ fún ẹni tó ń fi òòlù lu nǹkan lórí irin lókun. Ó ń sọ nípa ohun tí wọ́n jó pọ̀ pé: “Ó dáa.” Wọ́n wá fi ìṣó kàn án, kó má bàa ṣubú.   “Àmọ́ ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi,+Ìwọ Jékọ́bù, ẹni tí mo yàn,+Ọmọ* Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi,+   Ìwọ tí mo mú láti àwọn ìkángun ayé,+Ìwọ tí mo pè láti àwọn apá ibi tó jìnnà jù níbẹ̀. Mo sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;+Mo ti yàn ọ́; Mi ò kọ̀ ọ́.+ 10  Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+ Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’ 11  Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+ Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+ 12  O máa wá àwọn tó ń bá ọ jà, àmọ́ o ò ní rí wọn;Àwọn tó ń bá ọ jagun máa dà bí ohun tí kò sí, bí ohun tí kò sí rárá.+ 13  Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+ 14  Má bẹ̀rù, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,*+Ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì, màá ràn yín lọ́wọ́,” ni Jèhófà, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí. 15  “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ohun tí wọ́n fi ń pakà,+Ohun tuntun tó ní eyín olójú méjì tí wọ́n fi ń pakà. O máa tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, o máa fọ́ wọn túútúú,O sì máa ṣe àwọn òkè kéékèèké bí ìyàngbò.* 16  O máa fẹ́ wọn bí ọkà, Atẹ́gùn sì máa gbé wọn lọ;Ìjì máa tú wọn ká. Inú rẹ máa dùn torí Jèhófà,+O sì máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì yangàn.”+ 17  “Àwọn aláìní àti àwọn tálákà ń wá omi, àmọ́ kò sí rárá. Òùngbẹ ti mú kí ahọ́n wọn gbẹ.+ Èmi Jèhófà máa dá wọn lóhùn.+ Èmi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò ní fi wọ́n sílẹ̀.+ 18  Màá mú kí odò ṣàn lórí àwọn òkè tí nǹkan ò hù sí,+Màá sì mú kí omi sun ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.+ Màá sọ aginjù di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Màá sì sọ ilẹ̀ tí kò lómi di orísun omi.  + 19  Màá gbin igi kédárì sínú aṣálẹ̀,Màá gbin igi bọn-ọ̀n-ní, igi mátílì àti igi ahóyaya síbẹ̀.+ Màá gbin igi júnípà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú,Pẹ̀lú igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì,+ 20  Kí gbogbo èèyàn lè rí i, kí wọ́n sì mọ̀,Kí wọ́n fiyè sí i, kó sì yé wọn,Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló sì dá a.”+ 21  “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí. “Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí. 22  “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa. Ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́* fún wa,Ká lè ronú nípa wọn,* ká sì mọ ibi tí wọ́n máa já sí. Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+ 23  Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa,Ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.+ Àní, ẹ ṣe nǹkan kan, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú,Kó lè yà wá lẹ́nu tí a bá rí i.+ 24  Ẹ wò ó! Ohun tí kò sí ni yín,Iṣẹ́ ọwọ́ yín kò sì já mọ́ nǹkan kan.+ Ohun ìríra ni ẹnikẹ́ni tó bá yàn yín.+ 25  Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, ó sì máa wá,+Ẹnì kan láti ibi tí oòrùn ti ń yọ*+ tó máa ké pe orúkọ mi. Ó máa tẹ àwọn alákòóso* mọ́lẹ̀ bíi pé amọ̀ ni wọ́n,+Bí amọ̀kòkò tó ń tẹ amọ̀ rírin mọ́lẹ̀. 26  Ta ló sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀, ká lè mọ̀,Tàbí láti ìgbà àtijọ́, ká lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’?+ Lóòótọ́, kò sí ẹni tó sọ ọ́! Kò sí ẹni tó kéde rẹ̀! Kò sí ẹni tó gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ!”+ 27  Èmi ni mo kọ́kọ́ sọ fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn nìyí!”+ Màá sì rán ẹni tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 28  Àmọ́ mò ń wò, kò sì sí ẹnì kankan;Kò sí ìkankan nínú wọn tó ń gbani nímọ̀ràn. Mo sì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n fèsì. 29  Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀tàn.* Iṣẹ́ wọn kò já mọ́ nǹkan kan. Afẹ́fẹ́ lásán àti ohun tí kò sí rárá ni àwọn ère onírin* wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ẹ dákẹ́ níwájú mi.”
Tàbí “láti ìlà oòrùn.”
Ìyẹn, láti sìn Ín.
Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.
Ní Héb., “Èso.”
Ìyẹn, ẹni tó rẹlẹ̀ tí kò sì lè gbèjà ara rẹ̀.
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Héb., “àkọ́kọ́.”
Tàbí “fọkàn sí i.”
Tàbí “láti ìlà oòrùn.”
Tàbí “ìjòyè.”
Tàbí “ohun tí kò sí rárá.”
Tàbí “ère dídà.”