Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì

Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kan wà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó. Wo ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí gan-an. Kọ́ nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì tó o kà túmọ̀ sí nípa kíká àyíká ọ̀rọ̀ náà kó o lè mọ ohun tí wọ́n ń sọ bọ̀. Wo àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti àwọn ẹsẹ míì nínú Bíbélì kí ọ̀rọ̀ náà lè yé ẹ dáadáa.

Àlàyé Jẹ́nẹ́sísì 1:1​—“Ní Ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé”

Òtítọ́ pàtàkì méjì wo ni gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sọ?

Àlàyé Ẹ́kísódù 20:12​—“Bọlá fún Bàbá Rẹ àti Ìyá Rẹ”

Ìlérí tí Ọlọ́run fi kún àṣẹ náà mú kó rọrùn láti pa á mọ́.

Àlàyé Nọ́ńbà 6:24-26​—“Kí OLÚWA Bùkún Un Yín Kí Ó sì Pa Yín Mọ́”

Báwo ni ọ̀rọ̀ nípa ìbùkún Áárónì ṣe bẹ̀rẹ̀?

Àlàyé Jóṣúà 1:9​—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”

Báwo lo ṣe lè ní ìgboya àti agbára nígbà tó o bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó kà ẹ́ láyà?

Àlàyé Sáàmù 23:4—“Bí Mo Tilẹ̀ Ń Rìn Nínú Àfonífojì Tó Ṣókùnkùn Biribiri”

Bí nǹkan bá tiẹ̀ le gan-an fún àwọn tó ń sin Ọlọ́run, báwo ló ṣe ń dáàbò bò wọ́n nírú àsìkò yẹn?

Àlàyé Sáàmù 37:4​—“Jẹ́ Kí Inú Rẹ Máa Dùn Ninu OLUWA”

Báwo làwọn ọ̀rọ̀ inú Sàámù yìí ṣe lè jẹ́ ká máa hùwà ọgbọ́n, ká sì tún jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?

Àlàyé Sáàmù 46:10​—“Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ sì Mọ̀ Pé Èmi Ní Ọlọ́run”

Ṣé ohun tí ẹsẹ yìí túmọ̀ sí ni pé kéèyàn dákẹ́ nínú ìjọ?

Àlàyé Òwe 16:3—“Fi Gbogbo Àdáwọ́lé Rẹ lé OLUWA Lọ́wọ́”

Kí làwọn ìdí méjì tó fi yẹ ká gbà kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?

Àlàyé Òwe 17:17​—“Ọ̀rẹ́ A Máa Fẹ́ni Nígbà Gbogbo”

Òwe yìí jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́.

Àlàyé Òwe 22:6​—“Tọ́ Ọmọdé ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

Kí ni “ọ̀nà” tó yẹ kí ọmọ tọ̀? Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ọ̀nà tó yẹ kó máa tọ̀?

Àlàyé Oníwàásù 3:11​—“Ó Ti Ṣe Ohun Gbogbo Dáradára ní Àsìkò Tirẹ̀”

Kì í ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run dá nìkan ni àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó wà létòletò. Báwo ló ṣe kàn ẹ́?

Àlàyé Àìsáyà 26:3​—“Ìwọ Yóò Pa Á Mọ́ Ní Àlàáfíà Pípé Ọkàn Ẹni Tí Ó Dúró Ṣinṣin”

Ǹjẹ́ a lè ní àlàáfíà tí kò lópin? Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin?

Àlàyé Àìsáyà 40:31—“Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Máa Jèrè Okun Pa Dà”

Kí nìdí tí Bíbélì fi fọ̀rọ̀ àwọn tí Ọlọ́run fún lókun wé ẹyẹ idì tó ń fò yípo?

Àlàyé Àìsáyà 41:10​—“Má Bẹ̀ru; Nitori Mo Wà Pẹlu Rẹ”

Jèhófà sọ ohun kan náà ní ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kó lè fi dá àwọn tó ń fòótọ́ sìn ín lójú pé òun á tì wọ́n lẹ́yìn.

Àlàyé Nípa Àìsáyà 42:8—“Èmi Ni OLÚWA”

Orúkọ wo ni Ọlọ́run fún ara rẹ̀?

Àlàyé Jeremáyà 11:11​—“Èmi Yóò Mu Ibi . . . Wá Sórí Wọn”

Ṣé Ọlọ́run ló fa “ibi” sórí àwọn èèyàn rẹ̀ ni àbí ṣe ló kàn fàyè gbà á?

Àlàyé Jeremáyà 29:11​—⁠​“Mo Mọ Èrò Tí Mò Ń Gbà Si Yín”

Ṣé Ọlọ́run ti wéwèé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan?

Àlàyé Jeremáyà 33:3​—“Ké Pè Mí, Màá sì Dá Ọ Lóhùn”

Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa sọ “àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé lóye” fún àwọn tó bá ṣe tán láti gbàdúrà sí i. Àwọn nǹkan wo nìyẹn? Ṣé Ọlọ́run máa ṣe bákan náà lónìí?

Àlàyé Míkà 6:8​—“Máa Rìn ní Ìrẹ̀lẹ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Rẹ”

Ẹsẹ Bíbélì yìí fi gbólóhùn mẹ́ta péré ṣàkópọ̀ ohun tí Ọlọ́run retí pé ká máa ṣe.

Àlàyé lórí Mátíù 6:34​—‘Ẹ Má Ṣàníyàn Nípa Ọ̀la’

Jésù ò ní ká má ronú nípa ọ̀la tàbí ká má ṣe ètò kankan fún ọjọ́ iwájú wa.

Àlàyé Mátíù 11:28-30​—“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Fún Yín Ní Ìsinmi”

Ṣé Jésù sọ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lòun máa mú gbogbo ìṣòro tó wà láyé kúrò tóun á sì fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ?

Àlàyé Máàkù 1:15​—‘Ìjọba Ọlọ́run Ti Sún Mọ́lé’

Ka Máàkù 1:15 látinú onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì, lo àwọn àlàyé etí ìwé àti àlàyé ọ̀rọ̀ kó o lè mọ àlàyé tó ṣáájú àti èyí tó tẹ̀ lé e nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan. Mọ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí.

Àlàyé Máàkù 11:24​—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Béèrè fún Nínú Àdúrà, Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Pé, Ó Ti Tẹ̀ Yín Lọ́wọ́”

Báwo ni ìmọ̀ràn Jésù pé ká nígbàgbọ́ tá a bá gbàdúrà ṣe lè mú ká borí àwọn ìṣòro wa lónìí?

Àlàyé Lúùkù 1:37 ​—“Nítorí Kò Sí Ohun Tí Ọlọ́run Kò Le Ṣe”

Kò sí ohunkóhun tó lè dí Ọlọ́run Olódùmarè lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ṣèlérí. Báwo nìyẹn ṣe kàn ẹ́?

Àlàyé Jòhánù 1:1—“Ní Ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà Wà”

Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jésù Kristi jẹ́ kó tó wá sáyé.

Àlàyé Nípa Jòhánù 3:16​—“Torí Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Ayé Gan-an”

Báwo ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun fẹ́ ká wà láàyè títí láé?

Àlàyé Lórí Jòhánù 14:27​—“Alaafia Ni Mo Fi Sílẹ̀ Fun Yín”

Irú àlàáfíà wo ni Jésù fi sílẹ̀ tàbí tó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Kí ló yẹ ká ṣe ká lè ní àlàáfíà yìí?

Àlàyé Jòhánù 15:13​—“Kò Sí Ẹnìkan Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”

Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó fi hàn?

Àlàyé Jòhánù 16:33 —“Mo Ti Ṣẹgun Aiye”

Báwo ni ọ̀rọ̀ Jésù ṣe jẹ́ kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé wọ́n lè ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn?

Àlàyé Ìṣe 1:8​—“Ẹ̀yin Yóò Gba Agbára”

Agbára wo ni Jésù ṣèlérí pé òun máa fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun, kí sì nìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe?

Àlàyé Róòmù 6:23—“Ikú ni Èrè Ẹ̀ṣẹ̀, Ṣùgbọ́n Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Kristi Jesu Olúwa Wa”

Kò sí èèyàn aláìpé kankan tó lè ní ìgbàlà, àmọ́ a lè gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run ń fúnni. Lọ́nà wo?

Àlàyé Róòmù 10:13​—“Pe Orúkọ Oluwa”

Ọlọ́run nawọ́ àǹfààní láti rí ìgbàlà àti ìyè àìnípẹ̀kun sí gbogbo èèyàn, láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí ipò wọn láwùjọ sí.

Àlàyé Róòmù 12:12—“Ẹ Ma Yọ̀ ni Ireti; Ẹ Ma Mu Suru Ninu Ipọnju; Ẹ Ma Duro Gangan Ninu Adura”

Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ láìka inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì tí wọ́n ń kojú sí?

Àlàyé Róòmù 15:13​—“Ǹjẹ́ Kí Ọlọ́run Ìrètí Kí Ó Fi Gbogbo Ayọ̀ òun Àlàáfíà Kún Yín”

Báwo ní ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè mú ká ní àlàáfíà, ayọ̀, àti ìrétí?

Àlàyé 1 Kọ́ríńtì 10:13​—“Olódodo Ni Ọlọ́run”

Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run máa ń gbà fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ tí àdánwò bá dé bá wa?

Àlàyé 2 Kọ́ríńtì 12:9​—“Oore-Ọ̀fẹ́ Mi Tó fún Ọ”

Ọ̀nà wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run? Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Gálátíà 6:9 Àlàyé​—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”

Àǹfààní wo ni Kristeni kan máa rí tí kò bá jáwọ́ nínú ṣíṣe rere?

Éfésù 3:20​—“[Ọlọ́run] Lè Ṣe Lọ́pọ̀lọpọ̀ Ju Gbogbo Èyí Tí A Ń Béèrè Tàbí Tí A Ń Rò Lọ”

Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tó sì máa ń ṣe kọjá ohun tí wọ́n ń retí?

Àlàyé Lórí Fílípì 4:13—“Mo Lè Ṣe Ohun Gbogbo Nínú Kristi”

Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ní okun láti ṣe “ohun gbogbo” túmọ̀ sí?

Àlàyé Kólósè 3:23​—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Ń Ṣe, Ẹ Ṣe É Tọkàntọkàn”

Báwo ni ọwọ́ ti Kristẹni kan fi mú iṣẹ́ ṣe kan àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?

Àlàyé 2 Tímótì 1:7​—“Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ìbẹ̀rù”

Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù kó sì ṣe ohun tó tọ́?

Àlàyé Hébérù 4:12​—“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè, Ó sì Ní Agbára”

Ṣé ò ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ayé ẹ ṣe? Kí ni ìyẹn ń sọ nípa irú ẹni tó o jẹ́?

Àlàyé Lórí Hébérù 11:1—“Ìgbàgbọ́ Ni Ìdánilójú Ohun Tí À Ń Retí”

Báwo ni ìgbàgbọ́ tọ̀ọ́tọ́ ṣe lágbára tó? Báwo ló sì ti ṣe pàtàkì tó?

Àlàyé 1 Pétérù 5:6, 7—“Ẹ Rẹ Ara Yín Sílẹ̀ . . . , Ẹ Kó Gbogbo Ìpayà Yín Tọ̀ Ọ́ Lọ”

Kí ló túmọ̀ sí láti “kó” àníyàn wa lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe lè mára tuni?

Àlàyé Ìfihàn 21:1​—“Ọ̀run Tuntun Kan àti Ayé Tuntun Kan”

Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ ohun tí ẹsẹ yìí túmọ̀ sí?

Àlàyé Ìfihàn 21:4​—“Ọlọ́run Yóò sì Nu Omijé Gbogbo Nù Kúrò ni Ojú Wọn”

Ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ọjọ́ iwájú.