Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Mátíù 11:28-30​—“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Fún Yín Ní Ìsinmi”

Mátíù 11:28-30​—“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Fún Yín Ní Ìsinmi”

 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín. Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”​—Mátíù 11:28-30, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóò fún yín ní ìsinmi. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ àti ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóò sì balẹ̀. Nítorí àjàgà mi túni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”​—Matiu 11:28-30, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

Ìtumọ̀ Mátíù 11:28-30

 Jésù fìfẹ́ sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun. Ó fi dá wọn lójú pé tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun, ara máa tù wọ́n, ọkàn wọn sì máa balẹ̀.

 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí fún làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti “di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń fi dandan mú àwọn èèyàn láti máa tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. (Mátíù 23:4; Máàkù 7:7) Bákan náà, àníyàn àti wàhálà àtijẹ àtimú tún mú kí nǹkan nira fáwọn èèyàn, torí wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n lè pèsè fún ìdílé wọn.

 “Màá sì tù yín lára.” Jésù ṣèlérí pé tẹ́nì kan bá wá sọ́dọ̀ òun, òun máa tu ẹni náà lára tàbí fún un ní ìsinmi. Jésù tu àwọn èèyàn lára ní ti pé ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Mátíù 7:24, 25) Ohun tí wọ́n mọ̀ yìí ti jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà ìsìn ti wọ́n fi ń ni wọ́n lára. (Jòhánù 8:31, 32) Òótọ́ ni pé ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá kéèyàn tó lè máa ṣe ohun tí Jésù sọ, síbẹ̀ téèyàn bá ń ṣe é, ara máa tù ú.

 “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn òṣìṣẹ́ sábà máa ń fi igi kan tí wọ́n ń pè ní àjàgà gbé ẹrù tó wúwo. Igi náà máa ń rí gbọọrọ, orí èjìká ni wọ́n sì máa ń gbé e lé. Torí náà, nígbà míì ọ̀rọ̀ náà “àjàgà” lè túmọ̀ sí pé ká máa ṣe ohun tẹ́nì kan bá fẹ́. (Léfítíkù 26:13; Àìsáyà 14:25; Jeremáyà 28:4) Bákan náà, a lè túmọ̀ gbólóhùn náà “kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi” sí “ẹ di ọmọ ẹ̀yìn mi (ìyẹn akẹ́kọ̀ọ́).” Ńṣe ni Jésù ń rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn òun, kí wọ́n sì máa fara wé òun.​—Jòhánù 13:13-15; 1 Pétérù 2:21.

 “Ara sì máa tù yín.” Jésù ò sọ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lòun máa mu gbogbo ìṣòro tó wà láyé kúrò. Àmọ́, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó mú kára tu àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Mátíù 6:25-32; 10:29-31) Àwọn tó gba àwọn ẹ̀kọ́ Jésù gbọ́ tó sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí i pé kò nira láti sin Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ọkàn wọn balẹ̀, ara sì tù wọ́n.​—1 Jòhánù 5:3.

 “Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.” Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà tútù, èyí sì mú kó yàtọ̀ pátápátá sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn ayé ìgbà yẹn. (Jòhánù 7:47-49) Jésù ò le koko, kàkà bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì ṣeé sún mọ́. Kò retí pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. (Mátíù 7:12; Máàkù 6:34; Lúùkù 9:11) Ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ ki Ọlọ́run dárí jì wọ́n, kí wọ́n lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, kára sì tù wọ́n. (Mátíù 5:23, 24; 6:14) Èèyàn rere ni Jésù, ìyẹn sì mú káwọn èèyàn sún mọ́ ọn. Torí náà, wọ́n gba àjàgà rẹ̀ tó fúyẹ́, wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Mátíù 11:28-30

 Nígbà tí Jésù ń wàásù ní Gálílì lọ́dún 31 Sànmánì Kristẹni ló sọ ohun tó wà ní Mátíù 11:28-30. Nínú gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì, àpọ́sítélì Mátíù nìkan ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Mátíù tóun náà jẹ́ Júù ti fìgbà kan rí jẹ́ agbowó orí, torí náà ó mọ bí nǹkan ṣe nira tó fáwọn aláìní torí owó orí táwọn ara Róòmù ń gbà àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù. Ó dájú pé inú Mátíù dùn gan-an nígbà tó rí i tí Jésù lo ọlá àṣẹ tí Jèhófà, a Bàbá rẹ̀ fún un láti pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ àtàwọn tára ń ni wá sọ́dọ̀ rẹ̀.​—Mátíù 11:25-27.

 Ìwé Ìhìn Rere Mátíù jẹ́ ká mọ àwọn ìwà rere tí Jésù ní, ìyẹn sì jẹ́ kó ṣe kedere pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí àti Ọba Ìjọba Ọlọ́run.​—Mátíù 1:20-23; Àìsáyà 11:1-5.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Mátíù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?