Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jòhánù 1:1—“Ní Ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà Wà”

Jòhánù 1:1—“Ní Ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà Wà”

 “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.”—Jòhánù 1:1, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Li àtetekọṣe li Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.”—Jòhánù 1:1, Bibeli Mimọ. a

Ìtumọ̀ Jòhánù 1:1

 Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jésù Kristi jẹ́ kó tó wá sáyé. (Jòhánù 1:14-17) Ní ẹsẹ 14, orúkọ oyè ni gbólóhùn náà “Ọ̀rọ̀ náà” (tàbí “Logos,” ní Gíríìkì, ho loʹgos). Ńṣe ni orúkọ oyè náà “Ọ̀rọ̀ náà” jẹ́ ká mọ ojúṣe pàtàkì tí Jésù ní, ìyẹn bó ṣe jẹ́ agbẹnusọ àwọn òfin Ọlọ́run fáwọn míì. Nígbà tí Jésù wá sáyé, bó ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn ló jẹ ẹ́ lógún jù, kódà ó ń bá a nìṣó láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó pa dà sọ́run.—Jòhánù 7:16; Ìfihàn 1:1.

 Gbólóhùn náà “ní ìbẹ̀rẹ̀” ń sọ ìgbà tí Ọlọ́run dá Ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn ìyẹn ni Ọlọ́run wá dá gbogbo nǹkan míì nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà. (Jòhánù 1:2, 3) Bíbélì sọ pé Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá” àti pé “ipasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn.”—Kólósè 1:15, 16.

 Gbólóhùn náà “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan” jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára bí Ọlọ́run ni Jésù kó tó wá sáyé, ó sì láwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní. A lè pe Jésù bẹ́ẹ̀ torí ojúṣe tó ní gẹ́gẹ́ bí Agbẹnusọ Ọlọ́run àti pé òun ni ẹ̀dá tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ipasẹ̀ rẹ̀ sì ni Ọlọ́run dá àwọn nǹkan tó kù.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jòhánù 1:1

 Ìwé Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bẹ̀rẹ̀ orí kìíní ìwé Jòhánù sọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ kó tó wá sáyé, àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti ipa pàtàkì tó kó kí àwa èèyàn lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jòhánù 1:1-18) Àwọn nǹkan yìí ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ohun tí Jésù sọ àti àwọn ohun tó ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé.—Jòhánù 3:16; 6:38; 12:49, 50; 14:28; 17:5.

Àwọn Èrò Tí Kò Tọ́ Nípa Jòhánù 1:1

 Èrò tí kò tọ́: Ó yẹ kí ìtumọ̀ gbólóhùn tó parí Jòhánù 1:1 jẹ́ “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ Ọlọ́run.”

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ló túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí bó se wà lókè yìí, àwọn kan rídìí láti túmọ̀ ẹ̀ lọ́nà míì. Nínú gírámà èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì níbẹ̀rẹ̀, ìgbà méjèèjì tí gbólóhùn náà, “Ọlọ́run” (ní Gíríìkì, the·osʹ) fara hàn ní Jòhánù 1:1 ni ìtumọ̀ wọn yàtọ̀ síra. Ní ìgbà àkọ́kọ́ tó fara hàn, ọ̀rọ̀ atọ́ka lédè Gíríìkì ló ṣíwájú ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run” àmọ́ ọ̀rọ̀ atọ́ka náà kò sí níbẹ̀ ní ìgbà kejì tó fara hàn. Àwọn ọ̀mọ̀wé rí i pé ó gbọ́dọ̀ nídìí pàtàkì tí ọ̀rọ̀ yẹn ò fi sí níwájú the·osʹ kejì to fara hàn ní ẹsẹ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé The Translator’s New Testament sọ ìdí tí ọ̀rọ̀ atọ́ka náà kò fi sí níbẹ̀: Ó ní “ńṣe ni Theos (Ọlọ́run) kejì tó wà nínú ẹsẹ yẹn ń ṣàpèjúwe ànímọ́ tí “Ọ̀rọ̀ náà” ní, ohun tí ibẹ̀ ń sọ ni pé ‘Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ẹni ti ọ̀run.’” b Àwọn ọ̀mọ̀wé míì àtàwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà tọ́ka sáwọn ìyàtọ̀ yìí.

 Èrò tí kò tọ́: Ẹsẹ yẹn kọ́ wa pé ìkan náà ni Ọ̀rọ̀ náà àti Ọlọ́run Olódùmarè.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Gbólóhùn náà “Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run” jẹ́ ká rí i pé ẹ̀dá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹsẹ yìí ń sọ. Torí, kò ṣeé ṣe kí Ọ̀rọ̀ náà wà “pẹ̀lú Ọlọ́run” kó sì tún jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè. Ẹsẹ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Jòhánù 1:18 sọ pé “kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí.” Àmọ́, àwọn èèyàn rí Ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn Jésù, torí Jòhánù 1:14 sọ pé “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara, ó gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀.”

 Èrò tí kò tọ́: Ọ̀rọ̀ náà kò níbẹ̀rẹ̀.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: “Ní ìbẹ̀rẹ̀” tá a tọ́ka sí ní ẹsẹ yìí ò lè túmọ̀ sí “ìbẹ̀rẹ̀” Ọlọ́run, torí Ọlọ́run ò ní ìbẹ̀rẹ̀. Jèhófà c jẹ́ Ọlọ́run “láti ayérayé dé ayérayé.” (Sáàmù 90:1, 2) Àmọ́, Ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn Jésù Kristi ní ìbẹ̀rẹ̀. Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.”—Ìfihàn 3:14.

 Èrò tí kò tọ́: Pípe Ọ̀rọ̀ náà ní “ọlọ́run” ń gbé ẹ̀kọ́ polytheism lárugẹ, ìyẹn ìjọsìn ọlọ́run púpọ̀.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run” tàbí “ọlọ́run” (the·osʹ) sábà máa ń ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʼel àti ʼelo·himʹ, tó fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Májẹ̀mú Láéláé. Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù yìí máa ń túmọ̀ sí “Alágbára Ńlá; Ẹni Alágbára” wọ́n sì máa ń lò ó fún Ọlọ́run olódùmarè, àwọn ọlọ́run kéékèèké àtàwọn èèyàn pàápàá. (Sáàmù 82:6; Jòhánù 10:34) Ọlọ́run lo Ọ̀rọ̀ náà láti dá gbogbo nǹkan míì torí náà a lè pe Ọ̀rọ̀ náà ní ẹ̀dá alágbára. (Jòhánù 1:3) Bí wọ́n ṣe pe Ọ̀rọ̀ náà ní “ọlọ́run kan” wà níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Àìsáyà 9:6, tó sọ pé a máa pe àyànfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn mèsáyà tàbí Kristi ní “Ọlọ́run Alágbára” (ní Hébérù, ʼEl Gib·bohrʹ), kì í ṣe “Ọlọ́run Olódùmarè” (ʼEl Shad·daiʹ, bó ṣe wà ní Jẹ́nẹ́sísì 17:1; 35:11; Ẹ́kísódù 6:3; Ìsíkíẹ́lì 10:5).

 Bíbélì ò ti ìjọsìn ọlọ́run púpọ̀ lẹ́yìn. Jésù Kristi sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Mátíù 4:10) Bíbélì sọ pé: “Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí à ń pè ní ọlọ́run wà, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí ní ayé, bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” àti ọ̀pọ̀ “olúwa” ṣe wà, ní tiwa, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, Baba, ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, tí àwa náà sì wà fún un; Olúwa kan ló wà, Jésù Kristi, ipasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà, tí àwa náà sì wà nípasẹ̀ rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 8:5, 6.

a The Translator’s New Testament, ojú ìwé 451.

b Ọ̀mọ̀wé Jason David BeDuhn sọ pé bí ọ̀rọ̀ atọ́ka ò ṣe sí níwájú “Ọlọ́run” tó fara hàn lẹ́ẹ̀mejì nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí i pé ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn méjèèjì, bí a ṣe máa ń fi ìyàtọ̀ sáàárín ‘ọlọ́run kan’ àti ‘Ọlọ́run’ tá a bá ń kọ̀wé lédè Yorùbá.” Ó fi kún un pé: “Ní Jòhánù 1:1, Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo náà, àmọ́ ó jẹ́ ọlọ́run kan tàbí ẹ̀dá alágbára.”—Truth in Translation: Accuracy and Bias in English Translations of the New Testament, ojú ìwé 115, 122 àti 123.

c Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run gangan.—Sáàmù 83:18.