Àkọsílẹ̀ Jòhánù 17:1-26

  • Jésù gbàdúrà tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-26)

    • Tí a bá wá mọ Ọlọ́run, ó máa yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun (3)

    • Àwọn Kristẹni kì í ṣe apá kan ayé (14-16)

    • “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ” (17)

    • “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ” (26)

17  Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbójú sókè wo ọ̀run, ó sọ pé: “Baba, wákàtí náà ti dé. Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo,+  bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,*+ kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un+ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+  Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun,+ pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo*+ àti Jésù Kristi,+ ẹni tí o rán.  Mo ti yìn ọ́ lógo ní ayé,+ ní ti pé mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe.+  Torí náà, ní báyìí, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.+  “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé.*+ Ìwọ lo ni wọ́n, o sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.*  Wọ́n ti wá mọ̀ báyìí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo ohun tí o fún mi ti wá;  torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi ni mo ti sọ fún wọn,+ wọ́n sì ti gbà á, ó dájú pé wọ́n ti wá mọ̀ pé mo wá bí aṣojú rẹ,+ wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.+  Mo gbàdúrà nípa wọn; kì í ṣe nípa ayé, àmọ́ nípa àwọn tí o fún mi, torí pé ìwọ lo ni wọ́n; 10  ìwọ lo ni gbogbo ohun tí mo ní, èmi ni mo sì ni tìrẹ,+ a sì ti ṣe mí lógo láàárín wọn. 11  “Mi ò sí ní ayé mọ́, àmọ́ àwọn wà ní ayé,+ mo sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan* bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.*+ 12  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn, mo máa ń ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi; mo ti dáàbò bò wọ́n, ìkankan nínú wọn ò sì pa run+ àfi ọmọ ìparun,+ kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ.+ 13  Àmọ́ ní báyìí, mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ, mo sì ń sọ àwọn nǹkan yìí ní ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nínú wọn.+ 14  Mo ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, àmọ́ ayé ti kórìíra wọn, torí wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé. 15  “Mi ò ní kí o mú wọn kúrò ní ayé, àmọ́ kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.+ 16  Wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.+ 17  Sọ wọ́n di mímọ́* nípasẹ̀ òtítọ́;+ òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.+ 18  Bí o ṣe rán mi wá sí ayé, èmi náà rán wọn lọ sínú ayé.+ 19  Mo sì ń sọ ara mi di mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn náà di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́. 20  “Kì í ṣe àwọn yìí nìkan ni mò ń gbàdúrà nípa wọn, mo tún ń gbàdúrà nípa àwọn tó máa ní ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, 21  kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan,+ bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi. 22  Mo ti fún wọn ní ògo tí o fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.+ 23  Èmi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn, ìwọ sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, kí a lè mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan délẹ̀délẹ̀,* kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi àti pé o nífẹ̀ẹ́ wọn bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi. 24  Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà,+ kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.+ 25  Baba olódodo, ní tòótọ́, ayé ò tíì wá mọ̀ ọ́,+ àmọ́ èmi mọ̀ ọ́,+ àwọn yìí sì ti wá mọ̀ pé ìwọ lo rán mi. 26  Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n,+ kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aráyé; èèyàn.”
Tàbí “kí wọ́n gba ìmọ̀ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo sínú.”
Tàbí “Mo ti jẹ́ kí àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé mọ orúkọ rẹ.”
Tàbí “ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.”
Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”
Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”
Tàbí “Yà wọ́n sọ́tọ̀; Jẹ́ kí wọ́n di mímọ́.”
Tàbí “kí a lè mú kí wọ́n ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀.”