Òwe 22:1-29

  • Orúkọ rere sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ (1)

  • Kíkọ́ ọmọ láti kékeré máa ṣe é láǹfààní jálẹ̀ ayé rẹ̀ (6)

  • Ọ̀lẹ ń bẹ̀rù kìnnìún tó wà níta (13)

  • Ìbáwí ń mú ìwà òmùgọ̀ kúrò (15)

  • Òṣìṣẹ́ tó bá jáfáfá ló ń bá àwọn ọba ṣiṣẹ́ (29)

22  Orúkọ rere* ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀;+Kéèyàn níyì* sàn ju fàdákà àti wúrà.   Ohun tí ọlọ́rọ̀ àti aláìní fi jọra* ni pé: Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+   Ọlọ́gbọ́n* rí ewu, ó sì fara pa mọ́,Àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.*   Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù JèhófàNi ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.+   Ẹ̀gún àti pańpẹ́ wà ní ọ̀nà onímàgòmágó,Àmọ́ ẹni tí ẹ̀mí* rẹ̀ bá jọ lójú yóò jìnnà réré sí wọn.+   Tọ́ ọmọdé* ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀;+Kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.+   Ọlọ́rọ̀ ń ṣàkóso àwọn aláìní,Ẹni tó yá nǹkan sì ni ẹrú ẹni tó yá a ní nǹkan.+   Ẹni tó bá gbin àìṣòdodo yóò ká àjálù,+Ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò sì ṣègbé.+   Ọ̀làwọ́* yóò gba ìbùkún,Nítorí ó ń fún aláìní lára oúnjẹ rẹ̀.+ 10  Lé afiniṣẹ̀sín lọ,Ìjà á tán nílẹ̀;Àríyànjiyàn* àti àbùkù á sì dópin. 11  Ẹni tó fẹ́ràn ọkàn tó mọ́, tó sì lọ́rọ̀ rere lẹ́nu,Yóò di ọ̀rẹ́ ọba.+ 12  Ojú Jèhófà ń ṣọ́ ìmọ̀,Àmọ́ Ó ń dojú ọ̀rọ̀ oníbékebèke dé.+ 13  Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Kìnnìún wà níta! Àárín gbàgede ìlú ló máa pa mí sí!”+ 14  Kòtò jíjìn ni ẹnu obìnrin oníwàkiwà.*+ Ẹni tí Jèhófà dá lẹ́bi yóò já sínú rẹ̀. 15  Ọkàn ọmọdé* ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,+Àmọ́ ọ̀pá ìbáwí yóò mú un jìnnà sí i.+ 16  Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì láti túbọ̀ kó ọrọ̀ jọ+Àti ẹni tó ń fún ọlọ́rọ̀ lẹ́bùnYóò di aláìní. 17  Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n,+Kí o lè fi ọkàn rẹ sí ìmọ̀ mi,+ 18  Nítorí ó dára pé kí o pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,+Kí gbogbo wọn lè máa wà ní ètè rẹ nígbà gbogbo.+ 19  Kí o lè gbẹ́kẹ̀ lé JèhófàNi mo ṣe ń fún ọ ní ìmọ̀ lónìí. 20  Ǹjẹ́ mi ò ti kọ̀wé sí ọ,Láti fún ọ ní ìmọ̀ràn àti ìmọ̀, 21  Láti kọ́ ọ ní ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òótọ́ tó sì ṣe é gbára lé,Kí o lè pa dà lọ jẹ́ iṣẹ́ tó péye fún ẹni tó rán ọ? 22  Má ja tálákà lólè torí pé kò ní lọ́wọ́,+Má sì fojú aláìní gbolẹ̀ ní ẹnubodè,+ 23  Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò+Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tó lù wọ́n ní jìbìtì. 24  Má ṣe bá onínúfùfù kẹ́gbẹ́,Má sì bá ẹni tó máa ń tètè bínú da nǹkan pọ̀, 25  Kí o má bàa kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀,Kí o sì kó ara* rẹ sínú ìdẹkùn.+ 26  Má ṣe wà lára àwọn tó ń bọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́,Tí wọ́n ń ṣe onídùúró fún ẹni tó ń yá owó.+ 27  Tí o kò bá rí i san,Wọ́n á gba ibùsùn rẹ kúrò lábẹ́ rẹ! 28  Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìnÈyí tí àwọn baba ńlá rẹ pa.+ 29  Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀? Yóò dúró níwájú àwọn ọba;+Kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ojú rere.”
Ní Héb., “Orúkọ.”
Ní Héb., “bára pàdé.”
Tàbí “Aláròjinlẹ̀.”
Tàbí “jìyà àbájáde rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”
Ní Héb., “Ẹni tó ní ojú tó dára.”
Tàbí “Ẹjọ́.”
Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.
Tàbí “ọ̀dọ́.” Ní Héb., “ọmọdékùnrin.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”