Jẹ́nẹ́sísì 15:1-21

  • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúrámù dá (1-21)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjìyà fún 400 ọdún (13)

    • Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (18-21)

15  Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ fún Ábúrámù nínú ìran pé: “Ábúrámù, má bẹ̀rù.+ Apata ni mo jẹ́ fún ọ.+ Èrè rẹ yóò pọ̀ gan-an.”+  Ábúrámù fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí lo máa fún mi, bí o ṣe rí i pé mi ò tíì bímọ, tó sì jẹ́ pé Élíésérì,+ ọkùnrin ará Damásíkù ni yóò jogún ilé mi?”  Ábúrámù fi kún un pé: “O ò fún mi ní ọmọ,*+ ará* ilé mi ló sì máa jogún ohun tí mo ní.”  Àmọ́, èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Ọkùnrin yìí ò ní jogún rẹ, ọmọ rẹ* ni yóò jogún rẹ.”+  Ó wá mú un wá sí ìta, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, gbójú sókè wo ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, tí o bá lè kà á.” Ó sì sọ fún un pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+  Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,+ Ó sì kà á sí òdodo fún un.+  Ó wá fi kún un pé: “Èmi ni Jèhófà, ẹni tó mú ọ kúrò ní Úrì ti àwọn ará Kálídíà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí kó lè di ohun ìní+ rẹ.”  Ó bi í pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, báwo ni màá ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ yìí máa di ohun ìní mi?”  Ó fèsì pé: “Mú abo ọmọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta kan wá fún mi àti abo ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta kan, àgbò ọlọ́dún mẹ́ta kan, ẹyẹ oriri kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.” 10  Ó wá kó gbogbo rẹ̀, ó gé wọn sí méjì-méjì, ó sì kọjú wọn síra,* àmọ́ kò gé àwọn ẹyẹ náà. 11  Àwọn ẹyẹ aṣọdẹ wá ń bà lé àwọn òkú ẹran náà, àmọ́ Ábúrámù ń lé wọn. 12  Nígbà tó kù díẹ̀ kí oòrùn wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tó ń dẹ́rù bani sì ṣú bò ó. 13  Ó wá sọ fún Ábúrámù pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ* rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+ 14  Àmọ́ màá dá orílẹ̀-èdè tí wọn yóò sìn+ lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó ọ̀pọ̀ ẹrù+ jáde. 15  Ní tìrẹ, wàá lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; wàá dàgbà, wàá darúgbó kí o tó kú.+ 16  Àmọ́ ìran wọn kẹrin á pa dà síbí,+ torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ámórì kò tíì kún rẹ́rẹ́.”+ 17  Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ti ṣú, iná ìléru tó ń rú èéfín fara hàn, iná ògùṣọ̀ sì kọjá láàárín àwọn ẹran tó gé. 18  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+ 19  ilẹ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Kénásì, àwọn Kádímónì, 20  àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Réfáímù,+ 21  àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn ará Jébúsì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “ẹni tó wá látinú ara rẹ.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ó sì kọjú wọn síra kí wọ́n lè bára mu.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “Èso.”