Àkọsílẹ̀ Máàkù 1:1-45

  • Jòhánù Onírìbọmi ń wàásù (1-8)

  • Jésù ṣèrìbọmi (9-11)

  • Sátánì dán Jésù wò (12, 13)

  • Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Gálílì (14, 15)

  • Ó pe àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn (16-20)

  • Ó lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde (21-28)

  • Jésù wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn ní Kápánáúmù (29-34)

  • Ó gbàdúrà níbi tó dá (35-39)

  • Ó wo adẹ́tẹ̀ sàn (40-45)

1  Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìn rere nípa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run:  Bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé wòlíì Àìsáyà pé: “(Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ.)+  Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+  Jòhánù Onírìbọmi wà nínú aginjù, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+  Gbogbo àwọn tó ń gbé ní agbègbè Jùdíà àti gbogbo Jerúsálẹ́mù máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ń ṣèrìbọmi fún wọn* ní odò Jọ́dánì, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.+  Jòhánù wọ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe, ó sì de àmùrè tí wọ́n fi awọ ṣe mọ́ ìbàdí rẹ̀,+ ó máa ń jẹ eéṣú àti oyin ìgàn.+  Ó sì ń wàásù pé: “Ẹnì kan tó lágbára jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí mi ò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀.+  Mò ń fi omi batisí yín, àmọ́ ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.”+  Nígbà yẹn, Jésù wá láti Násárẹ́tì ti Gálílì, Jòhánù sì ṣèrìbọmi fún un ní Jọ́dánì.+ 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń jáde látinú omi, ó rí i tí ọ̀run ń pínyà, ẹ̀mí sì ń bọ̀ wá sórí rẹ̀ bí àdàbà.+ 11  Ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+ 12  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀mí sún un láti lọ sínú aginjù. 13  Torí náà, ó lo ogójì (40) ọjọ́ nínú aginjù náà, Sátánì sì dán an wò.+ Ó wà láàárín àwọn ẹran inú igbó, àwọn áńgẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+ 14  Lẹ́yìn tí wọ́n mú Jòhánù, Jésù lọ sí Gálílì,+ ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run,+ 15  ó ń sọ pé: “Àkókò tí a yàn ti pé, Ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.” 16  Bó ṣe ń rìn lọ létí Òkun Gálílì, ó rí Símónì àti Áńdérù+ arákùnrin Símónì, tí wọ́n ń ju àwọ̀n wọn sínú òkun,+ torí apẹja ni wọ́n.+ 17  Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.”+ 18  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 19  Lẹ́yìn tó lọ síwájú díẹ̀ sí i, ó rí Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe,+ 20  ó sì pè wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Torí náà, wọ́n fi Sébédè bàbá wọn sílẹ̀ sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀ lé e. 21  Wọ́n lọ sí Kápánáúmù. Gbàrà tí Sábáàtì bẹ̀rẹ̀, ó wọnú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni.+ 22  Bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yà wọ́n lẹ́nu, torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin.+ 23  Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú, ó sì kígbe pé: 24  “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́!”+ 25  Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀!” 26  Lẹ́yìn tí ẹ̀mí àìmọ́ náà mú kí gìrì gbé ọkùnrin náà, tó sì pariwo gan-an, ó jáde kúrò nínú rẹ̀. 27  Ẹnu ya gbogbo àwọn èèyàn náà débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Kí nìyí? Ẹ̀kọ́ tuntun ni o! Ó ń lo agbára tó ní láti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.” 28  Torí náà, ìròyìn rẹ̀ yára tàn kálẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè Gálílì. 29  Wọ́n wá kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n sì lọ sí ilé Símónì àti Áńdérù pẹ̀lú Jémíìsì àti Jòhánù.+ 30  Àìsàn ibà dá ìyá ìyàwó Símónì+ dùbúlẹ̀, wọ́n sì sọ fún un nípa rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 31  Ó lọ bá obìnrin náà, ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì gbé e dìde. Ibà náà sì lọ, obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 32  Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn ti wọ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo àwọn tó ní àìlera àti àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀;+ 33  gbogbo ìlú sì kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn. 34  Torí náà, ó wo ọ̀pọ̀ àwọn tí oríṣiríṣi àìsàn ń yọ lẹ́nu sàn,+ ó sì lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, àmọ́ kì í jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.* 35  Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.+ 36  Àmọ́ Símónì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá a kàn, 37  wọ́n sì rí i, wọ́n wá sọ fún un pé: “Gbogbo èèyàn ti ń wá ọ.” 38  Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ síbòmíì, sí àwọn ìlú tó wà nítòsí, kí n lè wàásù níbẹ̀ náà, torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.”+ 39  Ó wá lọ ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù wọn káàkiri gbogbo Gálílì, ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+ 40  Bákan náà, adẹ́tẹ̀ kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́, àní lórí ìkúnlẹ̀, ó sọ fún un pé: “Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 41  Àánú rẹ̀ wá ṣe é, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wá sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.”+ 42  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀, ó sì mọ́. 43  Ó wá kìlọ̀ fún un gidigidi, ó sì ní kó máa lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 44  ó sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ lọ fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú àwọn ohun tí Mósè sọ dání láti wẹ̀ ọ́ mọ́,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 45  Àmọ́ lẹ́yìn tó lọ, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ káàkiri, ó sì ń tan ọ̀rọ̀ náà kiri débi pé Jésù ò lè wọ ìlú mọ́ kí àwọn èèyàn má mọ̀, àmọ́ ó dúró sẹ́yìn ìlú láwọn ibi tó dá. Síbẹ̀, wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá láti ibi gbogbo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
Tàbí “ṣe batisí fún wọn.”
Tàbí kó jẹ́, “wọ́n mọ ẹni tó jẹ́.”