Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Yẹra fún Ẹ̀kọ́ Àwọn Apẹ̀yìndà

Yẹra fún Ẹ̀kọ́ Àwọn Apẹ̀yìndà

Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè ẹ̀ máa ń da irọ́ pọ̀ mọ́ òótọ́ kí wọ́n lè jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. (2Kọ 11:3) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Ásíríà pa irọ́ burúkú kí wọ́n lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn Jèhófà. (2Kr 32:10-15) Àwọn apẹ̀yìndà náà máa ń lo irú ọgbọ́n burúkú yìí lónìí. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà? Ó yẹ ká rí wọn bíi májèlé tó lè pani! Torí náà, má ṣe ka ìwé tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá gbé sórí ìkànnì, má ṣe dá wọn lóhùn, má sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fáwọn míì. Wà lójúfò kó o lè tètè yẹra fáwọn ọ̀rọ̀ tó lè mú kó o máa ṣiyèméjì nípa Jèhófà àti ètò rẹ̀, má sì fàyè gbà á láé!​—Jud 3, 4.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ MÁA JÀ FITAFITA TORÍ ÌGBÀGBỌ́”!​—ÀYỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò èyíkéyìí?

  • Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 16:17?