Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀kan Lára Àwọn Èso Tó Wúlò Jù Lọ Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ọ̀kan Lára Àwọn Èso Tó Wúlò Jù Lọ Lórí Ilẹ̀ Ayé

Ọ̀kan Lára Àwọn Èso Tó Wúlò Jù Lọ Lórí Ilẹ̀ Ayé

ÈSO àràmàǹdà kan wà tó ti rìnrìn àjò yíká ayé. Ó ń pèsè ohun jíjẹ àti ohun mímu. Ìrísí àrà-ọ̀tọ̀ tí igi tó ń so èso yìí ní lohun pàtàkì tí wọ́n fi ń dá àwọn erékùṣù Ilẹ̀ Olóoru mọ̀. Èso wo là ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àgbọn ni, ọ̀kan lára àwọn èso tó wúlò jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.

Lójú àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yàtọ̀ sí Ilẹ̀ Olóoru, igi àgbọn wulẹ̀ jẹ́ àmì kan tó ń rán wọn létí ìrìn àjò wọn sí Ilẹ̀ Olóoru ni. Àmọ́ lójú àwọn èèyàn tó wà nílẹ̀ olóoru, àǹfààní tí igi yìí ní ju ìyẹn lọ fíìfíì. Àwọn ará Indonesia máa ń sọ pé “bí ọjọ́ ṣe pọ̀ nínú ọdún bẹ́ẹ̀ ni ìwúlò èso yìí ṣe pọ̀ tó.” Ní orílẹ̀-èdè Philippines náà, wọ́n máa ń sọ pé: “Ẹni tó bá gbin igi àgbọn gbin ohun èlò inú ilé àti aṣọ, ó gbin oúnjẹ àti ohun mímu, ó gbin ibi tó máa rí forí pa mọ́ sí, ó sì tún gbin ogún tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa dé bá.”

Gbólóhùn yìí kì í ṣe àsọdùn o. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Coconut—Tree of Life, ti sọ, “kì í ṣe oúnjẹ, omi, àti òróró ìseúnjẹ nìkan ni [igi àgbọn] ń pèsè, àmọ́ ó tún ń pèsè ewé fún kíkọ́ àwọn ilé olórùlé koríko, ó ní fọ́nrán tó ṣeé lò bí okùn àti fún híhun ẹní, èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ ṣeé lò fún bíbu nǹkan nínú ilé wọ́n sì tún lè fi ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́, ó tún ní àwọn ìtànná tó ń mú oje dídùn jáde tí wọ́n ń fi ṣe ṣúgà àti ọtí.” Ìwé náà fi kún un pé: “Kódà bí wọ́n bá la igi rẹ̀ dáadáa, ó ṣeé lò.” Àní, àwọn èèyàn tó ń gbé ní Erékùṣù Maldive ní Òkun Íńdíà ti fi àwọn nǹkan tí wọ́n mú lára igi àgbọn ṣe ọkọ̀ ojú omi, ìtàn sì sọ pé wọ́n fi àwọn ọkọ̀ náà rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Arébíà àti Philippines. Àmọ́, àgbọn fúnra rẹ̀ la lè pè ní arìnrìn-àjò ojú òkun tí kò lẹ́gbẹ́, kì í ṣe àwọn tó ń gbìn ín.

Èso Tó Jẹ́ Arìnrìn-Àjò Òkun

Àwọn eteetí òkun ilẹ̀ olóoru làyè ti gba àgbọn jù lọ, tí òjò bá ṣáà ti ń rọ̀ dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn àgbègbè náà lè gbin igi àgbọn tó wúlò fún oríṣiríṣi nǹkan yìí, àgbọn ti fúnra rẹ̀ rìnrìn àjò dé àwọn àgbègbè kan lórí ilẹ̀ ayé tí èèyàn kì í gbé rárá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni hóró oríṣiríṣi èso máa ń gbà fọ́n káàkiri, àmọ́ ti àgbọn yàtọ̀, omi òkun ló máa ń gbé e kiri. Ìyẹn gan-an ló sì mú kó ṣeé ṣe fún un láti lè máa rìnrìn àjò kárí ayé.

Nígbà tí àgbọn kan bá gbó, á jábọ́ sílẹ̀. Nígbà mìíràn, àgbọn tó ti gbó á yí lọ sí etíkun. Ìgbì omi tó ń rọ́ wá sí etíkun sì lè gbé e wọnú òkun lọ. Nítorí pé pádi ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ afẹ́fẹ́ sínú, kò ṣòro rárá fún àgbọn láti léfòó lórí omi. Bó bá jẹ́ apá ibi tí òkìtì iyanrìn tàbí àpáta yí ká ni àgbọn náà bọ́ sí, ó lè máa yí lọ díẹ̀díẹ̀ sí òdìkejì adágún náà. Àmọ́ bó bá fi lè yí wọnú agbami òkun, àgbọn náà lè rìnrìn àjò lọ jìnnàjìnnà.

Omi oníyọ̀, èyí tó máa ń ba àwọn hóró irúgbìn mìíràn jẹ́, kì í tètè ráyè wọnú pádi àgbọn, nítorí pé ó le koránkorán. Àgbọn lè wà lójú òkun fún oṣù mẹ́ta láìsí ohunkóhun tó máa ṣe é—nígbà míì, tí á máa sún lọ díẹ̀díẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà—síbẹ̀, tí yóò sì hù láìsí ìṣòro tó bá dé etíkun tó bá a lára mu. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà yìí ni àgbọn fi gbilẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ etíkun ilẹ̀ olóoru lágbàáyé.

Adùn Inú Oúnjẹ Ilẹ̀ Olóoru

Láwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Ilẹ̀ Olóoru, àwọn èèyàn lè máa rò pé ohun tí wọ́n ń lo àgbọn fún kò ju láti fi mú midinmíìdìn tàbí bisikíìtì ládùn lọ. Àmọ́ ní Gúúsù Éṣíà, èso tó wúlò fún oríṣiríṣi nǹkan ni àgbọn jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Pacific and Southeast Asian Cooking, ti sọ, “ohun èlò tó ṣe pàtàkì gan-an nínú oúnjẹ sísè ni àgbọn jẹ́ ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àgbègbè, àtàwọn erékùṣù tó wà láti ilẹ̀ Hawaii lọ sí Bangkok.” Ìwé náà tún sọ pé, fún àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn àgbègbè yẹn, “ohun kòṣeémáàní ni àgbọn jẹ́, torí pé ó máa ń pèsè nǹkan aṣaralóore fún ara wọn . . . ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lò ó, ní fífi se àìlóǹkà oúnjẹ àti lílò ó bí èròjà amóúnjẹdùn.”

Kò ṣòro láti mọ ohun tó mú àgbọn gbayì bẹ́ẹ̀ nínú oúnjẹ àwọn èèyàn ilẹ̀ olóoru: Ó jẹ́ nítorí omi inú rẹ̀, mílíìkì rẹ̀ àti òróró rẹ̀ tó ṣeé se oúnjẹ. Omi àgbọn ni wọ́n máa ń pe omi dídùn tó mọ́ gaara tó máa ń wà nínú èso àgbọn tí kò tíì gbó. Ó jẹ́ ohun mímu aládùn tó ń tuni lára tí wọ́n sábà máa ń tà láwọn ṣọ́ọ̀bù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà láwọn Ilẹ̀ Olóoru. Àmọ́ bí wọ́n ṣe máa ń yọ mílíìkì àgbọn ni pé, wọ́n á rin àgbọn náà, wọ́n á lú omi mọ́ ọn, lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá sẹ́ ẹ. Mílíìkì àgbọn yìí máa ń fi kún adùn ọbẹ̀ àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń fi ìyẹ̀fun ṣe.

Láti yọ òróró ìseúnjẹ nínú àgbọn, àgbẹ̀ kan yóò la àgbọn tó ti gbó yóò sì sá a gbẹ nínú oòrùn. Tó bá ti gbẹ, àgbọn náà á rọrùn láti yọ kúrò nínú èèpo ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n á wá fún òróró rẹ̀ jáde. Láwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Olóoru, òróró àgbọn jẹ́ òróró tó ṣe pàtàkì gan-an nínú oúnjẹ sísè, ṣùgbọ́n láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé, bọ́tà, áísìkiriìmù àti bisikíìtì ni wọ́n sábà máa ń lò ó fún.

Kíká àgbọn lórí igi kò rọrùn rárá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó bá fẹ́ ká a ní láti gun igi náà dókè tí yóò sì máa gé wọn bọ́ sílẹ̀. Àwọn mìíràn máa ń lo igi gígùn tí wọ́n so ọ̀bẹ mọ́ lórí. Ní orílẹ̀-èdè Indonesia, wọ́n ti kọ́ àwọn ọ̀bọ láti ṣe iṣẹ́ yìí. Àmọ́ ọ̀nà rírọrùn jù lọ, èyí táwọn tó fẹ́ kó dá àwọn lójú pé àgbọn tó gbó làwọ́n ká, máa ń lò ni láti dúró títí dìgbà tí àgbọn náà máa jábọ́ sílẹ̀ fúnra rẹ̀.

Ọ̀nàkọnà tí wọn ì báà gbà ká a, onírúurú ohun tí wọ́n ń lo àgbọn fún ti mú kó jẹ́ ohun ọ̀gbìn tó ń mówó wọlé àti ohun jíjẹ tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Nítorí náà, nígbà mìíràn tó o bá rí igi àgbọn, ì báà jẹ́ nínú àwòrán tàbí lójúkojú, máa rántí pé kì í kàn ṣe igi ẹlẹ́wà tó ń mú àwọn etíkun ilẹ̀ olóoru lẹ́wà lásán. Igi tó ń mú ọ̀kan lára àwọn èso tó wúlò jù lọ lórí ilẹ̀ ayé jáde lò ń wò yẹn.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

ÀWỌN ÌSỌFÚNNI PÀTÀKÌ NÍPA ÀGBỌN

ALÁKÀN TÓ MÁA Ń JẸ ÀGBỌN. Èèyàn nìkan kọ́ ló ń gbádùn àgbọn. Alákàn tó ń jẹ àgbọn máa ń wà nínú ihò ilẹ̀ lọ́sàn-án, àmọ́ tó bá di òru, ó máa ń gbádùn jíjẹ àgbọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn nílò àdá láti lè la àgbọn, alákàn tí kò nílò ohúnkóhun yìí máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti la àgbọn. Ó máa ń sọ ọ́ mọ́ àpáta títí tó máa fi là. Ó dà bí ẹni pé oúnjẹ tó ní àgbọn nínú nìkan tẹ́ ẹ̀dá yìí lọ́rùn—kódà, ó lè gbé ju ọgbọ̀n ọdún lọ láyé!

WỌ́N Ń LO ÀGBỌN FÚN ÀWỌN ÈRÒJÀ ÌṢARALÓGE. Níwọ̀n bí òróró àgbọn ti dára fún awọ ara, àwọn tó ń ṣe èròjà ìṣaralóge máa ń lò ó fún ohun táwọn obìnrin ń fi kun ètè àti ìpara tó ń dáàbò bo ara lọ́wọ́ oòrùn. Tó o bá sì ń lo ọṣẹ ìwẹ̀ kan tàbí ọṣẹ ìfọrun tó ń hó gan-an, ó ṣeé ṣe kí òróró àgbọn wà lára àwọn nǹkan pàtàkì tí wọ́n fi ṣe é.

[Àwọn àwòrán]

Àgbọn lè rìnrìn àjò jíjìnnà lójú òkun

Alákàn tó máa ń jẹ àgbọn

Àgbọn

[Credit Line]

Godo-Foto

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Fọ́tò inú àkámọ́ lókè lápá ọ̀tún: Godo-Foto