Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

Wálé rí Ṣẹ́gun tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹ̀rù sì ń bà á, torí pé ọkàn rẹ̀ ti sọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ fún un. Nígbà tí Ṣẹ́gun dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Wálé, báwo ni? Mo fẹ́ fún ẹ ní nǹkan kan!” Nígbà tí Ṣẹ́gun la ọwọ́ rẹ̀, ohun tí Wálé ń rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ gan-an ló ṣẹlẹ̀, sìgá ló rí lọ́wọ́ Ṣẹ́gun. Wálé kò fẹ́ gbà á, síbẹ̀ kò fẹ́ kí Ṣẹ́gun máa wo òun bí ẹni tí kò ríta. Wálé kò mọ ohun tí ì bá ṣe, ó kàn ṣáà sọ fún Ṣẹ́gun pé: “Wò ó ọ̀rẹ́, tó bá dìgbà míì. Ṣó o gbọ́?”

Fọlákẹ́ rí Ṣẹ́gun tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ti múra sílẹ̀ fún ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Ṣẹ́gun dé ọ̀dọ̀ Fọlákẹ́, ó sọ fún un pé: “Fọlákẹ́, báwo ni? Mo fẹ́ fún ẹ ní nǹkan kan!” Nígbà tí Ṣẹ́gun la ọwọ́ rẹ̀, ohun tí Fọlákẹ́ ń rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ gan-an ló ṣẹlẹ̀, sìgá ló rí lọ́wọ́ Ṣẹ́gun. Pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ ni Fọlákẹ́ fi sọ fún Ṣẹ́gun pé: “O ṣeun gan-an ni, mi ò fẹ́. Mo ṣì ní àwọn nǹkan tí mo fẹ́ gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú, tí mi ò bá sì lè mí dáadáa mọ́ mi ò ní lè ṣe àwọn nǹkan ọ̀hún. Àti pé, . . . mi ò rò pé irú ẹ ló yẹ kó máa mu sìgá!”

NÍNÚ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, kí ló mú kí Fọlákẹ́ lè fún Ṣẹ́gun lésì pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀? Ìdí ni pé, Fọlákẹ́ ní nǹkan kan tí Wálé kò ní. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà? Ohun náà ni àmì ìdánimọ̀. Eléyìí kì í ṣe káàdì kan tí wọ́n kọ orúkọ sí, tí wọ́n sì lẹ fọ́tò mọ́ lára o. Àmì ìdánimọ̀ tá à ń sọ ni, irú èèyàn tí ọkàn rẹ sọ fún ẹ pé o jẹ́, àti irú ìwà tó o gbà pé ó yẹ kó o máa hù. Tó o bá ní irú àmì ìdánimọ̀ yìí, o kò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa kó ẹ sí wàhálà, wàá sì lè máa darí ìgbésí ayé rẹ, dípò tí wàá fi jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì máa bá ẹ darí rẹ̀. Báwo lo ṣe lè ní irú ìfọ̀kànbalẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ó máa dára kó o kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí ná.

1 ÀWỌN ÌWÀ RERE WO NI MO NÍ?

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Tó o bá mọ àwọn ẹ̀bùn tó o ní àtàwọn ìwà rere tó o ní, èyí máa jẹ́ kí ọkàn rẹ túbọ̀ balẹ̀.

Ronú lórí èyí: Gbogbo èèyàn ló ní ẹ̀bùn tirẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ní ẹ̀bùn yíya àwòrán tàbí orin kíkọ, nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹ̀lòmíì ní ẹ̀bùn ìfarapitú. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Raquel ní ẹ̀bùn bí wọ́n ṣe ń tún ọkọ̀ ṣe. a Ó sọ pé “Látìgbà tí mo ti wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo ti rí i pé iṣẹ́ atọ́kọ̀ṣe ló wù mí láti ṣe.”

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:6) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, èyí mú kó dúró lórí ìpinnu rẹ̀ nígbà táwọn kan ta kò ó. Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ kí èrò tí kò dáa táwọn èèyàn ní mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù.—2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:5.

Ṣàyẹ̀wò ara rẹ. Kọ ẹ̀bùn kan tó o ní tàbí nǹkan kan tó o mọ̀ ọ́n ṣe sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ní báyìí, kọ ìwà rere kan tó o ní sórí ìlà yìí. (Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ bí wọ́n ṣe ń ṣìkẹ́ èèyàn? ṣé ọ̀làwọ́ ni ẹ́? ṣé ẹni tó ṣeé gbára lé ni ẹ́? ṣé o kì í ṣe apẹ́lẹ́yìn?)

․․․․․

“Mo máa ń gbìyànjú láti jẹ́ adúrótini nígbà ìṣòro. Bí ẹnì kan bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n tí ọwọ́ mi dí, mo ṣì máa ń dáwọ́ ohun tí mò ń ṣe dúró kí n lè tẹ́tí gbọ́ ohun tí ẹni náà fẹ́ sọ.”—Brianne.

Tó bá ṣòro fún ẹ láti mọ ìwà rere kan tó o ní, ronú nípa ohun kan tí ò ń ṣe bó o ṣe ń dàgbà tó fi hàn pé o ti ní ìwà àgbà, kó o sì kọ ọ́ sórí ìlà yìí.—Bí àpẹẹrẹ, wo àpótí náà,  “Ohun Táwọn Ojúgbà Ẹ Sọ.”

․․․․․

2 ÀWỌN ÌWÀ TÓ KÙ DÍẸ̀ KÁÀTÓ WO NI MO NÍ?

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Àmì ìdánimọ̀ rẹ lè bà jẹ́, tó o bá lọ jẹ́ kí àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tó o ní máa darí ìgbésí ayé rẹ.

Ronú lórí èyí: Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. (Róòmù 3:23) Gbogbo èèyàn pátá ló ní àwọn ìwà kan tó jẹ́ pé ó wù wọ́n láti ṣàtúnṣe. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Seija sọ pé: “Kí nìdí tí mo fi máa ń bínú nítorí ohun tí kò tó nǹkan? Nǹkan kékeré ló máa ń múnú bí mi, kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, màá kàn rí i pé mo ti fara ya!”

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé òun ní ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó. Ó kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 7:22, 23.

Ṣàyẹ̀wò ara rẹ. Ìwà tó kù díẹ̀ káàtó wo lo ní tó yẹ kó o ṣàtúnṣe rẹ̀?

․․․․․

“Mo ti kíyè sí i pé lẹ́yìn tí mo bá ti wo àwọn eré tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́, ńṣe ni ìrònú máa ń bá mi, ó sì máa ń ṣe mi bíi pé kí èmi náà rí ẹnì kan tí ìfẹ́ rẹ̀ máa wọ̀ mí lọ́kàn. Torí náà, ní báyìí mo ti wá mọ̀ pé ó yẹ kí n máa kíyè sára nípa àwọn eré tí mò ń wò.”—Bridget.

3 KÍ NI ÀWỌN ÀFOJÚSÙN RẸ?

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Tó o bá fi àwọn nǹkan kan ṣe àfojúsùn rẹ, èyí á jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ ní ibi pàtó tí ó dorí kọ́, yóò sì ní ìtumọ̀. Èyí á sì jẹ́ kó o máa yẹra fún àwọn èèyàn àti àwọn ipò tó lè mú kí ọwọ́ rẹ má ṣe tẹ àwọn àfojúsùn rẹ.

Ronú lórí èyí: Ǹjẹ́ o lè dá onímọ́tò kan dúró, kó o wá sọ́ fún un pé kó kàn máa gbé ẹ yí po ibì kan títí epo ọkọ̀ rẹ̀ á fi gbẹ́? Ìyẹn kò bọ́gbọ́n mu rárá. Àti pé ńṣe ni ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kàn ń fi owó ṣòfò lásán! Tó o bá ní àwọn nǹkan tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ, wàá lè ṣe àwọn nǹkan náàláṣeyọrí. Wàá mọ ibi tí ò ń lọ, wàá sì mọ ọ̀nà tó o máa gbà dé ibẹ̀.

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú.” (1 Kọ́ríńtì 9:26) Dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá kàn fi máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ láìní ibi pàtó kan tó dorí kọ́, ńṣe ló ní àwọn àfojúsùn, ó sì gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tí ọwọ́ rẹ̀ á fi tẹ àwọn àfojúsùn náà.—Fílípì 3:12-14.

Ṣàyẹ̀wò ara rẹ. Kọ ohun mẹ́ta tó o fẹ́ fi ṣe àfojúsùn rẹ, tó o sì fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ní ọdún tó ń bọ̀.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

3 ․․․․․

èyí tó ṣe pàtàkì jù sí ẹ lára ohun mẹ́ta tó o kọ yẹn, kó o wá kọ ohun tó o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́.

․․․․․

“Tí mi ò bá ní nǹkan gidi kan tí mò ń ṣe, ohun tí mo máa ń kíyè sí ni pé ńṣe ni mo kàn ń fi àkókò ṣòfò lásán. Ó dáa kí èèyàn ní àwọn àfojúsùn, kí ó sì sapá láti máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ àwọn àfojúsùn náà.”—José.

4 ÀWỌN NǸKAN WO NI MO GBÀ GBỌ́?

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Tí o kò bá ní àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́, o kò ní lè lo làákàyè rẹ kó o sì ṣe ìpinnu gidi. Ńṣe ni wàá máa ṣe bí ẹranko tí wọ́n ń pè ní ọ̀gà, tó máa ń yí àwọ̀ rẹ̀ pa dà, ní ti pé wàá máa yí ìwà rẹ pa dà nígbà gbogbo kó o bàa lè hùwà tó máa tẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lọ́rùn. Ìyẹn sì jẹ́ àmì pé o kò ní àmì ìdánimọ̀ tìrẹ.

Ronú lórí èyí: Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ‘ṣàwárí fúnra wọn ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.’ (Róòmù 12:2) Tó bá jẹ́ pé ohun tó o gbà gbọ́ ló mú kó o ṣe ohun kan, ohunkóhun táwọn èèyàn ì báà ṣe, ńṣe ni wàá dúró lórí ìpinnu rẹ.

Àpẹẹrẹ inú Bíbélì: Wòlíì Dáníẹ́lì kò tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó ti “pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀” pé òun á máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí lọ́dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀ àtàwọn olùjọ́sìn Jèhófà bíi tirẹ̀. (Dáníẹ́lì 1:8) Ohun tó ṣe yìí ló mú kó dúró lórí ìpinnu rẹ̀. Dáníẹ́lì gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ohun tó gbà gbọ́ mu.

Ṣàyẹ̀wò ara rẹ. Àwọn nǹkan wo lo gbà gbọ́? Bí àpẹẹrẹ:

● Ǹjẹ́ o gbà pé Ọlọ́run wà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí? Kí ló mú kó dá  lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́?

● Ǹjẹ́ o gbà pé ó máa ṣe ẹ́ ní àǹfààní tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún wa nípa àwọn ìwà tó yẹ ká máa hù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, kí ló mú kó dá ẹ lójú pé tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin tí Ọlọ́run fún wa nípa ìbálòpọ̀, èyí á mú kó o láyọ̀ dáadáa ju kó o máa ṣe bó ṣe wù ẹ́, bíi tàwọn ojúgbà rẹ?

Àwọn ìbéèrè yìí kì í ṣe ohun tó o lè dáhùn lójú ẹsẹ̀. Ńṣe ni kó o fara balẹ̀ ronú lórí ìdí tó o fi gba àwọn nǹkan kan gbọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dúró lórí àwọn ìpinnu rẹ.—Òwe 14:15; 1 Pétérù 3:15.

“Nílé ìwé, ńṣe ni wọ́n máa ń fi èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá rí i pé ohun tí ẹnì kan gbà gbọ́ kò dá a lójú, èmi ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ kó dà bíi pé ohun tí mo gbà gbọ́ kò dá mi lójú. Torí náà, mo jẹ́ kí àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ dá mi lójú, mo sì rí i pé mo lè ṣàlàyé wọn lọ́nà tó ṣe kedere. Dípò tí mi ò bá fi sọ fún àwọn èèyàn pé ‘Ẹ wò ó, èmi kì í ṣe irú nǹkan yìí torí pé ẹ̀sìn mi kò fàyè gbà á,’ mo rí i pé ó sàn kí n kúkú sọ pé ‘èmi ò rò pé ó yẹ kí èèyàn máa ṣe irú nǹkan yìí.’ Àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ nìyẹn.”—Danielle.

Ní òpin gbogbo rẹ, irú èèyàn wo ni ìwọ fẹ́ jẹ́, ṣé a lè fi ọ́ wé ewé tó já bọ́ lára igi, tó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ tó kàn fẹ́ yẹ́ẹ́ lásán ló ń gbé e káàkiri, àbí a lè fi ọ́ wé igi tí ìjì tó lágbára kò lè bì ṣubú? Tí o kò bá jẹ́ kí ohunkóhun ba àmì ìdánimọ̀ rẹ jẹ́, ńṣe lo máa dà bí igi tá a fi ṣàpèjúwe yẹn. Èyí á jẹ́ kó o lè dáhùn ìbéèrè náà tó sọ pé, Irú èèyàn wo gan-an ni mo jẹ́?

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

 OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Ní báyìí tí mo ti dàgbà sí i, mo ti wá ń ronú jinlẹ̀ dáadáa tí mo bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ì báà jẹ́ ìpinnu ńlá tàbí kékeré, mi ò sì fẹ́ lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan tí kò ní mú inú Ọlọ́run dùn.”

“Nígbà tí mo wà ní ọmọdé, ojú aláìmọ̀kan ni mo fi máa n wo ẹnikẹ́ni tí èrò rẹ̀ bá ti yàtọ̀ sí tèmi. Àmọ́ ní báyìí, mo fẹ́ràn bó ṣe jẹ́ pé ọ̀nà tí kálukú gbà ń ronú yàtọ̀ síra, mo sì máa ń fẹ́ láti mọ èrò àwọn ẹlòmíì nípa àwọn nǹkan.”

[Àwọn àwòrán]

Jeremiah

Jennifer

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀bùn kan wà tí  rí i pé mo ní? Àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó wo lẹ rò pé ó yẹ kí n ṣàtúnṣe wọn? Kí ló mú kó dá yín lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló dára jù lọ?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌWÀ RERE

ÌWÀ TÓ KÙ DÍẸ̀ KÁÀTÓ

ÀFOJÚSÙN

OHUN TÓ O GBÀ GBỌ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Tó o bá ní àmì ìdánimọ̀ tí kò ṣeé yí pa dà, ńṣe lo dà bí igi tí ìtàkùn rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, tó jẹ́ pé bí atẹ́gùn fẹ́, bí ìjì jà, ńṣe ló máa dúró digbí