Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ Ọ́?—Apá Kejì

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ Ọ́?—Apá Kejì

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ Ọ́?​—Apá Kejì

NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE TÓ ṢÁÁJÚ ÈYÍ, a sọ̀rọ̀ nípa òótọ́ ọ̀rọ̀ méjì kan.

● Tó bá di pé ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ, ó lè yọrí sí ẹ̀dùn ọkàn fún ẹ.—Òwe 6:27.

● Tó bá di pé ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ, okùn ọ̀rẹ́ yín kò ní pẹ́ já. aÒwe 18:24.

NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ, a máa sọ̀rọ̀ nípa

● Òótọ́ ọ̀rọ̀ kẹta nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí ọkàn rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan

● Bó o ṣe lè mọ̀ tí ọ̀rọ̀ ìwọ àti ọkùnrin (tàbí obìnrin) kan bá ti ń kọjá ti ọ̀rẹ́ lásán

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀: Tó bá di pé ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan, tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ, o lè ba ara rẹ lórúkọ jẹ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Mia b sọ pé: “Mo mọ àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n ní àwọn ọmọbìnrin púpọ̀ tí wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́. Ṣe ni irú wọn kàn máa ń mú àwọn obìnrin ṣeré. Àwọn ọmọbìnrin yẹn á sì máa rò pé wọ́n máa fẹ́ àwọn, àmọ́ irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kàn fẹ́ràn láti máa bá àwọn obìnrin ṣeré lásán ni.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:

● Tó o bá jẹ́ obìnrin (tàbí ọkùnrin), tó o sì ń bá àwọn ọkùnrin (tàbí obìnrin) ṣeré ju bó ṣe yẹ lọ, báwo nìyẹn ṣe lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́?

“Tó o bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ ṣáá sí àwọn ọkùnrin lórí fóònù, ṣe ni wàá kàn kó bá ara ẹ. Ó lè jẹ́ pé orí ẹnì kan péré lo ti máa bẹ̀rẹ̀, tó bá yá, wọ́n á di púpọ̀. Kó o tó mọ̀ wàá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ọkùnrin mẹ́ta pa pọ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn á sì máa rò pé òun ni ‘olólùfẹ́’ tó o fẹ́ràn jù. Tí wọ́n bá wá rí i pé àwọn pọ̀ lọ́wọ́ ẹ, ó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, wọ́n á sì máa fi ojú pé o kò mọ̀ ju ọkùnrin lọ wò ẹ́.”—Lara.

Bíbélì sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan [tàbí ọmọdébìnrin kan] ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.”—Òwe 20:11.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò sí nǹkan tó burú nínú kó o máa bá àwọn ọkùnrin (tàbí obìnrin) ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ tó bá ti di àṣejù, o lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ara rẹ, ọ̀rẹ́ yín lè má wọ̀ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì tún lè ba ara rẹ lórúkọ jẹ́.

Báwo lo ṣe máa mọ̀ tí ọ̀rọ̀ yín bá ti ń kọjá pé ẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ lásán? Ọ̀nà kan tó o fi lè mọ̀ ni pé kó o bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin (tàbí obìnrin) ni mo máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí mi fún?’ Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Erin sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ lásán nìwọ àti ọmọkùnrin kan kàn ń bára yín ṣe, kò yẹ kó jẹ́ òun ni wàá kọ́kọ́ fẹ́ máa pè lójoojúmọ́ tàbí kó jẹ́ pé òun ni wàá kọ́kọ́ fẹ́ máa sọ ohun tó o bá gbọ́ fún. Kò yẹ kó jẹ́ òun ni wàá fi ṣe alábàárò rẹ.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:

● Kí nìdí tó fi lè dà bíi pé ó máa ń wù ẹ́ pé kó o sọ ọkùnrin (tàbí obìnrin) kan di ẹni tí wàá máa sọ ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ fún? Ewu wo ló wà ńbẹ̀?

“Èmi àtàwọn ọmọkùnrin tí mo mọ̀ kì í ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Mi kì í bá wọn sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí fóònù bí èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi obìnrin ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ kan tiẹ̀ wà tí mi ò ní wulẹ̀ bá wọn sọ.”Rianne.

Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ń ṣí ètè rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu-ìparun yóò jẹ́ tirẹ̀.”—Òwe 13:3.

Rò ó wò ná: Ǹjẹ́ ewu tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa sọ nǹkan tó pọ̀ jù nípa ara rẹ̀ fún ọkùnrin (tàbí obìnrin)? Tí ọ̀rẹ́ yín kò bá wọ̀ mọ́ ńkọ́? Ǹjẹ́ kò ní dùn ẹ́ pé o ti sọ àwọn nǹkan kan nípa ara rẹ fún ẹni náà?

Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Alexis sọ òótọ́ tó wà níbẹ̀ pé: “Kò yẹ kó o máa sá fún ẹnì kan torí pé ó jẹ́ ọkùnrin (tàbí obìnrin). Síbẹ̀, má ṣe máa tan ara ẹ jẹ pé ọ̀rẹ́ lásán lẹ kàn ń ṣe nígbà tọ́rọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣọ́ra kí ọkàn rẹ má kàn máa fà sáwọn ẹlòmíì ṣáá, kó o má bàa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ara ẹ.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.ps8318.com

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo Jí! July-September 2012, ojú ìwé 15 sí 17.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN: “Ọmọkùnrin kan wà tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́, ọ̀rọ̀ wa sì wọ̀ dáadáa. Àmọ́ nígbà tó yá, mo kíyè sí i pé àkókò tá a fi ń bá ara wa sọ̀rọ̀ ti ń pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó túbọ̀ ń sọ ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ fún mi, èmi náà sì ti ń sọ tèmi fún un. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé àwa méjèèjì ti ń sún mọ́ra ju bó ṣe yẹ lọ torí pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún mi. Ó wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé ó fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí kọ̀ǹpútà pé ọkàn òun ń fà sí mi ṣáá bíi pé ká jọ máa fẹ́ra. Mi o tiẹ̀ mọ ohun tí ǹ bá sọ fún un. Ọ̀rọ̀ yẹn wú mi lórí gan-an, torí inú èèyàn máa ń dùn tó bá mọ̀ pé ẹnì kan wà tó ń ronú nípa òun. Àmọ́ ọ̀rọ̀ yẹn tún ń kọ mí lóminú. Ó hàn pé ọ̀rọ̀ wa ti ń kọjá ti ‘ọ̀rẹ́ lásán’ torí ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yìí ti fi hàn pé ó ti ń rò pé à ń fẹ́ ara wa. Mo mọ̀ pé tí mo bá sọ fún un pé àwa méjèèjì ò tíì dàgbà tó láti máa fẹ́ra wa sọ́nà, ó máa dùn ún gan-an. Ni mo bá sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn òbí mi, wọ́n sì jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó fún èmi àti ọmọkùnrin náà láti dín ọ̀rẹ́ tá a jọ ń ṣe kù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí jẹ́ kí n wá mọ̀ pé nǹkan tó dà bíi ṣeréṣeré lásán lè wá di ọ̀rọ̀ tó le gan-an. Látìgbà yẹn ni mo ti máa ń ṣọ́ra nípa bí mo ṣe ń bá àwọn ọkùnrin ṣọ̀rẹ́, pàápàá tí mo bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn èèyàn lórí fóònù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tún ti mú kí n kọ́ láti máa báwọn èèyàn ṣeré pa pọ̀ dípò ká máa múra wa ní méjì-méjì. Ìyẹn kò ní jẹ́ kó o máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ fún ẹnì kan pàtó débi pé ọkàn rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí onítọ̀hún ṣáá.”—Elena.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Béèrè àwọn ìbéèrè tá a kọ sábẹ́ àwọn ìsọ̀rí tá a pè ní “Ohun tó yẹ kó o ronú lé” nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ, kí wọ́n sì sọ èrò wọn fún ẹ. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yàtọ̀ sí èrò tìrẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀? Àǹfààní wo lo rò pé ó wà nínú ohun tí wọ́n sọ?​—Òwe 1:8.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Andre—Bí ìwọ àti ọmọbìnrin kan bá jọ ń wà pa pọ̀ ṣáá, ọkàn yín lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ara yín, ìyẹn sì lè jẹ́ kí ọmọbìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ṣe lo fẹ́ máa fẹ́ òun. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o ní àwọn nǹkan míì tó o ṣì fẹ́ lé bá, ìyẹn ni kó o kọ́kọ́ gbájú mọ́, má ṣe fi ohun tó ò ní jẹ run imú.

Cassidy—Ara tèmi yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn dáadáa, nígbà tó sì jẹ́ pé àárín àwọn ọkùnrin ni mo dàgbà sí, ó máa ń wù mí kí n máa wà lọ́dọ̀ wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò fi bẹ́ẹ̀ dáa tó. Tó bá jẹ́ pé bí mo ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin náà ni mò ń ṣe pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, ìyẹn kò ní dáa torí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní nǹkan míì lọ́kàn. Ohun tó dáa jù ni pé kí n máa wò wọ́n bíi pé wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin jọ máa kẹ́gbẹ́ lọ́nà tó bójú mu. Àmọ́ ó yẹ kí àwọn tí kò tíì ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kọjá àyè wọn. c Kò yẹ kí wọ́n ṣe àṣejù, wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ àárín wọn.

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí ọkàn àwọn méjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fà síra wọn láìjẹ́ pé wọ́n ti ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn sọ́nà? Ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀rọ̀ irú wọn sábà máa ń yọrí sí. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn máa dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ wa mọ́tò tí kò ní táyà. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin náà á wá rí i pé àwọn kàn ń gbéra àwọn gẹṣin aáyán lásán ni. Àwọn kan tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa ṣe àwọn ohun tí kò dáa. Àwọn míì máa ń já ara wọn jù sílẹ̀ nígbà tó bá yá, èyí sì lè mú kó máa ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ti dalẹ̀ ara wọn, ó lè fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sì pàápàá. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà lọ́wọ́ kó má bàa kó sínú ewu tó wà nínú kéèyàn tọrùn bọ ọ̀ràn ìfẹ́ nígbà tí kò tíì dàgbà tó?—Oníwàásù 11:10.

Àṣírí ibẹ̀ ni pé kí ìwọ àti ọmọ rẹ jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa lórí ọ̀rọ̀ bíbá àwọn ọkùnrin (tàbí obìnrin) ṣọ̀rẹ́. Ìyẹn á jẹ́ kí o lè tètè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, tí wàá sì lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́, tó bá di pé ọ̀rọ̀ òun àti ẹni kan ti ń kọjá ti ọ̀rẹ́ lásán.

Láìmọ̀, àwọn òbí míì kì í fẹ́ bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí wọ́n ń fẹ́. Wo ohun tí àwọn ọ̀dọ́ kan sọ fún àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn Jí!

“Ó máa ń wù mí kí n bá mọ́mì mi sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí ọkàn mi ń fà sí, àmọ́ mi ò kì ń lè sọ ọ́ torí mo máa ń rò ó pé wọ́n lè lọ gbé ọ̀rọ̀ mi gbòdì.”—Cara.

“Ìgbàkigbà tí mo bá sọ fún mọ́mì mi nípa ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn mi ń fà sí, ohun tí wọ́n máa ń sọ fún mi kò ju pé ‘Má retí pé màá wà níbi tẹ́ ẹ ti máa ṣègbéyàwó o!’ dípò kí wọ́n tiẹ̀ bi mí nípa ẹni yẹn àti ohun tó mú kí n fẹ́ràn ẹ̀. Ká ní mọ́mì mi ti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ni, ì bá rọrùn fún mi láti gba ìmọ̀ràn wọn.”—Nadeine.

Àmọ́, wo ohun tó máa ń yọrí sí tí àwọn òbí bá fara balẹ̀, tí wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn sọ tinú wọn, tí wọ́n sì fún àwọn ọmọ náà ní ìmọ̀ràn tó wúlò.

“Àwọn òbí mi kò bínú sí mi nígbà tí mo sọ fún wọn nípa ọmọkùnrin kan tí ọkàn mi ń fà sí. Ohun tó yẹ kí wọ́n sọ fún mi ni wọ́n sọ, àmọ́ wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi. Torí náà, ó rọrùn fún mi láti tẹ́tí sí ìmọ̀ràn wọn, kí n sì wá sọ àwọn nǹkan míì tó wà lọ́kàn mi fún wọn.”—Corrina.

“Ìgbà táwọn òbí mi sọ fún mi nípa ẹni tí ọkàn wọn fà sí nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, tí wọ́n tún sọ fún mi nípa ohun tó fà á tí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àwọn kò fi bọ́ sí i pẹ̀lú àwọn kan, ìyẹn jẹ́ kó rọrùn fún èmi náà láti sọ fún wọn pé ọkàn mi ń fà sí ẹnì kan.”—Linette.

Àmọ́ ṣá o, ó tún yẹ kó o fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan míì wà tó lè mú kí ọkàn ọ̀dọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan nígbà tí ọ̀dọ́ náà kò tíì dàgbà tó.

“Ìgbà kan tí mò ń fẹ́ ọmọkùnrin kan ní bòókẹ́lẹ́, ohun tó fà á kò ju pé ó máa ń tẹ́tí gbọ́ ohun tí mo bá ń sọ, ó sì máa ń mú inú mi dùn.”—Annette.

“Ọmọkùnrin kan wà tó máa ń wù mí pé kí n máa wà lọ́dọ̀ ẹ̀ ṣáá. Ó máa ń gbọ́ tèmi, ìyẹn gan-an sì ni ibi tí mo kù sí. Torí mo máa ń fẹ́ ẹni táá máa gbọ́ tèmi, yálà ẹni náà dáa tàbí kò dáa.”—Amy.

“Táwọn òbí mi bá sọ fún mi tọkàntọkàn pé mo rẹwà tàbí aṣọ tí mo wọ̀ dáa gan-an lára mi, ìyẹn máa ń tẹ́ mi lọ́rùn, kì í sì í jẹ́ kí n máa wá ọkùnrin táá máa sọ irú ọ̀rọ̀ ìwúrí bẹ́ẹ̀ fún mi.”—Karen.

Bi ara rẹ pé:

Kí ni mo lè máa ṣe táá fi máa wu ọmọ mi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà pé kó máa sọ tinú ẹ̀ fún mi?—Fílípì 4:5.

Ǹjẹ́ mo máa ń “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ”?—Jákọ́bù 1:19.

Kí ni mo lè ṣe tí ọmọ mi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà kò fi ní máa wá ẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí á sì máa gba tiẹ̀ lọ síta?—Kólósè 3:21.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ran ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà lọ́wọ́ lórí bí kò ṣe ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ àárín òun àti ọkùnrin (tàbí obìnrin) tó ń bá kẹ́gbẹ́, kó má bàa kó ara rẹ̀ sínú ìṣòro. Ó wà lára àwọn ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ nìgbà tó bá dàgbà.—Kólósè 3:5; 1 Tẹsalóníkà 4:3-6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

c Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tó wà nínú Jí! July–September 2012, ojú ìwé 15 sí 17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌLÀNÀ TÓ O LÈ TẸ̀ LÉ

OHUN TÓ YẸ OHUN TÍ KÒ YẸ

máa báwọn èèyàn  X má ṣe máa wà pẹ̀lú ọkùnrin

ṣeré pa pọ̀ (tàbí obìnrin) kan ṣáá

mọ àwọn tí ò ń bá kẹ́gbẹ́ dáadáa  X má ṣe sọ ọ́ di alábàárò rẹ

ẹ jọ máa sọ̀rọ̀  X má ṣe tage

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

BÍBÁ ÀWỌN ÈÈYÀN ṢỌ̀RẸ́

TÍTAGE

FÍFỌWỌ́ KANRA

DÍDI ARA WA LỌ́WỌ́ MU

FÍFẸNU KONU