ÌTÀN ÀTIJỌ́
Plato
Plato jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kèfèrí ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí. (Ó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 427 sí 347 Sáájú Sànmánì Kristẹni) Inú ìdílé tó gbajúmọ̀ ni wọ́n bí i sí ní ìlú Áténì. Ó sì kàwé dáadáa bí àwọn ọmọ tí wọ́n bí sínú ìdílé ọlọ́lá nílẹ̀ Gíríìkì ṣe máa ń ṣe. Lára àwọn tó fi ṣe àwòkọ́ṣe ni Socrates onímọ̀ ọgbọ́n orí tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Pythagoras, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí àti ìṣirò.
PLATO pa dà sí ìlú Áténì, lẹ́yìn tó rìnrìn àjò yíká ẹ̀bá òkun Mẹditaréníà, tó sì tún lọ́wọ́ sí òṣèlú ní ìlú Sírákúsì, ìyẹn ìlú àwọn Gíríìkì ní àgbègbè Sísílì. Ó sì dá ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti sáyẹ́ǹsì sílẹ̀ ní ìlú Áténì. Ilé ẹ̀kọ́ yìí làwọn èèyàn máa ń pè ní yunifásítì àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yúróòpù. Ibẹ̀ wá di ojúkò fún ìwádìí nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ìṣirò.
BÁWO NI Ọ̀RỌ̀ PLATO ṢE KÀN Ọ́?
Àwọn ẹ̀kọ́ Plato ti nípa tó jọjú lórí ohun tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹlẹ́sìn gbà gbọ́, títí kan àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n rò pé inú Bíbélì làwọn ẹ̀kọ́ náà ti wá. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀kọ́ tí Plato fi kọ́ àwọn èèyàn ni pé ẹ̀mí àwa èèyàn ṣì máa ń wà níbì kan lẹ́yìn tá a bá kú.
“Ẹ̀kọ́ tó sọ pé ọkàn tàbí ẹ̀mí èèyàn kì í kú wà lára ẹ̀kọ́ tí Plato fẹ́ràn jù.”—Ìwé Body and Soul in Ancient Philosophy
Plato nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí èèyàn lẹ́yìn tá a bá kú. Ìwé Body and Soul in Ancient Philosophy tó dá lórí ojú táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nígbà àtijọ́ fi ń wo ẹ̀mí àti ara sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tó sọ pé ọkàn tàbí ẹ̀mí èèyàn kì í kú wà lára ẹ̀kọ́ tí Plato fẹ́ràn jù.” Ó dá a lójú gan-an pé “ẹ̀mí lè jáde kúrò nínú ara láti lọ gba ìbùkún tàbí kó lọ jìyà” lẹ́yìn téèyàn bá ti kú. Ó gbà pé bí onítọ̀hún bá ṣe lo ayé rẹ̀ ló máa pinnu ibi tó máa lọ. *
BÁWO NI ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ PLATO ṢE GBILẸ̀?
Nígbà tí ilé ìwé tí Plato dá sílẹ̀ ṣì wà, ìyẹn láàárín ọdún 387 sí 529 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó nípa lórí àwọn èèyàn gan-an. Àwọn ẹ̀kọ́ Plato sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmú ń ṣàkóso. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti Philo ará Alẹkisáńdíríà tí òun náà jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí lára àwọn Júù gba àwọn ẹ̀kọ́ Plato gbọ̀. Bí ẹ̀kọ́ àwọn kèfèrí onímọ̀ ọgbọ́n orí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọnú ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Júù àti tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn, títí kan ẹ̀kọ́ pé ẹ̀mí èèyàn máa ń lọ síbì kan téèyàn bá kú.
Ìwé atúmọ̀ èdè The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Dé ìwọ̀n àyè kan, ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì, pàápàá àwọn ẹ̀kọ́ Plato, wà lára ẹ̀kọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn onímọ̀ èrò orí tí wọ́n jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì ṣì ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ Plato lárugẹ.” Tún wo ohun tí àwọn ìwé kan sọ.
Ohun Tí Plato Sọ: Téèyàn bá kú, “onítọ̀hún yẹn gangan, ìyẹn ẹ̀mí tàbí ọkàn èèyàn tí kì í kú, máa gbéra lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run láti lọ jíhìn ohun tó gbé ilé ayé ṣe. Ẹ̀rù kò ní ba ẹni tó bá ṣe rere láti jẹ́jọ́, àmọ́ jìnnìjìnnì máa ń bo àwọn oníṣẹ́ èṣù.”—Ìwé Plato—Laws, Apá Kọkànlá.
Ohun Tí Bíbélì Sọ: Èèyàn fúnra rẹ̀ ni ọkàn, ìyẹn ló sì ṣàpẹẹrẹ ẹ̀mí rẹ̀. Ọkàn ni àwọn ẹranko pàápàá. Tí èèyàn bá kú, o ti di aláìsí nìyẹn, ẹ̀mí tàbí ọkàn rẹ̀ kò sí níbì kankan. * Wo ohun táwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ:
-
“Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.”—1 Kọ́ríńtì 15:45.
-
“Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹran tí ń rìn ká àti ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé.’”—Jẹ́nẹ́sísì 1:24.
-
“Jẹ́ kí ọkàn mi kú.”—Númérì 23:10.
-
“Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.”—Ìsíkíẹ́lì 18:4.
Ó ṣe kedere pé, Bíbélì kò sọ pé ọkàn tàbí ẹ̀mí èèyàn ṣì máa ń wà níbì kan lẹ́yìn téèyàn bá kú. Torí náà, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀kọ́ Bíbélì ni mo gbà gbọ́ àbí ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti Plato?’
^ ìpínrọ̀ 7 Òótọ́ ni pé Plato ló tan ẹ̀kọ́ tó dá lórí bí ẹ̀mí ṣe ń lọ síbìkan lẹ́yìn téèyàn bá kú kálẹ̀, òun kọ́ ló kọ́kọ́ gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ̀. Ó pẹ́ tí ẹ̀kọ́ yìí ti wà lóríṣiríṣi nínú ẹ̀sìn àwọn kèfèrí àti nínú ẹ̀sìn àwọn ará Íjíbítì àti Bábílónì.
^ ìpínrọ̀ 12 Bíbélì sọ pé àwọn tó ti kú dà bí ẹni tó sùn. Wọ́n ń dúró de àjíǹde. (Oníw. 9:5; Jòh. 11:11-14; Ìṣe 24:15) Tó bá jẹ́ pé ẹ̀mí tàbí ọkàn wọn kò kú, a jẹ́ pé kò sí àjíǹde nìyẹn.