Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | TỌKỌTAYA

Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín

Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Nígbàkigbà tí èdèkòyéde bá ti wáyé láàárín ìwọ àti ọkọ̀ tàbí aya rẹ, ṣe ni ẹ̀yin méjèèjì máa ń láálí ara yín. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti wá mọ́ yín lára débi pé ẹ ò rí ohun tó burú nínú kẹ́ ẹ máa sọ̀rọ̀ líle sí ara yín.

Tí irú nǹkan báyìí bá ń ṣẹlẹ̀ láàárín yín, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé ẹ borí ìṣòro yìí. Àmọ́, ó yẹ kẹ́ ẹ kọ́kọ́ mọ ohun tó ń fa ìṣòro yìí àti ìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ wá nǹkan ṣe sí i.

OHUN TÓ FÀ Á

Inú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ yín dàgbà. Inú ìdílé tí wọ́n ti sábà máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra wọn ni ọ̀pọ̀ tọkọtaya dàgbà sí. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè ti mọ́ wọn lára débi pé àwọn méjèèjì á bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ síra wọn.

Irú eré tẹ́ ẹ ń wò. Lọ́pọ̀ ìgbà, nínú fíìmù àtàwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, ọ̀rọ̀ èébú ni wọ́n sábà máa ń fi ṣàwàdà. Àwọn tó ń wò ó á sì gbà pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.

Àṣà. Àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan gbà pé ọkùnrin gidi gbọ́dọ̀ máa pàṣẹ wàá tàbí kí obìnrin máa kanra, kó sì máa bínú kí ọkọ rẹ̀ má bàa sọ ọ́ di ẹrú. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín irú tọkọtaya bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń mú ara wọn lọ́tàá, tí wọ́n á sì máa láálí ara wọn dípò kí wọ́n jọ yanjú ọ̀rọ̀.

Ohun yòówù kó fà á, tí tọkọtaya bá ń sọ̀rọ̀ líle sí ara wọn, ó lè tú ìdílé wọn ká, ó sì tún lè fa àìsàn sí wọn lára. Àwọn kan máa ń sọ pé ọ̀rọ̀ máa ń duni ju ẹgba lọ. Àpẹẹrẹ kan rèé, obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ máa ń lù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ẹnu ọkọ̀ mi máa ń dùn mí ju kó lù mí lọ. Ó tẹ́ mi lọ́rùn kó lù mí ju kó máa sọ̀rọ̀ burúkú sí mi.”

Kí ni ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lè ṣe tí ọ̀rọ̀ líle bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ da àárín yín rú?

OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE

Fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò. Ká ní ìwọ ni ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ sí, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Ìyẹn lè jẹ́ kó o mọ bọ́rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára òun náà.Ǹjẹ́ o lè rántí ìgbà kan tó o sọ̀rọ̀ ìbínú sí aya tàbí ọkọ rẹ? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó o sọ ṣe pàtàkì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára ẹnì kejì rẹ. Dípò ọ̀rọ̀ líle tó o sọ sí i, ọ̀rọ̀ tútù wo ló yẹ kó o sọ nígbà yẹn? Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”—Òwe 15:1.

Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya tó ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Tó bá jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti sábà máa ń sọ̀rọ̀ lílé síra wọn lo dàgbà sí, tẹ̀ lẹ́ àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya tó ń ṣe dáadáa. Ẹ fara wé àwọn tọkọtaya tó ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bára wọn sọ̀rọ̀.—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 3:17.

Rántí bẹ́ ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara yín tẹ́lẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, èrò téèyàn bá ní nípa ẹnì kejì ló máa ń mú kó sọ̀rọ̀ kòbákùngbé. Torí náà, ohun rere ni kó o máa ro nípa ọkọ tàbí aya rẹ. Máa rántí bẹ́ ẹ ṣe jọ máa ń ṣeré tẹ́lẹ̀. Máa wo àwọn fọ́tọ̀ tẹ́ ẹ jọ yà. Àwọn nǹkan wo ló máa ń pa yín lẹ́rìn-ín? Àwọn ìwà wo lẹ rí lára yín tó jẹ́ kẹ́ ẹ fẹ́ra?—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 6:45.

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ ni kó o sọ. Dípò kó o máa na ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́gba ọ̀rọ̀, bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára tìẹ ni kó o sọ. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó o sọ pé: “Ó ti mọ́ ẹ lára láti máa dá ìpinnu ṣe láì jẹ́ kí n mọ̀!” ì bá dáa kó o sọ pé: “Ó máa ń dùn mí tó o bá dá ìpinnu ṣe láì kọ́kọ́ jẹ́ kí n mọ̀.”—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 4:6.

Mọ ìgbà tó yẹ kó o dákẹ́. Tó o bá rí i pé inú ti ń bí ẹ gan-an, tí ọ̀rọ̀ sì ti ń le, á dáa kó o dákẹ́, kẹ́ e sì sọ ọ̀rọ̀ yẹn dìgbà míì. Kò sí ohun tó burú tó o bá kúrò níbẹ̀ títí dìgbà tí ọ̀rọ̀ náà á fi rọlẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 17:14.

Lọ́pọ̀ ìgbà, èrò téèyàn bá ní nípa ẹnì kejì ló máa ń mú kó sọ̀rọ̀ kòbákùngbé