Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Ítálì

Lọ́dún 2011, iye kẹ̀kẹ́ tí wọ́n tà lórílẹ̀-èdè Ítálì pọ̀ ju iye ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n tà lọ. Lára ohun tí wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó fà á ni ọrọ̀ ajé tó ń ṣe ségesège, owó epo tó ga sókè àti iye téèyàn fi ń bójú tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àbójútó kẹ̀kẹ́ ní tiẹ̀ kì í náni lówó púpọ̀, ó sì rọrùn láti lò.

Àméníà

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé ńṣe ni ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà fi ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́tàdínlógún kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n, látàrí bí wọ́n ṣe tì wọ́n mọ́lé nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú kan lábẹ́ àbójútó àwọn ológun. Ilé Ẹjọ́ náà sì sọ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà san owó ìtanràn àti owó ẹjọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàdínlógún náà.

Japan

Ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún lára àwọn ọmọdé tó kó sí páńpẹ́ àwọn èèyànkéèyàn látorí àwọn ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló jẹ́ pé àwọn òbí wọn kò kìlọ̀ fún wọn rí nípa ewu tó wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n ṣèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kàndínlẹ́gbẹ̀ta [599] kan, wọ́n rí i pé tá a bá kó àwọn ọ̀daràn mẹ́wàá jọ lára àwọn tó ń fi ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tú àwọn ọmọdé jẹ, ó ju méje lọ nínú wọn tó sọ pé ìdí táwọn fi ń lo àwọn ìkànnì náà ni láti wá àwọn ọmọdé táwọn máa bá ṣèṣekúṣe.

Ṣáínà

Nítorí pé ìjọba fẹ́ dènà sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í dín iye ọkọ̀ tuntun tí wọ́n ń fún ní ìwé ìrìnnà ọkọ̀ kù láwọn ìpínlẹ̀ pàtàkì-pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìrìnnà ọkọ̀ tí ìlú Beijing máa fún àwọn èèyàn lọ́dọọdún kò ní ju ọ̀kẹ́ méjìlá [240,000] lọ. Ní oṣù August 2012 ṣe ló dà bí ìgbà táwọn èèyàn ta á wò bóyá wọ́n á jẹ, torí àwọn tó fẹ́ gbàwé ìrìnnà ọkọ̀ tó nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [1,050,000], àmọ́ àwọn ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [19,926] nìkan ló rí i gbà. Èyí fi hàn pé ní ìpíndọ́gba, ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́tàléláàádọ́ta [53] péré ló rí ìwé ìrìnnà ọkọ̀ gbà.