Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Gidi?

Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Gidi?

NÍ December 25, ọdún 2010, obìnrin ẹni ọdún méjìlélógójì [42] kan, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kọ ọ̀rọ̀ sórí ìkànnì àjọlò kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé òun fẹ́ pa ara òun. Ọ̀rọ̀ tí obìnrin yìí kọ fi hàn pé ńṣe ló fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ tí obìnrin yìí ní lórí ìkànnì àjọlò lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000], kò sí ẹnì kankan nínú wọn tó ràn án lọ́wọ́. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ kejì òkú obìnrin yìí làwọn ọlọ́pàá rí. Ṣe ló gbé oògùn jẹ.

Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òde òní ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò. Ṣe lèèyàn á kàn fi orúkọ wọn kún orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ téèyàn ní lórí ìkànnì. Tí kò bá sì wù wá láti bá ẹnì kan nínú wọn ṣọ̀rẹ́ mọ́, ṣe la kàn máa yọ orúkọ onítọ̀hún kúrò. Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ ni kò ní ọ̀rẹ́ gidi. Kódà, ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti bá ara wọn ṣọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn ọ̀rẹ́ gidi ṣọ̀wọ́n.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ gidi, ó sì ṣeé ṣe kíwọ náà gbà bẹ́ẹ̀. O sì lè máa wò ó pé kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ gidi kọjá ọ̀rẹ́ orí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà. Ó dáa, irú ìwà wo ló wù ẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ ní? Báwo ni ìwọ fúnra rẹ ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi? Kí léèyàn lè ṣe tó bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tó máa wà pẹ́ títí?

A máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlànà mẹ́rin kan tó lè tọ́ ẹ sọ́nà. Ronú lórí wọn, kó o sì tún kíyè sí bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè mú kó o jẹ́ ẹni táwọn èèyàn máa fẹ́ bá ṣọ̀rẹ́.

1. Jẹ́ Káwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ Mọ̀ Pé Ọ̀rọ̀ Wọn Jẹ Ẹ́ Lógún

Ọ̀rẹ́ gidi kò ní fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré, ọ̀rọ̀ rẹ máa jẹ ẹ́ lógún gan-an, ó sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ. Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ yìí kò gbọ́dọ̀ fì sápá kan, ẹ̀yin méjèèjì lẹ gbọ́dọ̀ sapá, ó sì gba pé kẹ́ ẹ máa ran ara yín lọ́wọ́, kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn nígbà míì. Ṣùgbọ́n, àǹfààní tẹ́ ẹ máa rí níbẹ̀ pọ̀ gan-an. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè lo okun mi, àkókò mi àti ohun tí mo bá ní láti fi ran ọ̀rẹ́ mi lọ́wọ́?’ Máa rántí pé, tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ gidi, ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi.

IRÚ ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN FẸ́ KÍ Ọ̀RẸ́ WỌN NÍ

Irene: “Àjọṣe àárín àwọn ọ̀rẹ́ dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ ṣe ọgbà ẹlẹ́wà, ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò àti àbójútó. Kọ́kọ́ sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi. Fi hàn pé o nífèẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ ọ́ lógún. Kó o sì ṣetán láti fara mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ.”

Luis Alfonso: “Lóde òní, tara wọn nìkan làwọn èèyàn mọ̀, wọn kò rí ti ẹlòmíì rò, wọn kì í sì í fẹ́ ran ẹlòmíì lọ́wọ́. Tó o bá wá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ rẹ tọkàntọkàn tí kò sì retí pé kó o ṣe nǹkan kan fún òun láti fi san án pa dà, ó máa jọ ẹ́ lójú gan-an.”

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn. Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.” (Lúùkù 6:31, 38) Ohun tí Jésù ń rọ̀ wá nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni pé ká má ṣe mọ tara wa nìkan, ká sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ gidi. Tó o bá ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lọ́wọ́ láì rétí pé kí wọ́n san án pa dà, wọ́n máa fẹ́ràn rẹ gan-an ni.

2. Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Fàlàlà

Kò sí bí àárín àwọn ọ̀rẹ́ ṣe lè gún láìjẹ́ pé wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Torí náà, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ jọ nífẹ̀ẹ́ sí. Tẹ́tí sílẹ̀ tí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń sọ̀rọ̀, má sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà nù. Máa gbóríyìn fún un, kó o sì máa fún un níṣìírí. Nígbà míì, o lè rí i pé ó yẹ kó o fún ọ̀rẹ́ rẹ ní ìmọ̀ràn tàbí kó o tọ́ ọ sọ́nà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ọ̀rẹ́ gidi máa fi ìgboyà sọ ohun tí kò dáa tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá ṣe, á sì fọgbọ́n tọ́ ọ sọ́nà.

IRÚ ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN FẸ́ KÍ Ọ̀RẸ́ WỌN NÍ

Juan: “Ó yẹ káwọn ọ̀rẹ́ gidi lè bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà, ẹnì kan nínú wọn kò sì ní bínú tóri pé ọ̀rẹ́ òun ò fara mọ́ ohun tóun sọ.”

Eunice: “Mó máa ń mọyì àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú mi tí wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí mi, pàápàá nígbà ìṣòro.”

Silvina: “Ọ̀rẹ́ gidi máa bá ẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, bó tiẹ̀ mọ̀ pé ó lè dùn ẹ́. Àmọ́ kò ní ṣàì sọ ọ́, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ.”

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

“Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Àwọn èèyàn máa ń mọyì ẹ̀ tí ọ̀rẹ́ wọn bá tẹ́tí sí wọn. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwa nìkan la ṣáà fẹ́ máa sọ̀rọ̀, ńṣe là ń sọ pé èrò tiwa ṣe pàtàkì ju tàwọn tó kù lọ. Torí náà, tí ọ̀rẹ́ rẹ bá fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tàbí ohun tó ń dùn ún, ṣe ni kó o fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Má sì dà á sí ìbínú tó bá bá ẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ìwé Òwe 27:6 sọ pé, “Àwọn ọgbẹ́ tí olùfẹ́ dá síni lára jẹ́ ti ìṣòtítọ́.”

3. Má Ṣe Retí Ohun Tó Pọ̀ Jù

Bí a bá ṣe ń sún mọ́ ọ̀rẹ́ wa sí i, ó ṣeé ṣe ká túbọ̀ máa rí àléébù rẹ̀. Àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kì í ṣe ẹni pípé. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ retí pé àwọn ọ̀rẹ́ wa ò ní ṣe àṣìṣe. Dípò ìyẹn, ṣe ló yẹ ká mọyì àwọn ìwà dáadáa tí wọ́n ní, ká sì máa gbójú fo àwọn àṣìṣe wọn.

IRÚ ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN FẸ́ KÍ Ọ̀RẸ́ WỌN NÍ

Samuel: “A sábà máa ń retí ohun tó pọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, ó sì lè jẹ́ pé àwa fúnra wa ò lè ṣe ohun tí à ń retí pé kí wọ́n ṣe. Tá a bá gbà pé àwa náà máa ń ṣàṣìṣe, a sì ń fẹ́ káwọn tá a ṣẹ̀ dárí jì wá, èyí á mú ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.”

Daniel: “Má ṣe retí láé pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kò lè ṣe àṣìṣe. Tí èdèkòyedè bá wáyé, á dáa ká yanjú ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ká sì sapá láti gbé e kúrò lọ́kàn.”

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

Ṣé o máa ń dárí jini?​—Kólósè 3:13, 14

“Nítorí gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Tí a bá gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, àá máa fòye bá àwọn ọ̀rẹ́ wa lò. Èyí á jẹ́ ká lè máa gbójú fo àwọn àṣìṣe kéékèèké tí wọ́n bá ṣe àtàwọn ìwà tó lè múnú bí wa. Bíbelì sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. . . . Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”Kólósè 3:13, 14.

4. Mú Oríṣiríṣi Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́

Lóòótọ́, ó yẹ ká fara balẹ̀ yan àwọn tá a máa bá ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kìkì àwọn tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí kan pàtó tàbí tí wọ́n tọ́ dàgbà nírú ọ̀nà kan pàtó nìkan ni a máa mú lọ́rẹ̀ẹ́. Tí ara wa bá yá mọ́ àwọn èèyàn láìka ọjọ́ orí wọn, ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà tàbí ìlú wọn sí, ó máa mú kí ìgbésí ayé wa ládùn.

IRÚ ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN FẸ́ KÍ Ọ̀RẸ́ WỌN NÍ

Unai: “Tó bá jẹ́ pé àwọn tí ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́, tí ọ̀rọ̀ yín sì jọra nìkan lò ń bá ṣọ̀rẹ́, ṣe ló má dà bí ìgbà tó ò ń wọ aṣọ aláwọ̀ kan náà ṣáá nígbà gbogbo torí pé o fẹ́ràn àwọ̀ náà. Kò sí bó o ṣe fẹ́ràn àwọ̀ náà tó, ó máa sú ẹ tó bá yá.”

Funke: “Bí mo ṣe mú oríṣiríṣi èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́, ti jẹ́ kí n gbọ́n sí i. Mo mọ bí mo ṣe lè bá àwọn tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ sí tèmi àtàwọn tí ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ ṣọ̀rẹ́. Ó sì ti jẹ́ kí ara mi yá mọ́ àwọn èèyàn, kí n sì mú ara mi bá ipò tí mo bá wà mu. Èyí sì mú kí àwọn ọ̀rẹ́ mi fẹ́ràn mi.”

Ṣé ò ń mú oríṣiríṣi èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́?​—2 Kọ́ríńtì 6:13

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

“Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ ní ìdápadà—mo ń sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀—ẹ̀yin, pẹ̀lú, ẹ gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:13) Bíbélì rọ̀ wá pé ká bá oríṣiríṣi èèyàn ṣọ̀rẹ́. Tí o bá ṣe ohun tí Bíbélì sọ yìí, wàá láyọ̀, ẹni ọ̀wọ́n ni wàá sì jẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ.