Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Má Ṣe Sọ Ọmọ Rẹ di Àkẹ́bàjẹ́

Má Ṣe Sọ Ọmọ Rẹ di Àkẹ́bàjẹ́

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ká sọ pé kì í gbọ́, kì í gbà lọmọ rẹ, tó bá ṣáà ti fẹ́ nǹkan àfi kó o ṣe é fún un. Ọjọ́ tó o bá sọ fún un pé kò sí nǹkan tó béèrè báyìí, wàhálà dé nìyẹn. Á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjàngbọ̀n tàbí kó máa ṣe wọ́nran-wọ̀nran débi tá á fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pin ẹ́ lẹ́mìí. Kò sóhun tó o máa sọ tàbí ṣe fun un tára rẹ̀ á fi balẹ̀, àfìgbà tó o bá fún un ní ohun tó o ti sọ tẹ́lẹ̀ pé o kò ní fún un, kó tó jẹ́ kó o sinmi.

Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ pin ẹ́ lẹ́mìí débi tí wà á fi ṣe ohun tó o ti pinnu pé o kò ní ṣe tẹ́lẹ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa bí o ṣe lè ṣeé.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Tí o kò bá fún ọmọ rẹ ní ohun tó fẹ́, ìyẹn ò sọ ẹ́ di ọ̀dájú. Àwọn òbí kan kì í ronú lọ́nà yìí. Wọ́n ní á dáa kó o ṣàlàyé ìdí tí o kò fi fẹ́ ṣe ohun tó fẹ́, kódà wọ́n sọ pé ńṣe ló yẹ kẹ́ ẹ jọ jíròrò nípa ohun tó o fẹ́ ṣe fún un. Má kàn ṣáà sọ pé ‘o kò fún un,’ wọ́n ronú pé tí òbí kan kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ náà lè bínú kó sì máa dì gbọ́ńkú-gbọ́ńkú kiri.

Ká sòótọ́, tí o kò bá ṣe ohun tí ọmọ rẹ ń béèrè, ó lè kọ́kọ́ dùn ún. Àmọ́, ńṣe lò ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé kì í ṣe gbogbo nǹkan téèyàn ń fẹ́ láyé ló máa ń rí, èèyàn sì gbọ́dọ̀ máa ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun téèyàn bá ní. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé o máa ń fún ọmọ rẹ ní gbogbo ohun tó bá béèrè kó má bà a yọ ẹ́ lẹ́nu, ńṣe lò ń kọ́ ọ pé tó bá ti lè fi ẹkún máyé sú ẹ tàbí pin ẹ́ lẹ́mìí, wàá ṣe ohun tó fẹ́. Tó bá yá kò tiẹ̀ ní gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu mọ́, tó o bá sì bá a sọ̀rọ̀, ńṣe ló máa sọ ọ́ di ìbínú. Ó ṣe tán, báwo ni ọmọ kan ṣe máa bọ̀wọ̀ fún òbí tí kò lè dúró lórí ìpinnu rẹ̀.

Tí o kò bá fún ọmọ rẹ ní gbogbo ohun tó ń fẹ́, ńṣe lò ń múra ẹ̀ sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú. Ọmọ náà á mọ béèyàn ṣe ń fi àwọn nǹkan kan du ara ẹ̀. Ọmọ tó bá sì kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì yìí láti kékeré máa mọ béèyàn ṣe ń ní àmúmọ́ra tó bá dàgbà, pàápàá táwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi ìlọ̀kulọ̀ bí ìṣekúṣe tàbí oògùn olóró lọ̀ ọ́.

Bákan náà, tí o kò bá fún ọmọ rẹ ní gbogbo ohun tó fẹ́, ńṣe lò ń múra ẹ̀ sílẹ̀ de ọjọ́ alẹ́. Dókítà kan tó ń jẹ́ David Walsh sọ pé: “Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, kì í ṣe gbogbo nǹkan téèyàn bá fẹ́ ló máa ń rí. A ò sì ṣe àwọn ọmọ wa láǹfààní kankan tá a bá fi ń kọ́ wọn pé gbogbo nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ láyé yìí ni wọ́n máa rí.” a

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ohun tọ́mọ rẹ máa dà lẹ́yìnwá ọ̀la ni kó o gbájú mọ́. Ó dájú pé o fẹ́ kí ọmọ rẹ di géńdé tó dàgbà dénú, ẹni tó ṣeé mú yangàn, tó sì mọ béèyàn ṣe ń kó ara ẹ̀ níjàánu. Àmọ́ tó o bá ń fún un ní gbogbo nǹkan tó bá ṣáà ti fẹ́, ńṣe lò ń ba ọmọ náà jẹ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó di ẹni àmúyangàn. Bíbélì sọ pé: ‘Bí èèyàn bá ń kẹ́ ẹnì kan ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.’ (Òwe 29:21) Torí náà, tí o kò bá fún ọmọ rẹ ní gbogbo ohun tó fẹ́, má rò pé ńṣe lò ń fìyà jẹ ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ tó nílò lò ń fún un, èyí á sì ṣe é láǹfààní tó bá dàgbà.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 19:18.

Ìpinnu rẹ gbọ́dọ̀ ṣe ṣàkó. Ìwọ àtọmọ rẹ kì í ṣe ẹgbẹ́. Torí náà, kò yẹ kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ máa bá ọmọ rẹ fa ọ̀rọ̀ bíi pé o nílò àṣẹ rẹ̀ lórí ìpinnu tó o ṣe. Òótọ́ ni pé bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà, wọ́n gbọ́dọ̀ “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Torí náà, kò sóhun tó burú tó o bá ń gbé èrò ọmọ rẹ yẹ̀ wò lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Síbẹ̀, má ṣe bá àwọn ọmọ rẹ kéékèèké jiyàn lórí ìdí tí o kò fi ní ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Ìdí ni pé, tó o bá ń bá ọmọ rẹ kékeré fa ọ̀rọ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ rẹ máa dà bí àbá lójú rẹ̀, kò sì ní rí i bí ìpinnu tó ṣe ṣàkó.—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 6:1.

Dúró lórí ìpinnu rẹ. Ọmọ rẹ lè rò pé tí òun bá sunkún sí ẹ lọ́rùn tàbí tóun bẹ̀ ẹ́, wàá yí ìpinnu tó o ṣe pa dà. Tí ọmọ rẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe? Ìwé náà Loving Without Spoiling, sọ pe: “Má ṣe jẹ́ kó sunkún nítòsí rẹ, sọ fún un pé, ‘tó bá jẹ́ ẹkún ló ń wù ẹ́ sun, ìyẹn ò kàn mí. Gba inú yàrá lọ kó o lọ sun ẹkún yẹn débi tó o bá lè sun ún dé.’” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn láti ṣe irú ìpinnu yìí, àti pé inú ọmọ náà kò ní dùn, àmọ́ gbogbo agídí tó ń ṣe máa wálẹ̀ lára rẹ̀ tó bá rí i pé o kò yí ìpinnu rẹ pa dà.—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 5:12.

Má kàn kọ ohun tọ́mọ rẹ̀ fẹ́ torí kó lè máa bẹ̀rù rẹ

Má le koko jù. Má kàn kọ ohun tọ́mọ rẹ̀ fẹ́ torí kó lè máa bẹ̀rù rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Àwọn ìgbà míì wà tí wàá ṣe ohun tí ọmọ rẹ fẹ́ pàápàá tó bá jẹ́ pé ohun tó tọ́ ló béèrè. Àmọ́ rí i dájú pé kì í ṣe ẹkún ló fi tì ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. —Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:21.

a Látinú ìwé náà No: Why Kids—of All Ages—Need to Hear It and Ways Parents Can Say It ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.