Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ | ÌDÍLÉ

Nípa Ìdílé

Nípa Ìdílé

Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ń kojú onírúurú ìṣòro, àmọ́ àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà, kí wọ́n sì láyọ̀.

Áfíríkà

Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé, àwọn ìyà gbọ́dọ̀ fún ọmọ ìkókó lọ́mú láàárín wákàtí kan tí wọ́n bá bí i, kí wọ́n má sì fún wọn ní oúnjẹ míì yàtọ̀ sí ọmú nìkan fún oṣù mẹ́fà. Àjọ UNICEF wá sọ pé, láìka ìtọ́ni yìí sí, àwọn kan ṣì ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà nípa pípolówó pé “kò sí ìyàtọ̀ láàárín oúnjẹ ọmọ tí wọ́n ṣe sínú agolo àti ọmú.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Kánádà

Àwọn olùṣèwádìí nílùú Montreal sọ pé tí òbí bá jẹ́ apàṣẹwàá tó sì máa ń le koko, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ rẹ̀ sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ju àwọn ọmọ tí òbí wọn bá ń fi ìfẹ́ bá wí.

ǸJẸ́ O MỌ̀? Ọ̀nà tó dáa jù láti gbà tọ́mọ ti wà lákọ̀ọ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ nínú Bíbélì.—Kólósè 3:21.

Orílẹ̀-èdè Netherlands

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ìdílé ní Netherlands fi hàn pé àwọn òbí tí kì í da ọ̀rọ̀ iṣẹ́ pọ̀ mọ́ ìdílé máa ń ráyè bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ dáadáa ju àwọn òbí tí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ jẹ lógún. Bí àpẹẹrẹ, títẹ àwọn òṣìṣẹ́ láago lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn téèyàn ti délé lè mú kó ṣòro fún àwọn òbí láti fún àwọn ọmọ wọn ní àbójútó tó yẹ.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”—Oníwàásù 3:1.