Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Ti Ṣe?

Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Ti Ṣe?

Tó o bá fẹ́ mọ ẹnì kan dáadáa, ó máa dára kó o mọ àwọn nǹkan tó ti gbé ṣe àti àwọn ìṣòro tó ti borí. Bákan náà, tó o bá fẹ́ mọ Ọlọ́run dáadáa, o ní láti mọ àwọn nǹkan tó ti ṣe. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹnu máa yà ẹ́ láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti ṣe tá à ń jàǹfààní ẹ̀ títí dòní, tó sì máa ṣe wá láǹfààní ní ọjọ́ iwájú.

ỌLỌ́RUN DÁ OHUN GBOGBO FÚN ÀǸFÀÀNÍ WA

Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa atóbilọ́lá, àwọn “ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.” (Róòmù 1:20) “Òun ni Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀, Ẹni náà tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀, àti Ẹni náà tí ó na ọ̀run nípasẹ̀ òye rẹ̀.” (Jeremáyà 10:12) Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ń fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.

Tiẹ̀ wo bí Jèhófà ṣe buyì kún wa, ní ti pé ó dá wa “ní àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé ó dá wa lọ́nà tá a fi lè gbé àwọn ànímọ́ àgbàyanu rẹ̀ yọ dé ìwọ̀n àyè kan. Ó dá wa lọ́nà tí á fi máa wù wá pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ká lè mọyì àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ìwà rẹ̀. Bá a sì ṣe túbọ̀ ń sapá láti fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípa rẹ̀ sílò, àá máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì ládùn. Pabanbarì ẹ̀ ni pé, ó tún mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ òun ká lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Tá a bá wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, àá rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run ṣe kọjá pé kó kàn máa fún wa ní àwọn ohun tó ń gbé ẹ̀mí wa ró. Ó tún ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò fún wa lóríṣiríṣi àti lọ́pọ̀lọpọ̀ ká lè gbádùn ayé wa. Ìwọ̀nba ni èyí kàn jẹ́ nínú àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.

Jèhófà dá ilẹ̀ ayé kí àwa èèyàn lè máa gbé títí láé lórí rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn, kò dá a lásán, ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Sáàmù 115:16; Aísáyà 45:18) Àwọn wo ló fẹ́ kó máa gbé inú rẹ̀, ìgbà wo ló sì fẹ́ kí wọ́n gbé ibẹ̀ dà? “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​—Sáàmù 37:29.

Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, tó sì fi wọ́n sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé láti “máa ro ó, kí wọ́n sì máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:​8, 15) Apá méjì ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wọn pín sí. Ó ní: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà ní ìrètí láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, ó dùn wá pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà lára àwọn “olódodo” tí yóò “ni ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n, a dúpẹ́ pé àìgbọ́ràn wọn kò dá iṣẹ́ Ọlọ́run dúró. A máa tó rí ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun míì tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa.

ỌLỌ́RUN FÚN WA NÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ̀

Orúkọ míì tá a máa ń pe Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa ní Bíbélì? Ìdí pàtàkì tó fi fún wa ni pé ó fẹ́ ká mọ òun. (Òwe 2:​1-5) Lóòótọ́ kì í ṣe gbogbo ìbéèrè tá a lè ní ni Bíbélì dáhùn, àwa náà kúkú mọ̀ pé kò sí ìwé tó lè sọ ohun gbogbo nípa Ọlọ́run. (Oníwàásù 3:11) Síbẹ̀, gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ ká mọ Ọlọ́run. A lè fi òye mọ irú ẹni tó jẹ́ nípa bó ṣe bá àwọn èèyàn lò. A tún lè mọ irú àwọn èèyàn tó fẹ́ràn àti àwọn tó kórìíra. (Sáàmù 15:​1-5) Kódà, a lè mọ irú ìjọsìn tó tẹ́wọ́ gbà, irú ìwà tó fẹ́ ká máa hù àti èrò tó fẹ́ ká ní nípa owó àtàwọn nǹkan ìní. Bákan náà, a lè mọ Jèhófà dáadáa tá a bá kà nípa àwọn ohun tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ṣe àti ohun tó sọ nínú Bíbélì.​—Jòhánù 14:9.

Ìdí míì tí Jèhófà fi fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé ó fẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láyọ̀ kí ayé sì yẹ wá. Jèhófà ń lo Bíbélì láti bá wa sọ̀rọ̀ ká lè mọ ohun tó máa mú kí ìdílé wa láyọ̀, ká tún lè mọ ohun tó máá jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn àti bá a ṣe lè borí àníyàn ìgbésí ayé. Bá a ṣe máa rí i nínú ìwé yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì bíi: Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ó tún ṣàlàyé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe, kí ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ lè ṣẹ.

Ó dájú pé ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló sì wà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ni Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì, ó sì tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún kí wọ́n tó parí ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣì péye nítorí pé Ọlọ́run gangan ló ni ín. (2 Tímótì 3:16) Ó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ìwé àtijọ́ míì. Nígbà tá a fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó wà lóde òní wéra pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìwé Bíbélì àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣì péye. Bákan náà, oríṣiríṣi itú ni àwọn ẹni ibi ti pa kí àwọn èèyàn má bàa túmọ̀ Bíbélì sí èdè míì tàbí kí wọ́n má bàa pín in kiri tàbí kí wọ́n kà á, síbẹ̀ Bíbélì lékè nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Kódà, òun ni ìwé tó délé-dóko jù láyé, òun sì ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù láyé. Ti pé Bíbélì ṣì wà títí dòní olónìí jẹ́ ẹ̀rí pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”​—Aísáyà 40:8.

ỌLỌ́RUN MÁA ṢE OHUN TÓ NÍ LỌ́KÀN

Ohun míì tí Ọlọ́run tún ti ṣe ni pé ó ti pèsè ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó mú kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tí òun ní lọ́kàn láti ṣe fún wa máa ṣẹ. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn ni pé ká máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ nígbà tí Ádámù ti ṣàìgbọ́ràn sí Ọlọ́run, ńṣe ni òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pàdánù àǹfààní láti máa wà láàyè títí láé. “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Àìgbọràn ọmọ aráyé wá fẹ́ mú kó dà bíi pé Ọlọ́run ò ní lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Kí ni Jèhófà wá ṣe?

Jèhófà yanjú ọ̀ràn náà lọ́nà tó gbé àwọn ìwà rẹ̀ yọ. Ó ṣe ìdájọ́ tó yẹ fún Ádámù àti Éfà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, àmọ́ ó ṣí ọ̀nà ìgbàlà fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Ọgbọ́n tí kò láfiwé ni Jèhófà fi bójú tó ọ̀ràn náà. Ẹsẹ̀kẹsè tí wàhálà yẹn ṣẹlẹ̀ ló ti wá ojútùú sí i, ó sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó máa lo Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ láti dá aráyé nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀?

Jèhófà ṣètò kan láti gba aráyé lọ́wọ́ wàhálà tí ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù ti fà, ó rán Jésù wá sí ayé láti kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè, lẹ́yìn náà Jésù fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” * (Mátíù 20:28; Jòhánù 14:6) Ohun tó sì jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe fún Jésù ni pé ẹni pípé bí Ádámù ni òun náà. Àmọ́ Jésù ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ títí dójú ikú. Torí pé Jésù ò dẹ́ṣẹ̀ kankan, kò yẹ kó kú, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi jí i dìde sí ìyè ní ọ̀run. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti ṣe ohun tí Ádámù kò rí ṣe, ìyẹn láti fún aráyé onígbọràn ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. “Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” (Róòmù 5:19) Nípasẹ̀ ìràpadà Jésù, Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa mímú kó ṣeé ṣe fún aráyé láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ nípa Jèhófà látinú bó ṣe yanjú ọ̀ràn tí ìwà àìgbọ́ràn Ádámù dá sílẹ̀. A ti rí i pé kò sí ohunkóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ tí kò fi ní parí ohun tó bá bẹ̀rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló máa “ní àṣeyọrí sí rere.” (Aísáyà 55:11) A tún ti rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ju bá a ṣe rò lọ. “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”​—1 Jòhánù 4:​9, 10.

Bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run “kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa,” ó dá wa lójú pé ó máa “fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú,” gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣèlérí. (Róòmù 8:32) Kí ni àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa? Máa ka ìwé yìí nìṣó.

ÀWỌN NǸKAN WO NI ỌLỌ́RUN TI ṢE? Jèhófà dá àwa èèyàn ká lè máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó pèsè Bíbélì fún wa torí pé ó fẹ́ ká mọ òun. Jèhófà lo Jésù Kristi láti rà wá pa dà, ńṣe ni ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé gbogbo ohun tó ní lọ́kàn pátá ló máa ṣe

^ ìpínrọ̀ 16 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìràpadà, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì wa www.ps8318.com/yo.