ILÉ ÌṢỌ́ No. 2 2020 | Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń béèrè ìbéèrè yẹn. A lè rí ìdáhùn nínú Bíbélì.

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”​—Àdúrà Tí Àìmọye Èèyàn Ń Gbà

Àwọn ìbéèrè wo nípa Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká mọ ìdáhùn wọn ká lè lóye àdúrà yìí?

Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ìjọba Ọlọ́run?

Táwọn èèyàn aláìpé bá ń ṣàkóso ara wọn, kò sí kí wàhálà má ṣẹlẹ̀.

Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

Àwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó jẹ́ ká dá ẹni tó máa di Ọba Ìjọba Ọlọ́run mọ̀. Nínú gbogbo aráyé, ẹnì kan ṣoṣo ló bá ohun tí Bíbélì sọ mu.

Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ náà fẹ́ mọ̀. Báwo ló ṣe dá wọn lóhùn?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Jésù mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro ayé yìí. Kí ni Ìjọba yẹn ti ṣe tó jẹ́ ká gbà bẹ́ẹ̀?

Fi Hàn Nísinsìnyí Pé Ìjọba Ọlọ́run Lo Fara Mọ́!

Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ niyànjú pé kí wọ́n máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, àmọ́ ṣé o ti béèrè rí pé kí ni Ìjọba Ọlọ́run, kí ló sì máa ṣe?