Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Ṣọ̀fọ̀?

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Ṣọ̀fọ̀?

Ṣé àìsàn ti dá ẹ gúnlẹ̀ rí? Àìsàn náà lè lọ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, tí wàá sì gbàgbé ohun tí àìsàn náà fojú ẹ rí. Àmọ́, ẹ̀dùn ọkàn tí ikú ń fà kì í lọ bọ̀rọ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alan Wolfelt sọ nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ Healing a Spouse’s Grieving Heart pé, “ìbànújẹ́ náà kì í kúrò lọ́kàn.” Ó wá fi kún un pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn èèyàn, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ẹ̀dùn ọkàn yẹn máa fúyẹ́.”

Bí àpẹẹrẹ, wo bí Ábúráhámù ṣe hùwà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ kú. Bíbélì sọ pé: “Ábúráhámù sì wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.” Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ó pẹ́ díẹ̀ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ tó fúyẹ́. * Àpẹẹrẹ míì ni ti Jékọ́bù, tí wọ́n parọ́ fún pé ẹranko kan ti pa Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀ jẹ. “Ọ̀pọ̀ ọjọ́” ni ó fi ṣọ̀fọ̀, kò sì sí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kankan tó lè tù ú nínú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ikú ọmọkùnrin rẹ̀ Jósẹ́fù ṣì wúwo lọ́kàn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 23:2; 37:34, 35; 42:36; 45:28.

Ábúráhámù ṣọ̀fọ̀ nígbà tí Sárà ìyàwó rẹ̀ kú

Bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí nìyẹn tí ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn bá kú. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.

  • “Robert ọkọ mi kú ní July 9, 2008. Àárọ̀ ọjọ́ tí ìjàǹbá burúkú yìí ṣẹlẹ̀ kò yàtọ̀ sí àwọn ọjọ́ míì lójú mi. Lẹ́yìn tá a jẹun tán, a fi ẹnu ko ara wa lẹ́nu, a dì mọ́ra bá a ṣe máa ń ṣe lárààárọ̀ kó tó lọ sí ibiṣẹ́, a sì sọ fún ara pé ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ.’ Ó ti lé lọ́dún mẹ́fà báyìí tí ọkọ mi ti kú, síbẹ̀ ọgbẹ́ ọkàn yẹn kò tíì kúrò lọ́kàn mi. Mi ò sì rò pé ìbànújẹ́ náà lè tán lára mi.”—Gail, ẹni ọgọ́ta [60] ọdún.

  • “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ọdún méjìdínlógún [18] tí ìyàwó mi ti kú, mo ṣì ń ṣàárò rẹ̀, mi ò tíì gbé àdánù náà kúrò lára mi. Nígbàkigbà tí mo bá rí ohun tó rẹwà, mo máa ń rántí ìyàwó mi, mo sì máa ń ronú bí inú rẹ̀ ì bá ṣe dùn tó ká sọ pé òun náà rí ohun tí mo rí.”—Etienne, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84].

Òótọ́ kan ni pé ó máa ń dùn wá wọra tí a bá pàdánù ẹnì kan, kì í sì í kúrò lọ́kàn wa bọ̀rọ̀. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ṣe máa ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn yàtọ̀ síra, torí náà kò bọ́gbọ́n mu ká máa ṣàríwísí àwọn míì torí bí wọ́n ṣe ṣe nígbà tí èèyàn wọn kú. Lẹ́sẹ̀ kan náà, kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi tá a bá bara jẹ́ gan-an nígbà téèyàn wa bá kú. Báwo la ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn yìí?

^ ìpínrọ̀ 4 Ísákì ọmọkùnrin Ábúráhámù náà ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Bí a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú ìwé ìròyìn yìí, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ísákì ṣì ń ṣọ̀fọ̀ ikú Sárà ìyá rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:67.