Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?

Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

Bíbélì kò kọ́ wa pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa la ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò wá. Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 18:10) Àmọ́, ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé àwọn áńgẹ́lì máa ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn òun, kì í ṣe pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ó. Torí náà, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kì í fẹ̀mí ara wọn wewu, kí wọ́n wá máa ronú pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa dáàbò bo àwọn.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì kì í ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ni? Rárá o. (Sáàmù 91:11) Ó dá àwọn kan lójú gbangba pé Ọlọ́run ti lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn tó sì tún tọ́ wọn sọ́nà. Kenneth, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú wà lára àwọn tó nírú èrò yìí. Àmọ́, a ò lè sọ bóyá bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń rí i pé àwọn áńgẹ́lì ń darí wa bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n, torí pé a ò lè rí àwọn áńgẹ́lì, kò ṣeé ṣe fún wa láti mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n tó láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́. Síbẹ̀, kì í ṣe àṣìṣe rárá tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tó bá ṣe fún wa.​—Kólósè 3:15; Jákọ́bù 1:​17, 18.