Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dùn

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dùn

“Inú mi máa ń bà jẹ́ gan-an nígbà tí mo bá ráwọn ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, bí ogun, àìsàn, àìríjẹ àìrímu àti bí wọ́n ṣe ń hùwà ìkà sáwọn ọmọdé. Àmọ́ ní báyìí, mo ti wá mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”​—RANI. *

Obìnrin tó ń jẹ́ Rani yìí rí ayọ̀ tòótọ́ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa, Ọlọ́run Olódùmarè, tó jẹ́ orísun ọgbọ́n. Bó o ṣe ń ka ìwé yìí, wàá rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa jẹ́ . . .

  • kí ìdílé ẹ láyọ̀

  • kó o wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn

  • kó o ní ìtẹ́lọ́rùn, kí ọkàn ẹ sì balẹ̀

  • kó o mọ ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà, tá a sì ń kú

  • kó dá ẹ lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa

  • kó o mọ Ẹlẹ́dàá wa, kó o sì sún mọ́ ọn

Wàá tún rí i pé gbogbo èèyàn ló lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run, tí wọ́n bá ṣáà ti lè wá a.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ tá a lò nínú ìwé yìí pa dà.