Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Ń Rí Nínú Àgọ́ Àwọn Olùwá-ibi-ìsádi

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Ń Rí Nínú Àgọ́ Àwọn Olùwá-ibi-ìsádi

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Ń Rí Nínú Àgọ́ Àwọn Olùwá-ibi-ìsádi

KÍ LÓ máa ń wá sí ẹ lọ́kàn nígbà tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi”? Ǹjẹ́ o ti débẹ̀ rí? Báwo tiẹ̀ ni ibẹ̀ ṣe rí gan-an?

Lákòókò tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí, àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi mẹ́tàlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti kọ́ sí apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Tanzania. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ogun ti lé kúrò láwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà mìíràn ni ìjọba orílẹ̀-èdè Tanzania ń pèsè ìrànlọ́wọ́ fún pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR). Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa ń rí nínú àgọ́ yìí?

Tí Wọ́n Bá Kọ́kọ́ Dé Àgọ́

Ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Kandida ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tóun àti ìdílé rẹ̀ dé sí àgọ́ náà lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn. Ó ní: “Wọ́n fún wa ní káàdì kan tó ní nọ́ńbà ìdánimọ̀ nínú láti máa fi gba oúnjẹ, wọ́n sì sọ pé kí ìdílé wa máa lọ sí àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà ní Nyarugusu. Nígbà tá a débẹ̀, wọ́n fún wa ní nọ́ńbà tá a fi máa dá ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa àti àdúgbò wa mọ̀. Wọ́n fi ibi tá a ti máa gé igi àti ẹyá tá a fi máa kọ́ ilé bóńkẹ́ tiwa hàn wá. A yọ búlọ́ọ̀kù alámọ̀. Wọ́n fún wa ní ọ̀rá fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tá a fi borí ilé náà. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni, àmọ́ inú wa dùn nígbà tá a kọ́ ilé kóńkóló náà tán.”

Ọjọọjọ́ Wednesday ọ̀sẹ̀ méjì síra la máa ń lo káàdì tí wọ́n fi ń gba oúnjẹ. Kandida tún sọ pé “Ńṣe la máa ń tò sórí ìlà níbi ilé tí wọ́n ń kó oúnjẹ sí láti gba àwọn ohùn èèlò oúnjẹ látọ̀dọ̀ Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.”

Kí ló máa ń jẹ́ oúnjẹ ẹnì kan lójúmọ́?

“Wọ́n máa ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní kọ́ọ̀bù ìyẹ̀fun àgbàdo mẹ́ta, kọ́ọ̀bù ẹ̀wà pòpòǹdó kan, ogún gíráàmù ìyẹ̀fun ẹ̀wà sóyà, ṣíbí òróró ìsebẹ̀ méjì àti iyọ̀ ṣíbí ìmùkọ kan. Nígbà míì, wọ́n máa ń fún wa ní ọ̀pá ọṣẹ kan tá a máa ń lò fún odidi oṣù kan gbáko.”

Omi tó mọ́ ńkọ́? Ṣé ó wà? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Riziki dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n máa ń fi páìpù abẹ́ ilẹ̀ fa omi látinú odò kan tó wà nítòsí sínú àwọn táǹkì omi ńláńlá. Wọ́n á wá fi kẹ́míkà chlorine sínú omi náà kí wọ́n tó fà á káàkiri àgọ́. A máa ń se omi yìí ká tó mú un kó má bàa kó àìsàn bá wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa wà lẹ́nu omi pípọn àti aṣọ fífọ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. A ò lè rí pọn ju omi korobá kan àtààbọ̀ lójúmọ́.”

Tó o bá gba àárín àgọ́ náà kọjá, wàá rí ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi, ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ẹ̀kọ́ girama níbẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ àwọn àgbà tiẹ̀ lè wà nínú àgọ́ náà pẹ̀lú. Àgọ́ ọlọ́pàá àti ọ́fíìsì ìjọba wà nítòsí láti fi dáàbò bo àgọ́ náà. O tún lè rí ọjà ńlá níbẹ̀ tó ní àwọn ìsọ̀ kéékèèké níbi táwọn olùwá-ibi-ìsádi ti lè rí ewébẹ̀, èso, ẹja, adìyẹ àtàwọn ohun èlò oúnjẹ mìíràn rà. Lára àwọn èèyàn àgbègbè náà máa ń wá ta nǹkan lọ́jà ọ̀hún. Àmọ́ ibo làwọn olùwá-ibi-ìsádi náà ti ń rówó ra nǹkan? Àwọn kan ń dá oko ẹ̀fọ́ níwọ̀nba tí wọ́n á sì wá tà á lọ́jà. Àwọn mìíràn lè tà lára ìyẹ̀fun tàbí ẹ̀wà pòpòǹdó ti wọ́n fún wọn láti rí owó ra ẹran díẹ̀ tàbí èso. Àní, àgọ́ yìí kò jọ àgọ́ mọ́, ó ti di abúlé ńlá. Àwọn èèyàn sábà máa ń wà lọ́jà tí wọ́n á sì máa gbádùn ara wọn bí ẹni pé ìlú wọn ni wọ́n wà.

Tó o bá lọ sí ọsibítù, ọ̀kan lára àwọn dókítà tó wà níbẹ̀ lè sọ fún ọ pé ilé-ìgbàtọ́jú bíi mélòó kan wà nínú àgọ́ tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, pé ọ̀ràn pàjáwìrì tàbí ẹni tára rẹ̀ ò bá yá gan-an ni wọ́n máa ń gbé wá sí ọsibítù. Ó dájú pé ilé ìtọ́jú aláìsàn àti ilé ìgbẹ̀bí tó wà ní ọsibítù náà ṣe kókó gan-an, nítorí pé ní àgọ́ tí ẹgbàá mẹ́rìnlélógún [48,000] àwọn olùwá-ibi-ìsádi wà, àádọ́ta lé rúgba [250] nínú wọn lè bímọ lóṣù kan.

Wọ́n Ń Jẹun Tẹ̀mí Lájẹyó

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lè máa ronú nípa àwọn arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí tó wà láwọn àgọ́ yìí ní Tanzania. Nǹkan bí ẹgbẹ̀fà ni gbogbo wọn, a pín wọn sí ìjọ mẹ́rìnlá a sì dá wọn sí ọ̀nà mẹ́ta. Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn èèyàn yìí?

Lára nǹkan táwọn Kristẹni tòótọ́ yìí ṣe ní gbàrà tí wọ́n dé àgọ́ ni pé wọ́n tọrọ ilẹ̀ tí wọ́n máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí. Èyí á jẹ́ káwọn olùwá-ibi-ìsádi lè mọ ibi tí wọ́n ti lè ráwọn Ẹlẹ́rìí àti ibi tí wọ́n á ti lè ṣe àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìjọ méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú àgọ́ tó wà ní Lugufu, iye àwọn Kristẹni tó ń ṣe déédéé níbẹ̀ sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó dín ẹyọ kan [659]. Láwọn ìpàdé ọjọ́ Sunday, àpapọ̀ èèyàn tó ń wá sípàdé láwọn ìjọ méjèèje sábà máa ń tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700].

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní gbogbo àgọ́ yìí tún máa ń jàǹfààní àwọn àpéjọ ńláńlá táwa Kristẹni máa ń ṣe. Nígbà tí wọ́n ṣe àpéjọ àgbègbè àkọ́kọ́ ní àgọ́ tó wà ní Lugufu, egbèjìlá dín mẹ́tàdínlógójì [2,363] èèyàn ló pésẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí gbẹ́ odò ìrìbọmi sẹ́bàá ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà. Wọ́n gbẹ́ ihò tó jìn, wọ́n wá fi ọ̀rá fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tẹ́ ẹ kó lè gba omi dúró. Àtinú odò kan tó jìnnà tó nǹkan bíi kìlómítà méjì làwọn ará ti fi kẹ̀kẹ́ pọn omi sínú ihò tí wọ́n gbẹ́ yìí. Ogún lítà péré ni wọ́n lè gbé lẹ́ẹ̀kan, èyí ló mú kí wọ́n pààrà fún ọ̀pọ̀ ìgbà. Àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi wọṣọ tó bójú mu, wọ́n sì tò fún ìrìbọmi. Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni gbogbo wọn, a sì ṣèrìbọmi fún wọn nípa rírì wọn bọmi pátápátá. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ní àpéjọ àgbègbè náà sọ pé ogójì èèyàn lòun ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mẹ́rin lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò pé káwọn alábòójútó arìnrìn àjò máa bẹ̀ wọn wò látìgbàdégbà. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Àwọn ará wa nítara gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n ní ìpínlẹ̀ tó tóbi gan-an láti wàásù. Nínú ìjọ kan, Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n wàásù lóṣù kan. Ọ̀pọ̀ ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn tó fìfẹ́ hàn. Aṣáájú ọ̀nà [òjíṣẹ́ alákòókò kíkún] kan sọ pé òun mọ̀ pé òun ò lè rí ìpínlẹ̀ tó dára ju èyí lọ níbòmíràn. Àwọn èèyàn inú àgọ́ wọ̀nyí mọyì àwọn ìtẹ̀jáde wa gan-an.”

Báwo ni ìtẹ̀jáde Bíbélì ṣe ń dénú àwọn àgọ́ náà? Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń kó wọn ránṣẹ́ sí Kigoma, ìyẹn ìlú tó wà níhà ìlà oòrùn Adágún Tanganyika. Ibẹ̀ làwọn ará á ti gba àwọn ìwé wọ̀nyí tí wọ́n á sì ṣètò láti fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Nígbà míì, wọ́n á rẹ́ǹtì ọkọ̀ akẹ́rù tí wọ́n á sì fúnra wọn kó àwọn ìwé náà lọ sí gbogbo àgọ́. Èyí máa ń gbà wọ́n tó ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin láwọn ọ̀nà tó rí págunpàgun.

Ìtìlẹ́yìn Nípa Tara

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Belgium àti ilẹ̀ Switzerland ti ṣe bẹbẹ láti ran àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà láwọn àgọ́ yìí lọ́wọ́. Àwọn kan ti ṣèbẹ̀wò sáwọn àgọ́ yìí ní Tanzania, lẹ́yìn tí wọ́n gbàṣẹ lọ́dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Abẹ́lé àti lọ́dọ̀ Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Yúróòpù ti dá mílíìkì sóyà, aṣọ, bàtà, ìwé ilé ẹ̀kọ́ àti ọṣẹ jọ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Ńṣe làwọn ará fi àwọn ohun èèlò yìí tọrẹ fún gbogbo àwọn olùwá-ibi-ìsádi o, èyí sì bá ìlànà Bíbélì mu pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gálátíà 6:10.

Iṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re yìí ti méso rere jáde o, ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi la ti ràn lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ Àgọ́ Àwọn Olùwá-ibi-ìsádi ní ọ̀kan lára àwọn àgọ́ yìí fi ìmọrírì hàn pé: “Lórúkọ gbogbo èèyàn àgọ́ yìí, a kà á sí àǹfààní ńláǹlà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún iṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re tí ètò àjọ yín ti ṣe fún wa lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ . . . Aṣọ tẹ́ ẹ fún wa kárí ẹgbàá mẹ́fà àti ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́fà [12,654] èèyàn, lọ́kùnrin, lóbìnrin, àti ọmọdé tó fi dórí àwọn ìkókó pàápàá . . . Iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà ní àgọ́ Muyovozi ní lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án [37,000]. Lápapọ̀, ẹ ti ran ẹgbàá mẹ́fà àti ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́fà [12,654] èèyàn lọ́wọ́.”

Ní àgọ́ mìíràn, irínwó lé lẹ́gbàá mẹ́fà ó dín méjìdínlógún [12,382] èèyàn ni wọ́n fún ní aṣọ mẹ́ta mẹ́ta, àgọ́ kan tún gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé àwọn ọmọ ilé ìwé girama, ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti jẹlé-ó-sinmi. Òṣìṣẹ́ kan láti ilé iṣẹ́ Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lágbègbè náà sọ pé: “Inú wa dùn púpọ̀ fáwọn ọrẹ tá a rí gbà [láti lò] fún àìní àwọn èèyàn tó wà láwọn àgọ́ olùwá-ibi-ìsádi. Ẹnu àìpẹ́ yìí la gba àpótí ìkẹ́rùránṣẹ́ ńláńlá márùn-ún tó kún fún àwọn ìwé ilé ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ àdúgbò sì ti pín wọn fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi. . . . Ẹ ṣeun púpọ̀ púpọ̀.”

Kódà àwọn ìwé ìròyìn àdúgbò ti sọ̀rọ̀ nípa ìrànlọ́wọ́ yìí. Àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn Sunday News ti May 20, 2001, sọ pé: “Aṣọ Ń Bọ̀ Lọ́nà Fáwọn Olùwá-Ìbi-Ìsádi ní Tanzania.” Ìtẹ̀jáde ti February 10, 2002, sọ pé: “Àwọn olùwá-ibi-ìsádi mọrírì àwọn ọrẹ wọ̀nyí gan-an nítorí pé lára àwọn ọmọ tí ò lè lọ sílé ìwé mọ́ nítorí àìrí aṣọ wọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ báyìí.”

Ipò Nǹkan Le fún Wọn àmọ́ Wọ́n Ń Rí Ìrànlọ́wọ́

Ó máa ń gba nǹkan bí ọdún kan gbáko kí ìgbésí ayé nínú àgọ́ tó mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi yìí lára. Ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ ni wọ́n ń gbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn àgọ́ yìí ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn láti sọ ìhìn rere tó ń tuni nínú látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn aládùúgbò wọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi. Wọ́n ń sọ fáwọn yẹn nípa ayé tuntun kan, níbi tí gbogbo èèyàn “yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Lákòókò náà, gbogbo èèyàn “yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.” Pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run, ó ṣe kedere pé ayé kan tí ò ti ní í sí àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi lèyí máa jẹ́.—Míkà 4:3, 4; Sáàmù 46:9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn ilé àgọ́ tó wà ní Nduta

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Lukole (apá ọ̀tún) Àwọn èèyàn ń ṣe ìrìbọmi ní Lugufu (apá ìsàlẹ̀)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àpéjọ Àgbègbè ní àgọ́ tó wà ní Lugufu