Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà

ỌKÙNRIN kan wà tó ń jẹ́ Pascal. Àdúgbò kan táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ló ń gbé. Àmọ́, bó ṣe ń dàgbà ló ń wá bó ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìyà kó sì máa gbádùn ayé rẹ̀. Níwọ̀n bó ti fẹ́ràn kó máa kan ẹ̀ṣẹ́ ṣeré, ó máa ń ronú pé, ‘Báwo lèmi náà ṣe lè di abẹ̀ṣẹ́-kù-bí-òjò, kí n di olókìkí, kí n sì di ọlọ́rọ̀?’ ‘Nígbà tó tó nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], ó pinnu pé ilẹ̀ Yúróòpù lòun máa lọ. Àmọ́ kò ní lè wọ ilẹ̀ Yúróòpù lọ́nà tó bófin mu torí pé kò ní ìwé ìrìnnà kankan.

Lọ́dún 1998, nígbà tí Pascal ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27], ó mú ìrìn àjò rẹ̀ pọ̀n. Ó forí lé ẹnubodè tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Gánà àti Tógò. Láti Tógò, ó kọjá sí orílẹ̀-èdè Benin. Nígbà tó ṣe, ó dé ìlú Birni Nkonni lórílẹ̀-èdè Niger. Láti ìlú yẹn ló ti máa wá bẹ̀rẹ̀ apá tó léwu jù lọ nínú ìrìn-àjò náà. Torí pé kò rọrùn rárá láti rìnrìn àjò lọ sí apá àríwá, ó ní láti ta mọ́ ọkọ̀ akẹ́rù tó máa gbé e sọdá Aṣálẹ̀ Sàhárà. Tó bá wá dé òkun Mẹditaréníà, á wọ ọkọ̀ ojú omi tó máa gbé e dé ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tó pinnu láti ṣe nìyẹn, àmọ́ ohun méjì ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Niger tí kò jẹ́ kó lè dé Yúróòpù.

Ohun àkọ́kọ́ ni pé owó tán lọ́wọ́ rẹ̀. Èkejì ni pé, ó rí aṣáájú-ọ̀nà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Noé tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé ojú tó fi ń wo ìgbésí ayé yí pa dà. Bó ṣe di pé ó fi àwọn nǹkan tó máa mú kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run rọ́pò owó àti òkìkí tó ń lépa tẹ́lẹ̀ nìyẹn o. Nígbà tó di oṣù December ọdún 1999, Pascal ṣèrìbọmi. Kó lè fi hàn pé òun moore tí Jèhófà ṣe fóun, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ọdún 2001 lórílẹ̀-èdè Niger, ìyẹn ní ìlú tí wọ́n ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo ló ṣe ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣe sí? Ó fi ìdùnnú sọ pé, “Ìsinsìnyí gan-an ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń gbádùn ìgbésí ayé mi jù lọ!”

WỌ́N GBÁDÙN ÌGBÉSÍ AYÉ WỌN GAN-AN NÍ ÁFÍRÍKÀ

Anne-Rakel

Bíi ti Pascal, ọ̀pọ̀ ti wá rí i pé èèyàn máa túbọ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn tó bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Èyí ló mú kí àwọn kan ti ilẹ̀ Yúróòpù wá sí Áfíríkà kí wọ́n lè lọ sìn láwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Kódà, àwọn èèyàn tó tó márùndínláàádọ́rin [65] tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sí àádọ́rin [70] ọdún ló ti fi ilẹ̀ Yúróòpù sílẹ̀ láti wá sìn ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, láwọn orílẹ̀-èdè bíi Benin, Burkina Faso, Niger àti Tógò. * Kí ló mú kí wọ́n fi ilé àtọ̀nà wọn sílẹ̀? Báwo ni nǹkan sì ṣe rí fún wọn?

Arábìnrin Anne-Rakel tó wá láti orílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Àwọn òbí mi sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Senegal. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń fi ìdùnnú sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì, èmi náà sì fẹ́ kí ìgbésí ayé mi rí bíi tiwọn.” Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sẹ́yìn, Anne-Rakel kó lọ sí orílẹ̀-èdè Tógò láti sìn, ó sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití. Nígbà tá à ń wí yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ ní ọmọ ogún [20] ọdún ni. Báwo ni ohun tó ṣe yìí ṣe fún àwọn míì níṣìírí? Ó sọ pé: “Nígbà tó ṣe, àbúrò mi obìnrin àti àbúrò mi ọkùnrin wá bá mi ní Tógò.”

Albert-Fayette àti Aurele

 Arákùnrin kan tó ti ṣe ìgbéyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aurele, tó wá láti ilẹ̀ Faransé tó sì ti pé ẹni àádọ́rin [70] ọdún sọ pé: “Nígbà tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn, mo láǹfààní láti yan ohun tí mo fẹ́. Mo lè yàn láti rọra máa gbádùn ara mi ní ilẹ̀ Faransé kí n sì máa retí ìgbà tí Párádísè máa dé tàbí kí n wá bí màá ṣe mú iṣẹ́ ìsìn mi gbòòrò sí i.” Ńṣe ni Aurele pinnu láti mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gbòòrò sí i. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, òun àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Albert-Fayette kó lọ sí orílẹ̀-èdè Benin. Aurele sọ pé: “Kò sóhun tá a lè fi wé bá a ṣe yọ̀ǹda ara wa láti wá sin Jèhófà níbí.” Ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó tún wá sọ pé: “Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ibì kan wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tó jẹ́ etí òkun, tó máa ń rán mi létí Párádísè.”

Ní ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sẹ́yìn, Arákùnrin Clodomir àti ìyàwó rẹ̀ Lysiane wá sí orílẹ̀-èdè Benin láti ilẹ̀ Faransé. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀, àárò ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé máa ń sọ wọ́n gan-an, ẹ̀rù sì máa ń ba tọkọtaya náà pé bóyá ni ibẹ̀ máa mọ́ àwọn lára. Àmọ́ wọ́n wá rí i pé kò sídìí fáwọn láti máa bẹ̀rù, torí pé wọ́n ń rí ayọ̀ púpọ̀. Clodomir wá sọ pé: “Láti ọdún mẹ́rìndínlógún [16] tá a ti wà níbí, ọdún kan ò lè kọjá ká má ran èèyàn kan lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà.”

Lysiane àti Clodomir pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n ti ràn lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́

Johanna and Sébastien

Arákùnrin Sébastien àti ìyàwó rẹ̀ Johanna náà kúrò nílẹ̀ Faransé láti wá sìn ní orílẹ̀-èdè Benin lọ́dún 2010. Sébastien sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló nílò àbójútó nínú ìjọ. Bá a ṣe ń sìn níbí wá dà bí ìgbà téèyàn ń yára gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń bójú tó nǹkan nínú ètò Ọlọ́run.” Ṣé àwọn èèyàn máa ń tẹ́tí sílẹ̀ lóde ẹ̀rí? Johanna sọ pé: “Òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ àwọn èèyàn gan-an. Lọ́jọ́ tá ò bá tiẹ̀ jáde òde ẹ̀rí pàápàá, àwọn èèyàn máa ń dá wa dúró ní òpópónà láti bi wá láwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì, kí wọ́n sì tún gba àwọn ìtẹ̀jáde wa.” Ipa wo ni ìṣípòpadà yìí ní lórí ìgbéyàwó wọn? Sébastien sọ pé: “Ó mú ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa gan-an. Inú mi máa ń dùn bí èmi àtìyàwó mi ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, látàárọ̀ ṣúlẹ̀.”

Aṣáájú-ọ̀nà ni Arákùnrin Eric àti ìyàwó rẹ̀ Katy, apá àríwá orílẹ̀-èdè Benin níbi táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí ni wọ́n ti ń sìn. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilẹ̀ Faransé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, wọ́n sì tún máa ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Èyí ló mú kó máa wù wọ́n láti lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì gbéra nígbà tó di ọdún 2005. Wọ́n rí ìbísí tó kọyọyọ níbẹ̀. Eric sọ pé: “Ní ọdún méjì sẹ́yìn, gbogbo àwa akéde tá a wà nínú àwùjọ tó wà nílùú Tanguiéta ò ju mẹ́sàn-án lọ, àmọ́, ní báyìí a ti pé ọgbọ̀n [30]. Láwọn ọjọ́ Sunday, àwọn bí àádọ́ta [50] sí ọgọ́rin [80] ló máa ń wá sí ìpàdé. Ìbísí tá à ń rí yìí máa ń mú ká láyọ̀ gan-an ni!”

Katy àti Eric

BÍ WỌ́N ṢE BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO TÓ YỌJÚ

Benjamin

Àwọn ìṣòro wo ni díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní? Àbúrò Arábìnrin Anne-Rakel  ni Arákùnrin Benjamin. Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] ni. Lọ́dún 2000, nígbà tó wà ní orílẹ̀-èdè Denmark, ó pàdé míṣọ́nnárì kan tó ń sìn lórílẹ̀-èdè Tógò. Benjamin sọ pé: “Nígbà tí mo sọ fún míṣọ́nnárì náà pé mo fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sọ fún mi pé: ‘Ǹjẹ́ o mọ̀ pé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè Tógò?’” Benjamin ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún nígbà yẹn, àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjì ti ń sìn lórílẹ̀-èdè Tógò. Ìyẹn ló mú kó rọrùn fún mi láti lọ síbẹ̀.” Bó ṣe gbéra nìyẹn. Àmọ́ ó ní ìṣòro kan. Kí ni ìṣòro náà? Benjamin sọ pé: “Mi ò gbọ́ dòò nínú èdè Faransé. Oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ nira fún mi gan-an torí pé tá-tà-tá ni mò ṣì ń sọ.” Àmọ́, nígbà tó yá, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ní báyìí, Benjamin ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Benin, ó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń fi ìwé ránṣẹ́, ó sì tún ń ran ẹ̀ka tó ń bójú tó kọ̀ǹpútà lọ́wọ́.

Marie-Agnès àti Michel

Kí Arákùnrin Eric àti ìyàwó rẹ̀ Katy tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan tó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Benin, wọ́n ti kọ́kọ́ sìn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan táwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè wà ní orílẹ̀-èdè Faransé. Àmọ́, báwo ni ibi tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ sìn yẹn ṣe yàtọ̀ sí ti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà? Katy sọ pé: “Ó ṣòro gan-an ká tó rí ilé tó tẹ́ wa lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ oṣù la fi gbé nínú ilé tí kò ní iná àti omi.” Eric wá fi kún un pé: “Ládùúgbò tá a wà, ńṣe ni wọ́n máa ń yí orin sókè gan-an, á sì wà bẹ́ẹ̀ títí dòru. Àfi kéèyàn gba kámú nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kó sì fi gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ṣe osùn kó fi para.” Tọkọtaya yìí gbà pé: “Téèyàn bá lọ wàásù ní ilẹ̀ tí ọ̀pọ̀ kò tíì gbọ́ ìwàásù rí, ayọ̀ téèyàn máa ń rí kò láfiwé rárá. Ayọ̀ yẹn sì máa ń mú kéèyàn gbàgbé ìṣòro téèyàn ní.”

Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni Arákùnrin Michel àti ìyàwó rẹ̀ Marie-Agnès kúrò nílẹ̀ Faransé tí wọ́n sì wá sí orílẹ̀-èdè Benin. Wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́ta [60] ọdún báyìí. Wọ́n kọ́kọ́ ń ṣàníyàn kó tó di pé wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Benin. Michel sọ pé: “Àwọn kan sọ pé ńṣe ni lílọ tá a lọ síbẹ̀ dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń rìn lórí igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n gbé dábùú kòtò gìrìwò kan, tó sì ń ti ẹrù ńlá kọjá lórí rẹ̀. Tó wá jẹ́ pé àwa gan-an ni ẹrù tí ẹni náà ń tì! Ìyẹn tó láti dẹ́rù bani téèyàn ò bá mọ̀ pé Jèhófà ló ń ti ẹrù náà. Torí náà, iṣẹ́ Jèhófà ń lọ ṣe, àwa àti Jèhófà la sì jọ ń lọ.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE

Àwọn tí wọ́n ti sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i sábà máa ń tẹnu mọ́ ọn pé kéèyàn múra sílẹ̀ dáadáa kó sì tẹ̀ lé àwọn àbá wọ̀nyí: Ṣe àwọn ètò tó bá yẹ ṣáájú. Kọ́ bó o ṣe lè mú ara rẹ bá ipòkípò tó o bá bá ara rẹ mu. Má ṣe náwó kọjá iye tó o ti pinnu pé wàá máa ná. Gbára lé Jèhófà.—Lúùkù 14:28-30.

Arákùnrin Sébastien tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ká tó lọ, ọdún méjì lèmi àti ìyàwó mi fi tọ́jú owó pa mọ́. A dín iye tá à ń ná lórí àwọn eré ìtura kù, a ò sì ra àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan.” Wọ́n tún máa ń lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dọọdún láti lọ ṣiṣẹ́ fún oṣù mélòó kan kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa sìn nìṣó nílẹ̀ òkèèrè. Èyí wá ń mú kí wọ́n lè máa fi àwọn oṣù tó kù nínú ọdún náà ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Benin.

Marie-Thérèse

 Marie-Thérèse jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arábìnrin ogún [20] tí ò tíì lọ́kọ tí wọ́n ti ilẹ̀ òkèèrè lọ sìn níbi tá a ti túbọ̀ nílò àwọn oníwàásù ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Awakọ̀ bọ́ọ̀sì ni arábìnrin yìí nígbà tó wà ní ilẹ̀ Faransé; àmọ́, nígbà tó di ọdún 2006 ó gbàyè ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ kó lè lọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Niger. Ńṣe ni iṣẹ́ ìwàásù náà ń dùn mọ́ ọn débi pé kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ayọ̀ tòun ń fẹ́ ní ìgbésí ayé òun gan-an lòun ń rí yìí. Marie-Thérèse wá sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo pa dà sí ilẹ̀ Faransé mo sọ fún ọ̀gá mi pé mo fẹ́ yí bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ pa dà. Ó sì gbà láìjanpata. Ní báyìí, láti oṣù May sí August, mo máa ń ṣiṣẹ́ awakọ̀ bọ́ọ̀sì ní ilẹ̀ Faransé, àmọ́ láti oṣù September sí oṣù April mo máa ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Niger.”

Saphira

Ó yẹ kó dá àwọn tí wọ́n ń ‘wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’ lójú pé Jèhófà máa pèsè “gbogbo nǹkan mìíràn” tó pọn dandan fún wọn. (Mát. 6:33) Ká lè rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Arábìnrin Saphira yẹ̀ wò. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún, kò sì tíì lọ́kọ. Ó wá láti ilẹ̀ Faransé láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Benin. Ní ọdún 2011, ó pa dà sí ilẹ̀ Faransé kó lè ṣiṣẹ́ tá a fi rí owó tó máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ fún ọdún mìíràn sí i, ìyẹn lẹ́yìn tó ti lo ọdún márùn-ún nílẹ̀ Áfíríkà. Saphira sọ pé: “Nígbà tó di ọjọ́ Friday, ìyẹn ọjọ́ tí màá lò kẹ́yìn níbi iṣẹ́ náà, mo rí i pé mo ṣì ní láti ṣe iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́wàá sí i kí n tó lè rí owó tó máa tó mi fún ọdún kan. Ọ̀sẹ̀ méjì péré ló sì kù fún mi láti lò nílẹ̀ Faransé. Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì fi ọ̀rọ̀ mi lọ̀ ọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ilé iṣẹ́ kan tó ń bá èèyàn wáṣẹ́ tẹ̀ mí láago, tí wọ́n sì béèrè bóyá mo lè wá gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kan fún ọ̀sẹ̀ méjì.” Lọ́jọ́ Monday, Saphira lọ sí ibi iṣẹ́ tí wọ́n pè é sí yẹn, kí ẹni tó fẹ́ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lè fi ọwọ́ iṣẹ́ náà hàn án. Ó wá sọ pé: “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi láti rí i pé arábìnrin lẹni tí mo fẹ́ lọ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà ló sì fẹ́ lọ tó fi gbàyè ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́nu iṣẹ́! Ọ̀gá rẹ̀ ti sọ pé òun ò ní fún un láyè àyàfi tó bá rí ẹni tó máa ṣiṣẹ́ rẹ̀ láwọn ọjọ́ táá fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Ńṣe lòun náà fọ̀rọ̀ ara rẹ̀ lọ Jèhófà bí èmi náà ti ṣe.”

OHUN TÓ Ń MÚ KÉÈYÀN NÍ OJÚLÓWÓ ÌTẸ́LỌ́RÙN

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tí wọ́n ti sìn ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí sọ Áfíríkà di ilé wọn. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ní wọ́n lò kí wọ́n tó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Títí dòní, àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan sìn níbi tí wọ́n tí nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ṣì ń jàǹfààní látinú àwọn ìrírí tí wọ́n ní láwọn ọdún tí wọ́n fi sìn nílẹ̀ òkèèrè. Wọ́n ti rí i pé àfi téèyàn bá ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà nìkan lèèyàn lè ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn.

^ ìpínrọ̀ 6 Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Benin ló ń bójú tó àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé yìí.