Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 3 2018 | Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?

Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?

Bá a ṣe ń rí i tí àjálù ń ṣẹlẹ̀, tí ìyà sì ń jẹ àwọn èèyàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ni Ọlọ́run rí tiwa rò. Bíbélì sọ pé:

“Nítorí tí ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣùgbọ́n ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe àwọn ohun búburú.”​—1 Pétérù 3:12.

Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àti ohun tó ń ṣe láti fòpin sí gbogbo ìyà.

 

“Kí Ni Ọlọ́run Ń Wò?”

Ṣé nǹkan burúkú ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí tó mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ni Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ?

Ṣé Ọlọ́run Ń Kíyè Sí Ẹ?

Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa?

Ṣé Ọlọ́run Mọ Bí Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí Lára Wa?

Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa, ọ̀rọ̀ wa yé e, ó sì máa ń dùn ún tá a bá ní ìṣòro.

Tẹ́nì Kan Bá Ń Jìyà, Ṣé Ọlọ́run Ló Fà Á?

Ṣé Ọlọ́run máa ń fi àìsàn tàbí àjálù jẹ àwọn èèyàn níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn?

Ta Ló Fà Á?

Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta tó ń mú kí ìyà máa jẹ aráyé.

Ọlọ́run Máa Tó Mú Gbogbo Ìyà Kúrò

Báwo la ṣe lè mọ̀ pé Ọlọ́run ò ní pẹ́ fòpin sí ìyà àti ìrẹ́jẹ?

Wàá Jàǹfààní Tó O Bá Mọ̀ Pé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ

Ìwé Mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára.

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?

Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ rẹ yé Ọlọ́run.