Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run Olódùmarè?

Àwọn kan lè dáhùn pé:

▪ “Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè.”

▪ “Ọlọ́run ló gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, tó sì wá sáyé lórúkọ Jésù.”

Kí ni Jésù sọ?

▪ Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó yọ̀ pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí pé Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Jésù sọ pé Baba òun ju òun lọ.

▪ Jésù sọ pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” (Jòhánù 20:17) Jésù ò sọ pé Ọlọ́run lòun, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹni ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run.

▪ Jésù sọ pé: “Èmi kò sọ̀rọ̀ láti inú agbára ìsúnniṣe ti ara mi, ṣùgbọ́n Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòhánù 12:49) Jésù ò fi àwọn ẹ̀kọ́ ara rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn, ẹ̀kọ́ Baba rẹ̀ ló fi kọ́ wọn.

JÉSÙ sọ pé Ọmọ Ọlọ́run lòun, òun kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, ta ló wá ń gbàdúrà sí nígbà tó wà láyé? (Mátíù 14:23; 26:26-29) Kò ní bọ́gbọ́n mu tá a bá lọ rò pé ńṣe ni Jésù kàn ń díbọ́n pé òun ń bẹ́nì kan sọ̀rọ̀.

Nígbà tí méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá bá a pé kó fàwọn sí ipò tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀, ó dá wọn lóhùn pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọwọ́ Baba mi.” (Mátíù 20:23) Ṣérọ́ ni Jésù pa fún wọn nígbà tó sọ fún wọn pé òun ò lágbára láti ṣe ohun tí wọ́n béèrè? Kò kúkú parọ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló fi gbà pé Ọlọ́run nìkan ló láṣẹ láti ṣerú yíyàn yẹn. Kódà, Jésù tiẹ̀ ṣàlàyé pé àwọn nǹkan kan wà tóun àtàwọn áńgẹ́lì ò mọ̀ àyàfi Baba òun nìkan.—Máàkù 13:32.

Ṣé ìgbà tí Jésù wà láyé nìkan ló kéré sí Ọlọ́run ni? Rárá o. Kódà lẹ́yìn tí Jésù kú tí Ọlọ́run sì jí i dìde, Bíbélì ṣì jẹ́ ká mọ̀ pé ó kéré sí Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wá létí pé “orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Bíbélì sọ pé lọ́jọ́ iwájú “nígbà tí ohun gbogbo bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnra rẹ̀ yóò wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọ́run tí ó fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ olórí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.”—1 Kọ́ríńtì 15:28, Ìròhìn Ayọ̀.

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Ìdí nìyẹn tó fi pe Bàbá rẹ̀ ní “Ọlọ́run mi.”—Ìṣípayá 3:2, 12; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí, wo ojú ìwé 201 sí 204 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Jésù sọ pé àwọn nǹkan kan wà tóun àtàwọn áńgẹ́lì ò mọ̀ àyàfi Bàbá òun nìkan