Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Títí Ikú Yóò Fi Yà Wá”

“Títí Ikú Yóò Fi Yà Wá”

“Títí Ikú Yóò Fi Yà Wá”

Ọ̀PỌ̀ tọkọtaya ló máa ń fi ìdùnnú sọ ọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn láìronú pé ó lè ṣẹlẹ̀. Ọjọ́ ogbó, àìsàn tàbí jàǹbá wọ́pọ̀, wọ́n sì lè fòpin sí ìgbésí ayé ẹni téèyàn fẹ́ràn, tí ẹnì kejì rẹ̀ yóò dá wà, tí ìbànújẹ́ á sì dorí rẹ̀ kodò.—Oníwàásù 9:11; Róòmù 5:12.

Ìṣirò fi hàn pé ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin [65] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló jẹ́ opó. Ìdí ni pé àwọn obìnrin tí ọkọ wọn kú máa ń fi ìlọ́po mẹ́ta ju àwọn ọkùnrin tí aya wọn kú lọ, torí náà àwọn èèyàn kà á sí pé ikú ẹnì kejì ẹni jẹ́ ìṣòro tó ń bá àwọn obìnrin fínra. Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn ọkùnrin náà kò ní ìṣòro yìí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni irú rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí. Ṣé o wà lára wọn?

Bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin ni ẹ́, kí lo lè ṣe tó o bá nírú ìṣòro yìí? Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro yìí? Báwo làwọn obìnrin kan tí ọkọ wọn kú àtàwọn ọkùnrin kan tí aya wọn kú ṣe fara dà á? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ojútùú kan gbòógì sí gbogbo ọ̀ràn tó bá ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ àwọn ìlànà àtàwọn àbá kan wà tó lè ṣèrànwọ́.

Gbà Pé Ó Ti Ṣẹlẹ̀ Kó O sì Fara Dà Á

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò àwọn kan ni pé ẹkún sísun jẹ́ ìwà ojo tàbí pé ó léwu, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joyce Brothers tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú àti ìhùwàsí ẹ̀dá, tóun náà jẹ́ opó fi ẹkún sísun wé ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ fún ìlera ara. Ká sòótọ́, ẹkún sísun jẹ́ ohun tó yẹ lákòókò ìbànújẹ́ náà, ó sì máa ń dín ìrora kù. Kò sídìí láti tijú torí pé ò ń sunkún. Àpẹẹrẹ rere kan nípa èyí wà nínú Bíbélì. Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó tayọ, Bíbélì sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, nígbà tí Sárà ìyàwó rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ kú, ó “pohùn réré ẹkún [ó sì] sunkún lórí rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 23:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, má ṣe ya ara rẹ sọ́tọ̀. Òwe 18:1 kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹniti o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀.” (Bibeli Mimọ) Kàkà bẹ́ẹ̀, wá ìrànwọ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn. Nírú ipò yìí, ìrànlọ́wọ́ ńlá ni ìjọ Ọlọ́run jẹ́, ìyẹn ibi táwọn ọkùnrin tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ nínú wọn ti lè ṣèrànwọ́, tí wọ́n sì ti lè fún èèyàn ní ìmọ̀ràn lákòókò tó yẹ.—Aísáyà 32:1, 2.

Àwọn kan rí i pé ó ṣèrànwọ́ fún àwọn láti gba lẹ́tà àti káàdì ìbánikẹ́dùn. O lè lo irú àkókò yìí láti kọ àwọn ohun rere tó o rántí nípa ẹnì kejì rẹ sílẹ̀ àtàwọn àkókò aláyọ̀ tẹ́ ẹ ti jọ gbádùn. Tó o bá fi àwọn fọ́tò, àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé pélébé ṣe ìwé ìrántí nípa olóògbé náà, èyí yóò jẹ́ kí ara rẹ kọ́fẹ pa dà.

Kì í ṣe ohun tó burú tí nǹkan bá tojú sú ẹni téèyàn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ ló máa jẹ́ fún ẹ tí o kò bá jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe déédéé. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ní àkókò tó o máa ń sùn, tó ò ń jí, tó ò ń jẹun tàbí àkókò tó o máa ń lò fún àwọn nǹkan míì, rí i pé o kò jáwọ́ ṣíṣe wọn. Pinnu ohun tó o máa ṣe láwọn òpin ọ̀sẹ̀ kan àtohun tó o máa ṣe lọ́jọ́ pàtàkì bí àyájọ́ ọjọ́ tẹ́ ẹ ṣègbéyàwó, ìyẹn láwọn àkókò tí ìbànújẹ́ lè fẹ́ dorí rẹ kodò. Ó ṣe pàtàkì pé kó o má ṣe jáwọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tó o máa ń ṣe déédéé.—1 Kọ́ríńtì 15:58.

Téèyàn bá wà nínú ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà, ó lè mú kéèyàn ṣe ìpinnu tí kò dára. Àwọn elétekéte lè lo àǹfààní yìí láti tú ọ jẹ. Nítorí náà, má ṣe kánjú ṣe ìpinnu bíi títa ilé rẹ, dídá okòwò ńlá, kíkó kúrò nílé, tàbí títún ìgbéyàwó ṣe. Òwe ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Ó yẹ kó o sún ìpinnu pàtàkì èyíkéyìí síwájú títí dìgbà tí ara rẹ á fi túbọ̀ balẹ̀.

Bó o ṣe máa ṣe àwọn ẹrù ẹnì kejì rẹ lè fa ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an, àgàgà tẹ́ ẹ bá ti jọ lo ọ̀pọ̀ ọdún pa pọ̀, àmọ́, ó wà lára ohun tó yẹ kó o ṣe. Ńṣe lò ń sún ìbànújẹ́ síwájú láìyẹ tí o kò bá tètè ṣe nǹkan sí i. (Sáàmù 6:6) Àwọn kan máa ń fẹ́ láti dá bójú tó ọ̀ràn yìí, àwọn míì sì rí i pé ó ṣàǹfààní káwọn ọ̀rẹ́ wà lọ́dọ̀ àwọn káwọn lè rẹ́ni bá sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan tí wọ́n ń ṣe yìí bá mú kí wọ́n rántí nǹkan kan nípa olóògbé náà. O sì tún lè fẹ́ kí ọ̀rẹ́ tàbí èèyàn rẹ kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ orí ìwé, irú bíi gbígba ìwé ẹ̀rí pé ẹnì kejì rẹ ti kú; sísọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn báńkì tẹ́ ẹ̀ ń lò àtàwọn ilé iṣẹ́ ìrajà àwìn; yíyí orúkọ àwọn nǹkan ìní yín pa dà; gbígba àwọn nǹkan tí wọ́n ń fún ẹni téèyàn rẹ̀ kú; àti sísanwó ìtọ́jú ara ẹni.

Má gbà gbé pé inú ayé oníwà pálapàla là ń gbé. Ní báyìí tó o sì ti dá wà, á dáa kó o túbọ̀ wà lójúfò kó o máa bàa ṣubú sínú ìwà àìmọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àkókò wa yìí mu gan-an ni, ó ní: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní.” (1 Tẹsalóníkà 4:4, 5) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o yàgò fún wíwo àwọn fíìmù, kíkàwé àti gbígbọ́ àwọn orin tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mọ̀ pé ó máa gba àkókò kó o tó pa dà bọ̀ sípò pátápátá. Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ ohun tó ń lọ láwùjọ tó wà ní Yunifásítì Michigan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, ó kéré tán ó máa gba ẹni tí ẹnì kejì rẹ̀ kú ní oṣù méjìdínlógún [18] kó tó lè ní ìlera tó pé, kí èrò rẹ̀ sì tó lè já geere. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kó o lè fara dà á, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní. (Gálátíà 5:22, 23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè má ronú kàn án báyìí, àmọ́ nǹkan yóò máa dára sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.

Báwọn Kan Ṣe Fara Dà Á

Ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ fún Anna tó ti wà nílé ọkọ fún ogójì [40] ọdún sẹ́yìn, nígbà tó pàdánù ọkọ rẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ó ní, “Màmá mi kú nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, lẹ́yìn náà, bàbá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì àti àbúrò mi obìnrin tún kú. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àdánù yìí tó dùn mí gan-an tó ikú ọkọ mi. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n gé mi sí méjì. Ìrora náà pọ̀ jù.” Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da ìrora yìí? Ó ní, “Mo ti ṣe ìwé gbàǹgbà kan tó kún fún ọ̀rọ̀ ìmọrírì táwọn èèyàn fi ránṣẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn káàdì táwọn èèyàn fi kọ ọ̀rọ̀ ìmọrírì tó yani lẹ́nu nípa àwọn ànímọ́ rere tí ọkọ mi ní. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló sọ ohun pàtó kan nípa rẹ̀. Ó dá mi lójú pé Jèhófà náà rántí rẹ̀, ó sì máa jí i dìde nígbà àjíǹde.”

Esther tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] sọ ohun tó ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] lèmi àti ọkọ mi fi jọ wà, àmọ́ lẹ́yìn náà, ìṣòro tó tíì nira jù lọ tí mo ní ni ìdánìkanwà. Àmọ́ mo ti kíyè sí i pé jíjẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú ìjọsìn Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mi ò jáwọ́ lílọ sáwọn ìpàdé, wíwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn àti kíka Bíbélì. Bí mi ò ṣe ya ara mi sọ́tọ̀ tún ti ràn mí lọ́wọ́. Mo máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi tó máa ń fetí sí mi kẹ́gbẹ́. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n lè sọ̀rọ̀ tó máa tù mí nínú, àmọ́ mo mọrírì bí wọ́n ṣe máa ń lo àkókò wọn pẹ̀lú mi, tí wọ́n sì máa ń fetí sí mi.”

Robert, tí àrùn jẹjẹrẹ pa ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjìdínláàádọ́ta [48] tí wọ́n ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti fara da ikú ẹnì kejì ẹni téèyàn lè bá sọ̀rọ̀, téèyàn jọ máa ń ṣèpinnu, rìnrìn àjò, gbádùn àkókò ìsinmi, téèyàn sì lè bá sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Kò rọrùn rárá, àmọ́ mo pinnu pé mi ò ní juwọ́ sílẹ̀, ńṣe ni màá máa bá ìgbésí ayé mi nìṣó. Bí mo ṣe máa ń ṣiṣẹ́ kára, tí mo sì máa ń lo ọpọlọ mi ràn mí lọ́wọ́. Àdúrà tún ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”

Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀ Lẹ́yìn Àdánù Náà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó wà lára ohun ìbànújẹ́ tó tíì lágbára jù lọ tó lè ṣẹlẹ̀ séèyàn, síbẹ̀ má ṣe ronú pé ọ̀rọ̀ rẹ kò lè lójú mọ́. Tó o bá ronú pé nǹkan tún lè sunwọ̀n sí i, o lè rí àǹfààní láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tí àyè tó o ní fún un tẹ́lẹ̀ kò tó nǹkan, irú bí eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ tàbí rírin ìrìn-àjò. Lílọ́wọ́ nínú irú àwọn ìgbòkègbodò yìí lè gbà ẹ́ lọ́wọ́ ìbànújẹ́. Fún àwọn kan, wọ́n lè túbọ̀ wá láǹfààní láti lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó dájú pé wàá rí ayọ̀ àti ìdùnnú tó máa ń wá látinú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Má ṣe ronú pé, o ò lè láyọ̀ mọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà Ọlọ́run máa bójú tó ẹ tó o bá wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Onísáàmù náà Dáfídì sọ pé, Jèhófà máa ń ‘tu àwọn opó lára.’ (Orin Dafidi 146:9 Bibeli Mimọ) Ó múnú ẹni dùn láti mọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ó tún sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (2 Kọ́ríńtì 1:3; Sáàmù 145:16) Ká sòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run ìfẹ́, múra tán, ó sì lè ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń wojú rẹ̀ tọkàntọkàn. Ǹjẹ́ kí èrò tìẹ náà rí bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tó kọrin pé: “Èmi yóò gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè ńlá. Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 121:1, 2.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Ọ̀kẹ́ àìmọye ni ọkọ tàbí aya wọn ti kú, tí wọ́n sì dá wà. Ṣé o wà lára wọn?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Títún Ìgbéyàwó Ṣe Ńkọ́?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ikú ló ń fòpin sí ìdè ìgbéyàwó, èyí sì fún ẹnì kejì láǹfààní láti fẹ́ ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Síbẹ̀, ẹnì kan fúnra rẹ̀ ló máa ṣèpinnu yìí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ mọ̀ nípa ìpinnu tí bàbá tàbí màmá wọ́n ṣe, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Fílípì 2:4) Bí àpẹẹrẹ, Andrés, kò kọ́kọ́ fara mọ́ bí bàbá rẹ̀ ṣe fẹ́ ẹlòmíì. Ó fẹ́ràn màmá rẹ̀ gan-an, èrò rẹ̀ sì ni pé, kò sẹ́ni tó yẹ kó gba ipò rẹ̀. Ó sọ pé, “Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé ìpinnu tó tọ́ ni bàbá mi ṣe. Bó ṣe fẹ́ ẹ̀lòmíì yìí mú kó láyọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó ti pa tì láti àkókò díẹ̀ sẹ́yìn, irú bíi rírin ìrìn-àjò. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó tí bàbá mi ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fún bó ṣe bójú tó ìlera rẹ̀, tó sì ràn án lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Tó o bá ń jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí tó o sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ lókun láti fara dà á, wàá lè tètè pa dà bọ̀ sí pò