Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọjọ́ Yín Lọjọ́ Òní”

“Ọjọ́ Yín Lọjọ́ Òní”

AYẸYẸ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́YEGE KÍLÁÀSÌ KỌKÀNDÍNLÁÀÁDÓJE NÍLÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

“Ọjọ́ Yín Lọjọ́ Òní”

NÍ September 11, ọdún 2010, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] èèyàn tó péjọ síbí ayẹyẹ pàtàkì ti ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkàndínláàádóje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé: “Ọjọ́ yín lọjọ́ òní, a wá bá yìn yọ̀ ni!”

“Etí Ìgbọ́”

Nígbà tí Arákùnrin Herd bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ó sọ ìdí tó fi yẹ kí gbogbo Kristẹni máa lo “etí ìgbọ́” wọn lọ́nà rere nípa fífiyè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Òwe 20:12) Ó sọ fún kíláàsì náà pé: “Ẹ ti ń fetí sí Jèhófà láti oṣù bíi mélòó kan bọ̀, ẹ ó sì máa ṣé bẹ́ẹ̀ títí ayérayé.”

Báwo làwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí ṣe máa lo etí wọn lọ́nà rere? Arákùnrin Herd sọ pé, “Nípa fífetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.” Ó fi kún un pé: “A óò sọ ohun púpọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tòní tó máa múra yín sílẹ̀ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín lọ́jọ́ iwájú.”

“Fi Gbogbo Ọkàn-Àyà Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”

Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó wà lókè yìí. Ó sọ nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà nígbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé.

Arákùnrin Lösch wá sọ pé, bẹ́ẹ̀ náà ni “ó yẹ kí àwọn míṣọ́nnárì fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ wọn.” Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé, “o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé màá lè kọ́ èdè tuntun báyìí? Ṣé màá lè kọ́ àṣà ìbílẹ̀ míì? Ǹjẹ́ màá lè dúró síbi tí wọ́n yàn mí sí tí àárò ilé bá ń sọ mí?’” Kí ni ìdáhùn náà? Arákùnrin Lösch rọ kíláàsì náà pé kí wọ́n “gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”

Arákùnrin Lösch tún ka Òwe 14:26, tó sọ pé: “Inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà.” Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà yóò máa pọ̀ sí i tá a bá ń ronú lórí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tó ti gbà bù kún wa.

Bíbélì sọ pé ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà “yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀ tààrà lọ sẹ́bàá ipadò; òun kì yóò sì rí i nígbà tí ooru bá dé, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé yóò di èyí tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ti gidi.”—Jeremáyà 17:7, 8.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ níbẹ̀ yẹn yé wa kedere. Arákùnrin Lösch sọ pé, “Bó ti wù kí ohun tó wà níwájú rẹ le tó, Jèhófà ni kí o gbẹ́kẹ̀ lé.”

“Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Áńgẹ́lì Olóòótọ́”

Èyí ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ. Àwọn áńgẹ́lì jẹ́ àpẹẹrẹ àgbàyanu fún wa. Ó sọ pé, “Gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn ló yẹ ká tẹ̀ lé.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ ohun mẹ́rin nípa ìwà àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ náà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé, àwọn ìwà náà ni: ìfaradà, ìrẹ̀lẹ̀, ríranni lọ́wọ́ àti ìṣòtítọ́.

Bíbélì sọ fún wa pé, áńgẹ́lì kan fi ọjọ́ mọ́kànlélógún gbéjà ko ‘ọmọ aládé Páṣíà,’ tó jẹ́ ẹ̀mí èṣù alágbára. (Dáníẹ́lì 10:13) Áńgẹ́lì yẹn lo ìfaradà. Arákùnrin Lett jẹ́ kó ṣe kedere pé, àwa Kristẹni náà “ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí.” (Éfésù 6:12) Ó sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Ẹ jà fitafita kí ẹ bàa lè máa ṣe iṣẹ́ yín nìṣó.”

Nígbà tí Mánóà, bàbá Sámúsìnì béèrè orúkọ áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà kọ̀ láti sọ orúkọ rẹ̀ fún un. Ìrẹ̀lẹ̀ ni áńgẹ́lì náà fi hàn. (Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18) Arákùnrin Lett sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Tí ẹnì kan bá ti fẹ́ yìn ẹ́ kọjá bó ti yẹ tàbí tó bá ti fẹ́ sọ àsọrégèé nípa ohun tó o lè ṣe, fi ìrẹ̀lẹ̀ darí ìyìn náà kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 4:7.

Nígbà tí Jésù wà nínú ọgbà Gẹtisémánì kété ṣáájú ikú rẹ̀, “áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:43) Áńgẹ́lì yẹn ṣèrànwọ́ fún un. Arákùnrin Lett sọ pé, “Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kó o mọ ohun táwọn èèyàn nílò níbi tó o ti ń ṣe míṣọ́nnárì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kó o bójú tó ohun tí wọ́n nílò.”

Bó ti jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì díẹ̀ ló dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ó dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ gidi nínú ìṣòtítọ́.Ìṣípayá 12:4.

Arákùnrin Lett rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Ẹ dènà Èṣù bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yẹn ti ṣe.” Ó tún sọ pé, “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá.”—Jákọ́bù 4:7.

Àwọn Kókò Mẹ́ta Míì Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà

“Fi Jèhófà Ṣe Àpáta Ọkàn Rẹ.” Nígbà tí Arákùnrin Gary Breaux tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń sọ̀rọ̀ nípa àkòrí tó fa kíki tó wà lókè yìí, tó gbé ka Sáàmù 73:26, ó ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọyì gbígbára lé Jèhófà. Báwo ni Jèhófà ṣe dà bí àpáta? Arákùnrin Breaux sọ pé, “A lè gbé òkúta kan tẹ bébà kan mọ́lẹ̀ kí atẹ́gùn má bàa gbé e lọ. Lọ́nà kan náà, Jèhófà lè dáàbò bo ọkàn tìrẹ náà.” Àmọ́ ṣá o, ọkàn wa lè ṣì wá lọ́nà tá a bá dojú kọ àwọn ohun tó ń dán ìfaradà ẹni wò. (Jeremáyà 17:9) Àwọn nǹkan bí, ojú ọjọ́ àti oúnjẹ tó yàtọ̀ sí èyí tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ àti ìwà àwọn míṣọ́nnárì tẹ́ ẹ jọ ń gbélé lè mú kó o fẹ́ fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Arákùnrin Breaux sọ pé: “O máa dojú kọ ipò tó máa mú kó o gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò kó o sì ṣe àwọn ìpinnu. Ṣé wàá yan ohun tí inú Jèhófà máa dùn sí? Tó ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò di ‘àpáta ọkàn rẹ.’ Yóò máa darí ìṣísẹ̀ rẹ.”

“Ṣé O Ní Ìgbàgbọ́ Tí Ó Tó Láti Ki Ẹsẹ̀ Rẹ Bọ Omi?” Arákùnrin Sam Roberson tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí, ìwé Jóṣúà orí 3 ló gbé ọ̀rọ̀ náà kà. Báwo ni ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa gba Odò Jọ́dánì kọjá nígbà tó kún àkúnya? Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé kó pàṣẹ fún àwọn àlùfáà láti “dúró jẹ́ẹ́ ní Jọ́dánì.” Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ní kété tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà . . . bá ti kanlẹ̀ nínú omi Jọ́dánì, omi Jọ́dánì ni a óò ké kúrò, . . . yóò sì dúró jẹ́ẹ́ bí ìsédò.” (Jóṣúà 3:8, 13) Arákùnrin Roberson sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Àwọn ìṣòro kan máa wà nígbèésí ayé rẹ tó máa dà bí ‘omi Jọ́dánì’ èyí tí kò ní jẹ́ kó o dé ibi tó o ti máa rí ìbùkún rẹ gbà tó o bá fàyè gbà á.” Bí àpẹẹrẹ, èdèkòyédè lè wà láàárín ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ míṣọ́nnárì. Kí ló máa yanjú ìṣòro náà? “Iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ni kó o gbájú mọ, kì í ṣe àṣìṣe àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́.” Arákùnrin Roberson gba kíláàsì náà níyànjú pé: “Tó o bá ní ìgbàgbọ́ láti ki ẹsẹ̀ rẹ bọ omi, Jèhófà yóò mú kó o la àwọn ìṣòro tó dà bí ‘omi Jọ́dánì’ nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ kọjá.”

“Fìdí Àwọn Ìwéwèé Rẹ Múlẹ̀ Gbọn-in Gbọn-in.” Èyí ni kókó ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin William Samuelson tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ. Ó gbé ọ̀rọ̀ náà ka Òwe 16:3, tó sọ pé: “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” Arákùnrin Samuelson bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Ṣé ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé kó o kàn ‘yí àwọn iṣẹ́ rẹ’ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà láìṣe nǹkan míì mọ́?” Rárá o, nítorí Òwe 16:1 sọ pé: “Àwọn ìṣètò ọkàn-àyà jẹ́ ti ará ayé.” Arákùnrin Samuelson sọ pé: “Jèhófà kò ní fi iṣẹ́ ìyanu múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ fúnra rẹ lo máa rí i dájú pé ò ń ṣe ohun tó tọ́. Tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tí ò ń gbàdúrà tí o sì ń bá ẹ̀ka ọ́fíìsì ibi tó wà sọ̀rọ̀, ọkàn rẹ á mú kó o lè máa ṣe ohun tó tọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọin-gbọin.”

Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Gẹ́gẹ́ bí ara ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì máa ń jáde lọ wàásù pẹ̀lú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí wọn. Arákùnrin Mark Noumair tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lọ wàásù. Àwọn ìrírí náà ní pàtàkì sì ṣàgbéyọ ipa tí àdúrà ń kó nínú wíwá àwọn olóòótọ́ ọkàn rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù.

Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lọ sílé oúnjẹ ìpápánu kan. Òṣìṣẹ́ kan nílé oúnjẹ náà kíyè sí i pé tọkọtaya náà ń gbàdúrà kí wọ́n tó jẹun. Ó sún mọ́ wọn, ó sì bi wọ́n bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Nígbà tó mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni wọ́n, ó ṣàlàyé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí òun, àmọ́ òun ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́. Ó tiẹ̀ ti hùwà ọ̀daràn tí wọ́n sì ti rán an lọ sẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní báyìí, ọ̀dọ́kùnrin yìí fẹ́ kí Jèhófà dá sí ọ̀ràn ìgbésí ayé òun. Ó tún sọ pé, kí tọkọtaya náà tó wọlé oúnjẹ náà ni òun ti ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́ láti tún ìgbésí ayé òun ṣe. Àdúrà rẹ̀ sì gbà!

Arákùnrin Rudi Hartl tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka tó ń bójú tó Lẹ́tà Táwọn Èèyàn Kọ sí Ọ́fíìsì Wa, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Tọ́ Ọ Wò, Kí Ẹ Sì Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Ẹni Rere.” Ó fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Arákùnrin Wayne Wridgway láti orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì, Arákùnrin Jason Reed láti orílẹ̀-èdè Chile, àti Arákùnrin Kenji Chichii láti orílẹ̀-èdè Nepal. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn arákùnrin yìí sọ̀rọ̀ látọkànwá nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì, nígbà tí wọ́n ń kọ́ èdè tuntun, nígbà tí wọ́n ń kọ́ àwọn àṣà ìbílẹ̀ míì àti nígbà tí àárò ilé ń sọ wọ́n. Arákùnrin Chichii sọ pé: “Ohun kan tó ràn wá lọ́wọ́ ni pé, a tètè ní àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ wa tuntun. Bí a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ là ń rí i pé, ó túbọ̀ ń rọrùn fún wa láti kápá àárò ilé tó ń sọ wá.”

Kété lẹ́yìn tí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, ọ̀kan lára wọn ṣojú fún kíláàsì náà láti ka lẹ́tà ìdúpẹ́ kan tó wọni lọ́kàn ṣinṣin. Ní apá kan nínú lẹ́tà náà, wọ́n sọ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí pé: “Àwa kíláàsì yìí ti fúnra wa rí bí ẹ ṣe fìfẹ́ lo ara yín fún wa láìṣàárẹ̀, tí ẹ ṣètò àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́, tí ẹ ṣèbẹ̀wò sí kíláàsì wa, tí ẹ sì fún wa ní ìtọ́ni tẹ̀mí tó jíire. Nítorí pé ẹ ti tọ́jú wa tìfẹ́tìfẹ́, a ó ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́, sùúrù, ìrẹ̀lẹ̀, àti ọkàn rere tí ẹ ní sí wa, nígbà tí a bá dé ibi tá a ti fẹ́ ṣiṣẹ́.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]

“Tí ẹnì kan bá ti fẹ́ yìn ẹ́ kọjá bó ti yẹ . . . , darí ìyìn náà kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

“Àwọn ìṣòro tó dà bí ‘omi Jọ́dánì’ yóò wà nínú ìgbésí ayé rẹ”

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

9 iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá

56 iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́

28 iye àwọn tọkọtaya

33.0 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn

17.9 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi

13.3 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ sí orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wà nísàlẹ̀ yìí

IBI TÁ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ

BÒLÍFÍÀ

BOTSWANA

BULGARIA

KÓŃGÒ (KINSHASA)

CÔTE D’IVOIRE

GÁŃBÍÀ

JÁMÁNÌ

ÍŃDÍÀ

INDONESIA

KẸ́ŃYÀ

LÀÌBÉRÍÀ

MAKEDÓNÍÀ

MADAGÁSÍKÀ

MALAYSIA

MÒSÁŃBÍÌKÌ

PANAMA

PERU

POLAND

ROMANIA

SERBIA

SIERRA LEONE

SWAZILAND

TANZANIA

UGANDA

SÌǸBÁBÚWÈ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Kọkàndínláàádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tó wà nísàlẹ̀ yìí, ńṣe la to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Munaretto, R.; Olofsson, Y.; Budden, K.; Najdzion, L.; Moya, G.; Treviño, G.; Dion, A.; Fleegle, A.

(2) Smith, J.; Michael Raj, J.; Smith, S.; Paramo, A.; McDonald, J.; Deans, M.; Joyal, S.; Watson, L.

(3) Joyal, C.; Crawley, T.; Hacker, D.; Shynkarenko, J.; Knapp, T.; Ayling, J.; Highley, C.; Olofsson, B.

(4) Fitzpatrick, M.; Najdzion, B.; Skallerud, L.; Harris, A.; Harris, S.; Budden, R.; Paramo, Y.; Skallerud, K.

(5) Crawley, B.; Michael Raj, J.; Lodge, A.; Lodge, R.; Herms, N.; Fitzpatrick, J.; Moya, R.; Munaretto, P.

(6) Watson, S.; Deans, M.; Hacker, J.; McDonald, J.; Treviño, J.; Harris, S.; Herms, C.; Harris, P.

(7) Shynkarenko, V.; Highley, T.; Smith, A.; Dion, J.; Ayling, R.; Smith, B.; Knapp, T.; Fleegle, B.