Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Kan Láti Ilẹ̀ Gíríìsì

A Lọ Wàásù Ní Ìpẹ̀kun Ilẹ̀ Yúróòpù Níhà Gúúsù

A Lọ Wàásù Ní Ìpẹ̀kun Ilẹ̀ Yúróòpù Níhà Gúúsù

ÀWA mẹ́tàlá kan gbéra ìrìn àjò ní erékùṣù Kírétè láti lọ wàásù ní erékùṣù Gáfúdò tí kò ju bíńtín lọ nínú àwòrán ilẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé ibẹ̀ ni ìpẹ̀kun ilẹ̀ Yúróòpù níhà gúúsù. Erékùṣù kékeré yìí jẹ́ òkè olórí títẹ́jú kan tó yọ sókè láàárín Òkun Mẹditaréníà. Bí ọkọ̀ ojú omi wa ṣe ń rìn jìnnà sí àwọn òkè ńláńlá tó ń jẹ́ Levká Mountains ní erékùṣù Kírétè, ló ṣe ń dà bíi pé àwọn òkè náà ń kéré sí i títí a kò fi rí wọn mọ́.

Ó kọ́kọ́ dà bíi pé ìrìn àjò wa tí a ń rìn nígbà ẹ̀rùn yìí máa tura torí bí oòrùn ṣe mú gan-an lọ́jọ́ náà. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìjì líle fi bẹ̀rẹ̀ sí í jà lójú òkun, tó wá ń taari ọkọ̀ wa káàkiri lójú agbami. Èébì wá ń gbé mi, ìyẹn sì mú mi rántí ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìjì líle kan ṣe wáyé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń rìnrìn àjò lórí òkun yìí ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Káúdà ni wọ́n ń pe erékùṣù Gáfúdò nígbà yẹn. (Ìṣe 27:13-17) Mo wá ń fọkàn gbàdúrà pé ká lè gúnlẹ̀ sí Gáfúdò láyọ̀.

Nígbà tó yá, a rí ibi tí a ń lọ lọ́ọ̀ọ́kán. Erékùṣù náà jẹ́ àpáta ńlá tó yọ sókè láàárín agbami, tí etí rẹ̀ sì dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọnú òkun. Kò ga ju ọ̀ọ́dúnrún [300] mítà lọ, orí rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ́jú pẹrẹsẹ, torí kò sí ibì kan tó fi bẹ́ẹ̀ yọ sókè ju àwọn ibi yòókù. Àwọn igi ahóyaya ńlá àti kéékèèké ló gba èyí tó pọ̀ jù nínú ilẹ̀ erékùṣù yìí, gígùn ilẹ̀ ibẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ kò sì ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lọ. Àwọn igi júnípà etíkun wà ní àwọn ibì kan níbẹ̀ títí wọ etí òkun.

Ìgbà kan wà tí iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní erékùṣù náà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000]. Lónìí, iye àwọn tó ń gbé ibẹ̀ kò tó ogójì. Ìgbé ayé ọ̀làjú kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dé erékùṣù Gáfúdò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá tó ń kó ẹrù àti èyí tó ń gbé epo máa ń kọjá ní etíkun ibẹ̀, Kírétè nìkan ni ọkọ̀ ojú omi ti ń wá sí erékùṣù náà, kì í sì í wá síbẹ̀ déédéé pàápàá, torí lọ́pọ̀ ìgbà kì í lè tètè gbéra tàbí kó máà tiẹ̀ lè lọ mọ́ nítorí ojú ọjọ́ tí kò dáa.

Ṣe la wá sí Gáfúdò láti wá sọ ìròyìn ayọ̀ tí ó ń gbéni ró fún wọn, èyí tó dá lórí ìrètí tó dájú tó fi hàn pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa débi pé àwọn ènìyàn yóò máa wà láàyè títí láé nínú ìlera pípé. Bí ọkọ̀ wa ṣe ń sún mọ́ èbúté, ara wa ti wà lọ́nà láti sọ̀ kalẹ̀ kí a bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere yìí.

Nǹkan bíi wákàtí mẹ́rin ni a fi wà lójú agbami, tí ìjì ń bi ọkọ̀ wa síbí sọ́hùn-ún, nítorí náà nígbà tí a gúnlẹ̀, ó hàn lójú gbogbo wa pé ìrìn àjò wa dé Gáfúdò kò fi bẹ́ẹ̀ tura. Àmọ́ bí a ṣe rẹjú díẹ̀ tí a sì mu kọfí, ara tù wá ọkàn wa sì balẹ̀. Lẹ́yìn àyẹ̀wò ṣókí lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù, a gbàdúrà tọkàntọkàn, a sì lọ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù.

Àwọn èèyàn ibẹ̀ kóni mọ́ra, wọ́n sì ní aájò àlejò. Wọ́n á ní ká wọlé, wọ́n á sì fún wa ní ìpápánu. Àwa náà sì ṣe wọ́n lóore ní ti pé, yàtọ̀ sí wíwàásù ìhìn rere fún wọn látinú Bíbélì, a ṣe ìrànlọ́wọ́ míì fún wọn níbi tí wọ́n bá ti nílò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀kan lára wa tó mọ̀ nípa iṣẹ́ iná ń wàásù fún obìnrin kan ní ilé ìtajà rẹ̀, ó kíyè sí ohun èlò abánáṣiṣẹ́ rẹ̀ kan tó bà jẹ́, ó sì bá a tún un ṣe. Ìyẹn wú obìnrin náà lórí gan-an. Ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a fún un, ó sì yìn wá pé òun mọrírì iṣẹ́ ìwàásù tí a wá ṣe. Obìnrin míì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, ó ní: “Bí ẹ ṣe wá sí erékùṣù tó jìnnà réré yìí láti wá wàásù fi hàn pé Ọlọ́run ló rán yín ní iṣẹ́ yìí, kì í ṣe èèyàn.”

Ó jọ pé wọ́n mọyì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a mú wá fún wọn gan-an ni. Ọkùnrin kan gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, ó sì tún fẹ́ láti gba àwọn ìwé míì tó lè máa kà ní ìgbà òtútù tó sábà máa ń gùn tó oṣù mélòó kan. Ọkùnrin míì náà fẹ́ gba àwọn ìwé wa tí yóò máa kà, ó sì tún fẹ́ gba àwọn tó máa kó sí ibi tó ti ń tajà kí àwọn oníbàárà rẹ̀ lè máa kà wọ́n. Ó fún wa ní àdírẹ́sì rẹ̀, kí a lè máa fi àwọn ìwé ìròyìn ránṣẹ́ sí i lóṣooṣù. A tún pàdé ìdílé kan níbẹ̀, a sì fi ibi tí Bíbélì ti mẹ́nu kan erékùṣù kékeré tí wọ́n ń gbé yìí hàn wọ́n, ìyẹn sì jọ wọ́n lójú gan-an. Wọ́n wá fi ìdùnnú gba àwọn ìwé ìròyìn tí a fún wọn.

Inú wa dùn gan-an bí àwọn èèyàn ṣe tẹ́wọ́ gbà wá. Àmọ́ Gáfúdò tí a wá yìí mú kí àwọn kan lára wa rántí ohun kan tó dùn wọ́n gan-an. Ilé kan wà nítòsí ibì kan tó ń jẹ́ Sarakíniko Bay, ilé yìí ni ìjọba máa ń kó àwọn tí wọ́n bá rán lọ sí ìgbèkùn sí láyé àtijọ́. Ibẹ̀ ni wọ́n fi Emmanuel Lionoudakis tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà kan láàárín ọdún 1936 sí 1939, nígbà tí wọ́n rán an lọ sí ìgbèkùn nítorí pé ó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. * Bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe Gáfúdò ìgbà yẹn ni pé ó jẹ́ “erékùṣù aṣálẹ̀ tí kò ní nǹkan míì ju àwọn àkekèé olóró, ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn . . . ti kú dà nù torí ebi, àìní àwọn nǹkan kòṣeémánìí àti àrùn, [ibi] tí wọ́n ń pè ní erékùṣù ikú, bí ibẹ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn.” Ẹja ni Lionoudakis máa ń pa láti fi ṣe oúnjẹ, síbẹ̀ ó ṣì ń wàásù lójú méjèèjì fún àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹ̀wọ̀n náà, torí pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Nígbà tí ọmọ rẹ̀ obìnrin, ọkọ ọmọ rẹ̀ àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ obìnrin rí ibi tí wọ́n gbé Lionoudakis wá ní nǹkan bí àádọ́rin ọdún sẹ́yìn, inú wọn bà jẹ́. Àmọ́ ní ti àwa yòókù, ṣe ni àpẹẹrẹ Lionoudakis mú ká túbọ̀ pinnu pé a máa jẹ́ adúróṣinṣin, àti pé a ó máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó.

Láyé àtijọ́, ojú àwọn tí wọ́n bá mú nígbèkùn wá sí Gáfúdò máa ń rí màbo. Ṣùgbọ́n fún àwa tó wá wàásù yí ká erékùṣù náà lópin ọ̀sẹ̀ yẹn, ibi tí ó tura láti wàásù ló jẹ́. Àwọn èèyàn ọlọ́yàyà tó wà níbẹ̀ gba ìwé ìròyìn mẹ́rìndínláàádọ́ta àti ìwé pẹlẹbẹ mẹ́sàn-án lọ́wọ́ wa. À ń fójú sọ́nà fún ìgbà tí a tún máa pa dà rí àwọn ọ̀rẹ́ wa tuntun yìí!

Ká tó mọ̀, àsìkò ti tó láti pa dà lọ sílé. Aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ló yẹ ká gbéra kúrò níbẹ̀, àmọ́ nítorí ojú ọjọ́ tí kò dáa, wọ́n sún un síwájú. Ní aago méjìlá òru, a wọ ọkọ̀ ojú omi, a bẹ̀rẹ̀ sí í gbára dì fún ìrìn àjò tí kò rọrùn tí a tún máa rìn. Níkẹyìn, a gbéra ní aago mẹ́ta òru, lẹ́yìn tí a sì ti wà lójú agbami fún nǹkan bíi wákàtí márùn-ún tí ìjì ń bi ọkọ̀ wa síbí sọ́hùn-ún, a dé erékùṣù Kírétè. Ó ti rẹ̀ wá gan-an débi pé nígbà tí a fi máa kúrò nínú ọkọ̀, ẹsẹ̀ wa ò kọ́kọ́ dúró dáadáa nílẹ̀ bí a ṣe ń rìn, síbẹ̀ inú wa dùn pé ó ṣeé ṣe fún wa láti sọ orúkọ Jèhófà dí mímọ̀ fún àwọn tó wà ní erékùṣù Gáfúdò. (Aísáyà 42:12) Gbogbo àwa tí a lọ ni a gbà pé lílọ tí a lọ síbẹ̀ yẹn tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lóòótọ́, a kò ní pẹ́ gbàgbé gbogbo ìnira tó bá wa, àmọ́ ó dájú pé títí láé la ó máa rántí ìrìn àjò yìí.

^ Ìtàn ìgbésí ayé Emmanuel Lionoudakis, wà nínú Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 25 sí 29.