Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ NǸKAN BURÚKÚ FI Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÈÈYÀN RERE?

Ohun Tí Ọlọ́run Máa Ṣe Láti Fòpin Sí Ìwà Búburú

Ohun Tí Ọlọ́run Máa Ṣe Láti Fòpin Sí Ìwà Búburú

Bíbélì sọ ohun tí Jèhófà àti Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ máa ṣe sí ìyà tí Sátánì Èṣù fi ń pọ́n aráyé lójú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Ìdí nìyí tí a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run [Jésù] hàn kedere, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.’ (1 Jòhánù 3:8) Gbogbo iṣẹ́ Èṣù bí ìwọra, ìkórìíra àtàwọn ìwà ibi míì tó kún inú ayé yìí ló máa dòfo. Jésù ṣèlérí pé Sátánì Èṣù tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé yìí” ni òun “máa lé jáde.” (Jòhánù 12:31) Ayé tuntun òdodo Ọlọ́run ló máa rọ́pò ìṣàkóso Sátánì, nígbà náà ilẹ̀ ayé á wá dùn ún gbé.—2 Pétérù 3:13.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá kọ̀ láti yí pa dà tí wọ́n sì ń ṣe nǹkan burúkú? Ohun tí Bíbélì ṣèlérí ni pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:21, 22) Gbogbo ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù ni kò ní sí mọ́. Nínú ìjọba Ọlọ́run, gbogbo àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn máa bọ́ lọ́wọ́ àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún.—Róòmù 6:17, 18; 8:21.

Nínú ayé tuntun yẹn, báwo ni Ọlọrun á ṣe mú aburú kúrò? Kì í ṣe pé Ọlọ́run máa gba òmìnira tá a ní tàbí kó ṣe wá bí rọ́bọ́ọ̀tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa kọ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ tirẹ̀ láti máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, èyí á sì mú kí wọ́n yàgò fún èròkerò tó lè sún wọn hùwà burúkú.

Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìjìyà kúrò

Kí ni Ọlọ́run máa ṣe sí àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀? Ọlọ́run ti ṣèlérí pé, láìpẹ́, Ìjọba òun máa ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. Jésù Kristi ni Ọlọ́run fi ṣe Ọba Ìjọba náà, ó sì ní agbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá. (Mátíù 14:14) Ó tún ní agbára láti kápá àwọn ohun tí Ọlọ́run dá bí afẹ́fẹ́, omi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Máàkù 4:35-41) Torí náà, gbogbo àdánù tí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń fà máa pòórá. (Oníwàásù 9:11) Tí Kristi bá ń ṣàkóso, onírúurú àjálù ló máa di ohun ìgbàgbé.—Òwe 1:33.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tó ti kú? Ṣáájú kí Jésù tó jí Lásárù dìde, ó sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Ó dájú pé Jésù lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde!

Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ láti gbé nínú ayé tí àjálù burúkú ti ní ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rere mọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, oò ṣe kúkú kẹ́kọ̀ sí i nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà nínú Bíbélì kí o lè mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àdúgbò rẹ yóò láyọ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Jọ̀wọ́ kàn sí wọn tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí.