Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ

Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun

Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun

Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.

Bí ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa, àárín wọ́n máa gún. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.” (Jeremáyà 29:12) Bó o ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, wàá “sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ [ẹ].” (Jákọ́bù 4:8) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Bí a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ máa túbọ̀ gún régé.

“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”Sáàmù 145:18

Ọlọ́run fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Jésù sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì, òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja, òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Mátíù 7:9-11) Torí náà, Ọlọ́run fẹ́ kó o gbàdúrà sí òun torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ,’ ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Pétérù 5:7) Kódà, ó fẹ́ kó o sọ gbogbo ìṣòro rẹ fún òun. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Ó máa ǹ wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run.

Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá kíyè sí i pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa ń fẹ́ gbàdúrà. Títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà. * Èyí fi hàn pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi máa wù wá láti sún mọ́ ọn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà sí i déédéé.

Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?

^ ìpínrọ̀ 8 Lọ́dún 2012, iléeṣẹ́ ìwádìí kan tó ń jẹ́ Pew Research Center ṣe ìwádìí kan nípa àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́wàá lára wọn máa ń gbàdúrà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù.