KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?
“Èrò mi ni pé ó máa ṣòro fún mi láti lóye Bíbélì.”
—Jovy
“Mo ronú pé kíka Bíbélì kì í gbádùn mọ́ni.”
—Queennie
“Nígbà tí mo bá rí bí Bíbélì ṣe tóbi tó, ńṣe ló máa ń sú mi.”
—Ezekiel
Ṣé o ti ronú nípa kíka Bíbélì, àmọ́ tí o kò kà á torí pé o ní irú èrò tí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ní? Kíka Bíbélì máa ń ka ọ̀pọ̀ èèyàn láyà. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè láyọ̀, kó o sì máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀? Tó o bá wá mọ̀ pé àwọn ọ̀nà kan wà tó o lè gbà kà á, tí wàá sì gbádùn ẹ̀ ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ láti gbìyànjú ẹ̀ wò, kó o sì rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì?
Àwọn kan ti ka Bíbélì, ó sì ti ṣe wọ́n láǹfààní. Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọn sọ.
Ezekiel, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo dà bí ẹni tó ń wa mọ́tò láìjẹ́ pé ó ní ibi kan lọ́kàn tó fẹ́ lọ. Ṣùgbọ́n kíka Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ ní ìtúmọ̀. Ó ní àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí mo lè máa lò lójoojúmọ́.”
Frieda, tí òun náà ti lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mo máa kanra lódìlódì. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, mo tí mọ bí mo ṣe lè kápá rẹ̀. Ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń sún mọ́ mi, mo sì ti láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i.”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Eunice tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún, sọ nípa Bíbélì pé, “Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìwà tó dáa.”
Bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì, kíka Bíbélì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé rẹ. (Aísáyà 48:
Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Àmọ́, kí làwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀, kó o sì gbádùn rẹ̀?