Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa ṣe ìdájọ́ òdodo?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.” (Sáàmù 140:12) Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà láyé.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run ń rí bí ìdájọ́ òdodo ò ṣe sí láyé mọ́, ó sì máa ṣe àtúnṣe sí i.Oníwàásù 5:8.

  • Tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ òdodo wá, àlàáfíà àti ààbò máa wà láyé.Aísáyà 32:16-18.

Ṣé Ọlọ́run ka àwọn èèyàn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ?

Èrò àwọn kan ni pé Ọlọ́run bù kún àwùjọ àwọn èèyàn pàtó kan, ó sì ti gégùn-ún fún àwọn kan. Àwọn míì sì gbà pé bákan náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bákàn náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • “Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ni “ìhìn rere” tàbí ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì wà fún.Ìṣípayá 14:6.