Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kyrgyzstan

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìyàsímímọ́ Ẹ̀ka Ọ́fí ìsì

Ìyàsímímọ́ Ẹ̀ka Ọ́fí ìsì

ÀWỌN ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé àti àwọn ará tó wà nílùú Bishkek, fi ọdún kan ààbọ̀ ṣiṣẹ́ takuntakun láti kọ́ àwọn ilé míì kún ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Bishkek, olú-ìlú Kyrgyzstan, wọ́n sì tún ṣe é kó lè bóde mu. Wọ́n ya ibẹ̀ sí mímọ́ ní October 24, 2015, ìyẹn oṣù kan péré lẹ́yìn tí iṣẹ́ náà parí. Inú àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] dùn láti wo ìyàsímímọ́ náà lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìdínlógún [18] àti àwọn ilé márùn-ún míì tí wọ́n kóra jọ sí. Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà, àsọyé náà sì wọni lọ́kàn. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Fi Ọkàn Tó Pé Sin Jèhófà.” Lọ́jọ́ kejì, wọ́n ṣe ìpàdé kan tó ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló sì wò ó.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Kyrgyzstan

Ní Saturday, May 14, 2016, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùndínlógójì [6,435] èèyàn ló pé jọ síbi ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Àméníà. Inú ilé gbígbé alájà méjìdínlógún [18] kan tó rẹwà ni ọ́fíìsì náà wà, àjà mẹ́fà ló sì gbà. Wọ́n tún ṣe ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti ibi tí wọ́n á ti máa ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn àsọyé tí wọ́n sọ níbẹ̀ dá lórí bí ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní Àméníà ṣe bẹ̀rẹ̀. Iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Àméníà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, lẹ́yìn ọdún 1900, ó sì bẹ̀rẹ̀ ní Àméníà gangan ní àárín ọdún 1970 àti 1980, nígbà tí orílẹ̀-èdè náà ṣì wà lábẹ́ ìjọba Soviet Union. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin, a sì gbé ẹ̀ka ọ́fíìsì kan kalẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbi ìyàsímímọ́ náà ni kò rò ó rí pé àwọn máa rí àwọn nǹkan ribiribi yìí tí ètò Ọlọ́run gbé ṣe lórílẹ̀-èdè náà. Apá pàtàkì lára ìyàsímímọ́ náà ni ìgbà tí gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀ fi gbogbo ọkàn gbà pẹ̀lú arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí pé kí wọ́n ya àwọn ilé tó rẹwà náà sí mímọ́ fún Jèhófà.

Armenia

Lókè: Ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì Àméníà

Láàárín: Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wá sí àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ lópin ọ̀sẹ̀

Nísàlẹ̀: Àwọn ará Àméníà ń jó ijó ìbílẹ̀