Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá òsì: Arábìnrin kan ní ìpínlẹ̀ Alabama ní Amẹ́ríkà, ń fi àwo rẹ́kọ́ọ̀dù gbé ìwàásù Arákùnrin Rutherford sétígbọ̀ọ́ ẹnì kan, láàárín ọdún 1936 sí 1939; Apá ọ̀tún: Ilẹ̀ Switzerland

APÁ 1

Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run​—Pípèsè Oúnjẹ Nípa Tẹ̀mí

Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run​—Pípèsè Oúnjẹ Nípa Tẹ̀mí

O RÍ i pé inú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ dùn gan-an bó ṣe wá lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. Ó wá rọra bi ọ́ pé, “Ṣé pé Bíbélì sọ pé a lè gbé nínú Párádísè títí láé, láyé ńbí?” Ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí rẹ́rìn-ín músẹ́, ó ní, “Ó dáa, kí ni Bíbélì tẹ́ ẹ kà yẹn sọ?” Ọ̀rọ̀ yìí wú akẹ́kọ̀ọ́ náà lórí débi pé ó mirí tìyanutìyanu, ó ní, “Ó yà mí lẹ́nu pé kò tiẹ̀ sẹ́ni tó kọ́ mi nírú nǹkan báyìí rí!” O wá rántí pé ó sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn nígbà àkọ́kọ́ tó máa gbọ́ ọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí? Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí. Irú ìrírí bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ ká tún rántí ẹ̀bùn iyebíye tá a rí gbà, ìyẹn ìmọ̀ òtítọ́! Rò ó wò ná: Báwo ni ẹ̀bùn náà tiẹ̀ ṣe tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́? A máa sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè yẹn ní apá yìí. Bí àwa èèyàn Ọlọ́run ṣe ń rí ìlàlóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lóòótọ́. Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí ni Jésù Kristi Ọba Ìjọba náà ti ń rí sí i lójú méjèèjì pé àwa èèyàn Ọlọ́run ń kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 3

Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ Payá

Ṣé ara ète Ọlọ́run ni Ìjọba náà jẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀? Báwo ni Jésù ṣe là wá lóye Ìjọba náà?

ORÍ 4

Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè

Kí ni Ìjọba náà ti ṣe nípa orúkọ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè kópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?

ORÍ 5

Ọba Ìjọba Ọlọ́run Mú Ká Túbọ̀ Lóye Ìjọba Náà

Ní òye tó túbọ̀ ṣe kedere nípa Ìjọba Ọlọ́run, àwọn alákòóso rẹ̀ àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ àti ohun tó gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba náà.