Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

INDONÉṢÍÀ

A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa

Daniel Lokollo

A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1965

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1986

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó fi ìdúróṣinṣin kojú inúnibíni.

NÍ APRIL 14, 1989, mo ń darí ìpàdé kan lọ́wọ́ nílùú Maumere tó wà ní erékùṣù Flores, ṣàdédé ni àwọn aláṣẹ ìjọba kan já wọnú ilé tí wọ́n sì wá mú èmi àti àwọn mẹ́ta míì.

Àwọn tó ń bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n gbìyànjú láti fipá mú wa pé ká kí àsíá orílẹ̀-èdè. Nígbà tá a kọ̀, wọ́n lù wá bí ẹni máa kú, wọ́n tún fi ẹsẹ̀ gbá wa, wọ́n sì sá wa sínú oòrùn fún ọjọ́ márùn-ún. Tó bá dalẹ́, wọ́n á dá wa pa dà sínú ẹ̀wọ̀n kótópó tá a máa sùn. Nígbà tá a bá máa fi débẹ̀, á ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, tí gbogbo ara á sì máa ro wá. Yàtọ̀ síyẹn, yàrá ẹ̀wọ̀n ọ̀hún kéré, ó sì dọ̀tí. Kó sí ẹní, kò sí bẹ́ẹ̀dì, orí sìmẹ́ǹtì lásán la máa ń sùn, nígbà tó bá fi máa di òru, ṣe ni otútù máa ń mú wa. Bẹ́ẹ̀ ni aláṣẹ ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n náà ń rọ̀ wá pé ká sẹ́ ìgbàgbọ́ wa kí wọ́n lè tú wa sílẹ̀, àmọ́ a sọ fún un pé: “Títí tá a máa fi kú, àwa kò ní kí àsíá náà.” Bíi ti àwọn Kristẹni ìṣáájú, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ pé a “jìyà nítorí òdodo.”1 Pét. 3:14.