Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa

Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa

 Ṣé o gbà pé nǹkan máa dáa lọ́jọ́ iwájú? Aráyé ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro lónìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ gbà pé nǹkan ṣì máa dáa. Àmọ́ ká sòótọ́, ṣé ó yẹ ká gbà pé nǹkan ṣì máa dáa? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀la máa dáa.

 Ìlérí wo ni Bíbélì ṣe?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo aráyé ló ń dojú kọ ìṣòro tó le gan-an. Àmọ́, ó tún sọ pé àwọn ìṣòro náà máa dópin láìpẹ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

  •   Ìṣòro: Àìrílégbé

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn.”—Àìsáyà 65:21.

     Ohun tó máa ṣelẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Àwọn èèyàn máa ní ilé tara wọn.

  •   Ìṣòro: Àìríṣẹ́ṣe àti ipò òṣì

     Ohun tí Bíbélì sọ: ‘Àwọn àyànfẹ́ mi máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’—Àìsáyà 65:22.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Gbogbo èèyàn ló máa ní iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn, tó ń gbádùn mọ́ni, tó sì ń mérè wá.

  •   Ìṣòro: Ìwà Ìrẹ́jẹ

     Ohun tí Bíbélì sọ: ‘Àwọn ìjòyè máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.’— Àìsáyà 32:1.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Kò ní sí ẹ̀tanú àti ìrẹ́jẹ mọ́ títí láé. Àwọn èèyàn ò ní máa hùwà àìdáa sáwọn míì torí pé ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwọn tàbí torí pé wọn ò lówó lọ́wọ́. Kò sì ní sí ojúsàájú mọ.

  •   Ìṣòro: Àìrí oúnjẹ tó tó jẹ àti Ebi

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀; ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.”—Sáàmù 72:16.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Gbogbo èèyàn ló máa rí oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ lọ́pọ̀ yanturu. Ebi ò ní pa ẹnikẹ́ni, gbogbo èèyàn á sì máa jẹ́ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù.

  •   Ìṣòro: Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”—Míkà 4:4.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Ọkàn gbogbo èèyàn á balẹ̀ torí pé àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́, àti pé “àwọn olódodo ni yóò jogún ayé.”—Sáàmù 37:10, 29.

  •   Ìṣòro: Ogun

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Àìsáyà 2:4.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Àlàáfíà máa jọba kárí ayé. (Sáàmù 72:7) Kò ní sẹ́ni táá ṣọ̀fọ̀ èèyàn ẹ̀ tó kú sójú ogun, kò sì ní sẹ́ni táá máa wá ibi ìsádi nígbà ogun.

  •   Ìṣòro: Àìsàn àti àrùn

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.’ ”— Àìsáyà 33:24.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Kò sẹ́ni tó máa jẹ́ aláàbọ̀ ara, kò sì sẹ́ni táá ṣàìsàn. (Àìsáyà 35:5, 6) Bíbélì tiẹ̀ ṣèlérí pé “ikú ò ní sí mọ́.”—Ìfihàn 21:4.

  •   Ìṣòro: Bíba àyíká jẹ́

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀, aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.”— Àìsáyà 35:1.

     Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Ilẹ̀ ayé máa di Párádísè àwọn èèyàn á sì máa gbébẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15; Àìsáyà 45:18.

  Ṣé àlá tí kò lè ṣẹ làwọn ìlérí inú Bíbélì?

 Ó lè jọ bẹ́ẹ̀ lójú ẹ. Àmọ́, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì yàtọ̀ sáwọn ìlérí táwọn èèyàn máa ń ṣe. Ọlórun ló ṣe àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì. Kí nìdí tó fi yẹ kíyẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀?

  •   Ọlọ́run ṣeé fọkàn tán. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kò lè parọ́.” (Títù 1:2) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run nìkan ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Àìsáyà 46:10) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run máa ń ṣẹ. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò náà Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?

  •   Ọlọ́run lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro wa. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe “gbogbo ohun tó bá fẹ́.” (Sáàmù 135:5, 6) Lédè míì, kò sóhun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.—Jòhánù 3:16.

 Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé ó wu Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́, tó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí ìṣòro ṣì fi pọ̀ láyé?’ Tó o bá fẹ́ rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

 Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ?

 Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó ti fi Jésù Kristi ṣe Ọba Ìjọba yẹn, ó sì ti fún-un láṣẹ láti bójú tó ayé àtàwọn èèyàn tó ń gbé nínú rẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó mú kí òkun pa rọ́rọ́, ó sì jí àwọn òkú dìde. (Máàkù 4:39; 6:41-44; Lúùkù 4:40; Jòhánù 11:43, 44) Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yẹn jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa ṣe nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

 Ìgbà wo làwọn ìlérí náà máa ṣẹ?

 Láìpẹ́! Kí nìdí tó fi dá wa lójú? Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan táá fi hàn pé kò ní pẹ́ tí Ìjọba Ọlọ́run á fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé. (Lúùkù 21:10, 11) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ní Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

 Báwo làwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí?

 Òǹkọ̀wé Bíbélì kan fi àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe wé “ìdákọ̀ró fún ọkàn” wa. (Hébérù 6:19) Bí ìdákọ̀ró ṣe máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi dúró digbí nígbà ìjì, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlérí inú Bíbélì tó dájú nípa ọjọ́ iwájú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú lónìí. Ìrètí tá a ní yìí ò ní jẹ́ kẹ́rù bà wá, àá sì ní ìlera tó dáa.—1 Tẹsalóníkà 5:8.