Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2017

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Èèyàn Ń Jàǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Kárí Ayé

Àwọn Èèyàn Ń Jàǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Kárí Ayé

DECEMBER 1, 2020

 Ọdọọdún ni ètò Ọlọ́run máa ń pe àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kárí ayé, láti wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà nílùú Patterson, New York. a Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá fún wọn. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn máa ń jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tóótun láti fáwọn ìjọ àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì lókun kárí ayé, ìyẹn á sì jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ará.

 Ibi gbogbo kárí ayé ni ètò Ọlọ́run ti ń pe àwọn ará sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) tó wá láti orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ni wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹtàdínláàádọ́jọ (147) tá a ṣe lọ́dún 2019. Gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń pè wá sílé ẹ̀kọ́ yìí ló wà lẹ́nu àkànṣe ìṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn kan lára wọn ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míì ń ṣe alábòójútó àyíká, míṣọ́nnárì tàbí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

 Káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ rárá la ti máa ń múra sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìrìn Àjò ní Oríléeṣẹ́ (WHQ Travel) máa ń ṣètò báwọn akẹ́kọ̀ọ́ á ṣe wọkọ̀ òfúrufú wá sílé ẹ̀kọ́ náà. Ní ìpíndọ́gba, ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400,000) náírà ni wọ́n fi ṣètò ìrìnnà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá sí kíláàsì kẹtàdínláàádọ́jọ (147) láti orílẹ̀-èdè míì. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó wá láti Solomon Islands wọkọ̀ òfúrufú mẹ́rin kí wọ́n tó dé Patterson, wọ́n sì tún wọkọ̀ òfúrufú mẹ́ta pa dà sílé. Àlọ àtàbọ̀ wọn ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) máìlì! Owó tíyẹn sì ná wa lórí akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900,000) náírà. Ká lè ṣọ́wó ná, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìrìn Àjò máa ń lo ètò orí kọ̀ǹpútà kan láti wá tíkẹ́ẹ̀tì tí kò wọ́nwó. Kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ra tíkẹ́ẹ̀tì náà, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ àti ọ̀pọ̀ oṣù ni ètò orí kọ̀ǹpútà yìí á ṣì tún máa ṣọ́ ìgbà tówó tíkẹ́ẹ̀tì á wálẹ̀ dáadáa ju èyí tí wọ́n kọ́kọ́ rà lọ. Àwọn ará tún máa ń fi àjẹmọ́nú tílé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú fún wọn ṣètọrẹ, torí náà Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìrìn Àjò máa ń lò ó láti fi ra tíkẹ́ẹ̀tì.

 Ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló nílò ìwé àṣẹ kí wọ́n tó lè wọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Torí náà, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní Oríléeṣẹ́ máa ń gbà á fún wọn. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200,000) náírà ni wọ́n máa ń ná lórí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè gba ìwé àṣẹ náà, kí wọ́n sì ṣe àwọn ètò míì tó yẹ.

 Báwo ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí gbà ṣe ń ṣe àwọn ará láǹfààní? Nílẹ̀ Éṣíà, alàgbà kan tó ń jẹ́ Hendra Gunawan wà níjọ kan náà pẹ̀lú tọkọtaya kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Arákùnrin Hendra sọ pé: “A ò ní aṣáájú-ọ̀nà kankan níjọ wa tẹ́lẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí tọkọtaya yìí dé láti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìtara wọn ran àwọn míì nínú ìjọ, débi pé àwọn kan lára wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kódà nígbà tó yá, arábìnrin kan lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run!”

 Ní ọ̀kan lára àwọn Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Éṣíà, Arákùnrin Sergio Panjaitan ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Arákùnrin Sergio sọ pé: “Àwọn nìkan kọ́ ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà ń ṣe láǹfààní, àwa náà ń jàǹfààní ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọ́n ti kọ́ lóòótọ́! Àmọ́ dípò tíyẹn á fi mú kí wọ́n máa gbéra ga, ṣe ni wọ́n ń fi ohun tí wọ́n kọ́ ràn wá lọ́wọ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ káwa náà ran àwọn míì lọ́wọ́.”

 Ibo la ti ń rówó tá a fi ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ yìí? Àwọn nǹkan tẹ́ ẹ fi ń ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn ló mú kó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ lára ìtìlẹyìn yìí lẹ sì ń fi ránṣẹ́ láti ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì donate.ps8318.com. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín ló jẹ́ kí ilé ẹ̀kọ́ yìí ṣeé ṣe, ẹ ṣeun gan-an.

a Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ló ń ṣètò ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ló máa ń kọ́ni nílé ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n tún máa ń pe àwọn míì wá láti wá kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, bákan náà, àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń kọ́ni nílé ẹ̀kọ́ yìí.