Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkọ̀ Ojú Omi Lightbearer Tan Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Dé Ilẹ̀ Éṣíà

Ọkọ̀ Ojú Omi Lightbearer Tan Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Dé Ilẹ̀ Éṣíà

 Ní ọdún 1930 sí ọdún 1934, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì wàásù dé orílẹ̀-èdè Indonesia, Malaysia àti orílẹ̀-èdè tá à ń pè ní Papua New Guinea báyìí. Báwo ni ìhìn rere ṣe máa dé àwọn ilẹ̀ yìí? Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Ọsirélíà (tá à ń pè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia báyìí) ra ọkọ̀ ojú omi kan tó gùn tó mítà mẹ́rìndínlógún (16 mítà) ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà méjìléláàádọ́ta (52). Wọ́n fún un lórúkọ náà, Lightbearer torí pé ọkọ̀ yìí làwọn aṣáájú-ọ̀nà a tó wà nínú rẹ̀ máa fi tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ dé àwọn ilẹ̀ tó jìn gan-an.—Mátíù 5:14-16.

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Orílẹ̀-Èdè New Guinea

 Ní February 1935, àwọn méje tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi yìí gbéra láti àríwá Sydney tó wà ní etíkun Ọsirélíà, wọ́n sì forí lé ìlú Port Moresby ní orílẹ̀-èdè New Guinea. Bí wọ́n ṣe ń tukọ̀ lọ lórí agbami bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pa ẹja, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á dúró ra epo sí ọkọ̀ wọn láwọn èbúté, wọ́n á ra oúnjẹ, wọ́n sì máa ṣe àtúnṣe tó bá yẹ sí ọkọ̀ wọn. Nígbà tó di April 10, 1935, wọ́n tukọ̀ kọjá òkun tó wà ní ìlú Cooktown, ní ìpínlẹ̀ Queensland. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n tan ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà bí wọ́n ṣe forí lé òkìtì ńlá kan tó léwu gan-an tí wọ́n ń pè ní Great Barrier Reef. Ni ọkọ̀ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo kan tó yàtọ̀, ni wọ́n bá pa á. Ṣé kí wọ́n wá pa dà síbi tí wọ́n ti ń bọ̀ ni àbí kí wọ́n ṣì máa tukọ̀ lọ sí New Guinea? Eric Ewins tó jẹ́ ọ̀gákọ̀ sọ pé: “A ò fẹ́ pa dà rárá.” Bí Lightbearer ṣe ń bá ìrìn ẹ̀ lọ nìyẹn, ìgbà tó sì di April 28, 1935 ó gúnlẹ̀ sí ìlú Port Moresby.

Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi Lightbearer, láti apá òsì: William Hunter, Charles Harris, Alan Bucknell (iwájú), Alfred Rowe, Frank Dewar, Eric Ewins, Richard Nutley

 Nígbà tí mẹkáníìkì ń tún ọkọ̀ náà ṣe, gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà ló lọ wàásù nílùú Port Moresby àfi Frank Dewar nìkan tí kò tẹ̀ lé wọn. Ọ̀kan lára wọn sọ pé “aṣáájú-ọ̀nà tó ń ṣiṣẹ́ kára ni” Frank, ó tiẹ̀ sọ pé Frank kó òbítíbitì ìwé, ó fẹsẹ̀ rin nǹkan bí i kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n (32) ìyẹn ogún (20) máìlì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó sì ń bá àwọn ará ibẹ̀ sọ̀rọ̀ níkọ̀ọ̀kan. Nígbà tó ń pa dà bọ̀, ọ̀nà míì ló gbà pa dà, kódà ó gba inú odò kan kọjá níbi tó jẹ́ pé àwọn ọ̀nì ló kún inú ẹ̀ bámú. Ṣùgbọ́n, ó fọgbọ́n ṣe é, ó sì pa dà sínú ìlú láyọ̀ àti àlàáfíà. Iṣẹ́ ìsìn àwọn arákùnrin yìí so èso rere torí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fún láwọn ìtẹ̀jáde wa ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá.

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Erékùṣù Java

 Nígbà tí wọ́n tún ọkọ̀ náà ṣe tán, wọ́n gbéra kúrò nílùú Port Moresby, wọ́n sì forí lé erékùṣù Java tó wà ní Dutch East Indies (èyí tó pọ̀ jù nínú ẹ̀ là ń pè ní Indonesia báyìí). Lẹ́yìn tí wọ́n ti dúró lọ́pọ̀ etíkun kí wọ́n lè ra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, wọ́n dúró ní ìlú Batavia (tá à ń pè ní Jakarta báyìí) ní July 15, 1935.

 Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Charles Harris tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní erékùṣù Java, ó sì ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. b Ó sọ pé: “Láwọn ìgbà yẹn, a kàn máa ń fún àwọn èèyàn láwọn ìtẹ̀jáde wa ni, tá a bá ti ṣe tán, àá lọ sí ìlú míì. Mo máa ń kó àwọn ìtẹ̀jáde wa lédè Lárúbáwá, Chinese, Dutch, Gẹ̀ẹ́sì àti Indonesian dání. Àwọn èèyàn sì máa ń gba àwọn ìwé wa débi pé láàárín ọdún kan péré, mo fi ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún (17,000) síta.”

Lightbearer rèé lórí omi

 Ìjọba orílẹ̀-èdè Netherlands gan-an dá Arákùnrin Charles mọ̀ torí ìtara tó fi ń wàásù. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ọlọ́pàá kan béèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń wàásù ní erékùṣù Java pé, Ẹlẹ́rìí mélòó ló ń wàásù ní Ìlà-oòrùn Java níbí tí Charles wà. Arákùnrin náà fèsì pé “Ẹyọ kan ni.” Ni ọlọ́pàá náà bá jágbe mọ́ ọn pé: “O sì rò pé mo lè gba ohun tó o sọ yẹn gbọ́, àbí? Pẹ̀lú adúrú ìwé yín tẹ́ ẹ pín fáwọn èèyàn ìlú yìí, ó ní láti jẹ́ pé òbítíbitì àwọn ará yín ló ń ṣiṣẹ́ níbí.”

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Singapore àti Malaysia

 Lightbearer tún gbéra kúrò ní Indonesia, ó sì dé Singapore ní August 7. Bí wọ́n ṣe ń dúró láwọn etíkun kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ làwọn arákùnrin yìí ń tan àwọn àsọyé tá a ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ fáwọn èèyàn, ọkọ̀ ojú omi yìí sì ní ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tóhùn ẹ̀ rinlẹ̀ dáadáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì tẹ́tí sí ìhìn rere lọ́nà yìí. Kódà, ìwé ìròyìn kan tó n jẹ́ Singapore Free Press ròyìn pé: “Àwọn èèyàn máa ń gbọ́ ohùn tó ń dún ròkè lálá lórí omi . . . ní alẹ́ Wednesday,” ó wá fi kún un pé: “Mánigbàgbé làwọn àsọyé . . . tó máa ń dún . . . látinú ọkọ̀ ojú omi ‘Lightbearer,’ tó máa ń gbé àwọn àsọyé Watch Tower tí wọ́n ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ sáfẹ́fẹ́ ní Singapore látìgbà tí ọkọ̀ náà tí gúnlẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé: ‘Láwọn ìgbà tí ojú ọjọ́ bá dáa, àwọn èèyàn tó wà ní nǹkan bíi máìlì méjì sí mẹ́ta [ìyẹn kìlómítà mẹ́ta sí mẹ́rin] máa ń gbọ́ àwọn àsọyé yìí ketekete.’

 Nígbà tí Lightbearer dé Singapore, Arákùnrin Frank Dewar kúrò láàárín wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tuntun. Ohun tó sọ lẹ́yìn ìgbà náà rèé: “A bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun lórílẹ̀-èdè Singapore bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ ojú omi la fi ṣe ilé. Nígbà tí àkókò tó láti gbéra lọ sí ìlú míì, Eric Ewins sọ ohun kan tó yà mí lẹ́nu, tó sì bá mi lójijì. Ó sọ pé: ‘Ibi a wí la dé yìí o, Frank, ìwọ lo sọ pé Siam (tá à ń pè ní Thailand báyìí) lo fẹ́ fi ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù ẹ̀. A ò lè gbé ẹ kọjá ibí yìí. Wá máa lọ o!’ Mo mi kanlẹ̀, àyà mi sì já, mo wá sọ pé: ‘Àmọ́, mi ò mọ bí màá ṣe dé ilẹ̀ Siam látibí!’” Eric sọ fún Frank pé tó bá ti dé Kuala Lumpur tá à ń pè ní Malaysia báyìí, ó máa wọ ọkọ̀ ojú irin táá gbé ẹ débẹ̀. Frank ṣègbọràn, ó sì lọ sí Kuala Lumpur, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, ó gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Thailand. c

 Lightbearer ṣe dé etíkun ìwọ̀ oòrùn Malaysia, ó dúró ní Johore Bahru, Muar, Malacca, Klang, Port Swettenham (tá à ń pè ní Port Klang báyìí) àti Penang. Bí wọ́n ṣe ń dé etíkun kọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń fi ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn tó wà nínú ọkọ̀ náà gbé àwọn àsọyé Bíbélì tá a ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ sáfẹ́fẹ́. Arákùnrin Jean Dejschamp tó ń sìn ní Indonesia nígbà yẹn sọ pé: “Àwọn èèyàn tẹ́tí sílẹ̀ ju bá a ṣe rò lọ.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbé àwọn àsọyé náà sáfẹ́fẹ́, wọ́n á wá lọ bá àwọn èèyàn, wọ́n á sì fún wọn láwọn ìtẹ̀jáde wa.

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Sumatra

 Láti Penang, ọkọ̀ náà gba orí òkun tí wọ́n ń pè ní Strait of Malacca kọjá sí Medan, ó sì forí lé Sumatra (tó jẹ́ apá kan Indonesia báyìí). Eric Ewins sọ pé: “A gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa ní agbègbè Medan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì tẹ́tí sí ìhìn rere tá a wàásù rẹ̀.” Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìtẹ̀jáde ni wọ́n fún àwọn èèyàn níbẹ̀.

 Lightbearer tún gbéra, ó di apá ìlà oòrùn, àwọn tó wà nínú ẹ̀ sì wàásù láwọn etíkun táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó tó wà ní apá ìlà oòrùn ìlú Sumatra. Nígbà tó sì di November 1936, ọkọ̀ náà pa dà sí Singapore, ibẹ̀ sì ni Eric Ewins dúró sí. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà ló fẹ́ Arábìnrin Irene Struys, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Singapore. Eric àti Irene sì ń bá iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà lọ ní Sumatra. A jẹ́ pé Lightbearer nílò ọ̀gákọ̀ tuntun nìyẹn.

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Borneo

 Norman Senior ni ọ̀gákọ̀ tuntun náà, ẹni tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń tukọ̀ òkun. Ìlú Sydney ló ti wá, ó sì gúnlẹ̀ ní January 1937. Ni wọ́n bá gbéra láti Singapore, ó di Borneo àti Celebes (tá à ń pè ní Sulawesi báyìí), ṣàṣà sì nibi tí wọn ò wàásù dé níbẹ̀ débi pé wọ́n fẹsẹ̀ rìn tó irínwó lé ní ọgọ́rin (480) kìlómítà, ìyẹn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) máìlì.

 Nígbà tí Lightbearer dé etíkun Samarinda tó wà ní Borneo, ọ̀gá àgbà tó ń bójú tó etíkun náà ò gbà káwọn arákùnrin yìí wàásù fáwọn èèyàn ibẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Arákùnrin Norman ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa fún un, ó gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀, kódà, ó gba àwọn ìtẹ̀jáde wa.

 Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí àlùfáà kan ní kí Norman wá wàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì òun. Dípò kó wàásù fúnra rẹ̀, ṣe ló tan àwọn àsọyé Bíbélì márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn, àlùfáà náà sì nífẹ̀ẹ́ sáwọn ohun tó gbọ́. Ó tiẹ̀ gba àwọn ìtẹ̀jáde wa, ó sì kó o fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àlùfáà yìí nìkan ló yàtọ̀, ṣe ni gbogbo àwọn àlùfáà tó kù ń bínú burúkú burúkú sí iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Wọ́n kórìíra bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń fìtara wàásù. Kódà, inú bí wọn débi pé wọ́n fúngun mọ́ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n fòfin de Lightbearer kó má bàá dé àwọn èbúté tó kù.

Àwọn ibi tí ọkọ̀ ojú omi Lightbearer dé pẹ̀lú orúkọ tí wọ́n ń pè wọ́n nígbà yẹn

Wọ́n Pa Dà sí Ọsirélíà

 Nígbà tó di December 1937, Lightbearer pa dà sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà torí ohun tí àwọn àlùfáà ṣe yìí. Gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi yìí sì dúró ní Sydney Harbor kí wọ́n lè lọ sí àpéjọ agbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa wáyé ní April 1938. Nígbà yẹn, ó ti lé ní ọdún mẹ́ta tí Lightbearer ti kúrò ní Sydney. Wọ́n ta ọkọ̀ náà ní nǹkan bí ọdún 1940 sí 1944, ní kété lẹ́yìn tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí ní Ọsirélíà. Arákùnrin Ewins sọ pé: “Ọkọ̀ náà ti ṣe gudugudu méje àti yààyàà mẹ́fà,” ó sọ síwájú sí i pé, àwọn ọdún tí òun fi ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ọkọ̀ Lightbearer làwọn ọdún tí òun “láyọ̀ jù lọ.”

Mánigbàgbé ni Ọkọ̀ Lightbearer

 Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi Lightbearer fún irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó láwọn èrò tó pọ̀ gan-an tí wọ́n ń gbé ibẹ̀. Láìka àtakò sí, iṣẹ́ wọn so èso nígbà tó yá. (Lúùkù 8:11, 15) Kódà ní báyìí, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) ló ń wàásù láwọn ilẹ̀ náà. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà làwọn arákùnrin onítara yẹn jẹ́ fún wa lónìí, a ò sì lè gbàgbé orúkọ tó bá a mu gẹ́lẹ́ tí wọ́n fún ọkọ̀ ojú omi náà!

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà.

b Ìtàn ìgbésí ayé Charles Harris wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 1994.

c Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1991, ojú ìwé 187.