Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 107

Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa

Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa

(1 Jòhánù 4:19)

  1. 1. Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Jèhófà kọ́ wa

    Ló yẹ ká máa tẹ̀ lé.

    Gbogbo ‘hun tó ṣe fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa,

    Ká fara wé e; ká fìfẹ́ hàn.

    Ó fún wa lọ́mọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo;

    Ó kú fẹ́ṣẹ̀ wa kí a lè rí ìyè.

    Kò sóhun tá a lè fi wé ìfẹ́ ńlá yìí!

    Ìfẹ́ yìí ga; Bàbá nífẹ̀ẹ́ wa.

  2. 2. Tá a bá fara wé e, ìfẹ́ wa yóò jinlẹ̀,

    Yóò máa tuni lára.

    Yóò jẹ́ ká lè máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo

    Ẹgbẹ́ ará, tàgbà tèwe.

    Ó ṣe pàtàkì ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,

    Ká sì tún rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa.

    Yóò jẹ́ ká lè máa dárí ji ara wa;

    Ìyẹn fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ tòótọ́.

  3. 3. Ìfẹ́ òtítọ́ tá a ní ló so wá pọ̀

    Bí ọmọ ìyá kan.

    Bàbá wa ọ̀run fìfẹ́ ké sí wa pé:

    “Tọ́ ọ wò kóo rí ìfẹ́ tòótọ́.”

    Ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtẹ̀mí mímọ́ rẹ̀

    Ṣèrànwọ́ fún wa, ká lè wà níṣọ̀kan.

    Ìfẹ́ àárín wa sì ń rán wa létí pé

    Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́.