Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 128

Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin

Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin

(Mátíù 24:13)

  1. 1. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé

    A nílò ‘faradà.

    Ojúlówó ni ìfẹ́ wa,

    Ẹ̀kọ́ wa jinlẹ̀ púpọ̀.

    Àwọn ìdánwò ‘gbàgbọ́ wa,

    Ń mú ká lè fẹsẹ̀ múlẹ̀.

    Kígbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀,

    Ọjọ́ Jèhófà dé tán.

  2. 2. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà

    Kò gbọ́dọ̀ tutù láé.

    Bá a ti ń dojú kọ àdánwò,

    Má ṣe bẹ̀rù, má fòyà.

    Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Jáà,

    Yóò mú kó o lè fara dà á.

    Ìgbàgbọ́ rẹ máa lágbára

    Tó o bá lè ní ‘faradà.

  3. 3. Mọ̀ dájú pé àwọn tó bá

    Fara dà á dé òpin

    Ni yóò la ètò búburú

    Ayé Sátánì kọjá

    Sínú ayé tuntun tó ń bọ̀,

    Orúkọ wọn yóò tàn yòò.

    Máa bá a lọ ní fífara dà á

    Kó o lè gba adé ògo.