Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 31

Bá Ọlọ́run Rìn!

Bá Ọlọ́run Rìn!

(Míkà 6:8)

  1. 1. Fìrẹ̀lẹ̀ bá Ọlọ́run rìn;

    Sún mọ́ ọn, kó o sì gbára lé e.

    Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà,

    Ó sì máa fún ẹ lókun.

    Tó o bá rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

    Kò ní jẹ́ kó o ṣìnà.

    Tó o bá ń ṣègbọràn s’Ọ́lọ́run,

    Á tọ́ ẹ sọ́nà ìyè.

  2. 2. Fìwà mímọ́ b’Ọ́lọ́run rìn;

    Fọkàn sí ohun mímọ́.

    Kò sí bí àdánwò ṣe fẹ́ le tó,

    Yóò jẹ́ kó o lè fara dàá.

    Ohunkóhun tó yẹ fún ìyìn,

    Tó sì jẹ́ òtítọ́

    Ni kó o máa rò nígbà gbogbo;

    Jáà yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.

  3. 3. Fi ayọ̀ bá Ọlọ́run rìn;

    Máa yọ̀ pó o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀.

    Dúpẹ́ fún gbogbo ẹ̀bùn tó fún ọ

    Àti bó ṣe ń bù kún ọ.

    Bóo ṣe ń bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn,

    Máa fayọ̀ kọrin sí i.

    Èyí yóò jẹ́ káráyé mọ̀

    Pé Jèhófà lò ń bá rìn.