Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 38

Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

(1 Pétérù 5:10)

  1. 1. Ó nídìí t’Ọ́lọ́run fi jẹ́ kó o rí òótọ́,

    Tó sì mú ọ wá sínú ìmọ́lẹ̀.

    Ó rọ́kàn rẹ, ó rí gbogbo bó o ṣe ńsapá

    Kóo lè sún mọ́ ọn, kó o lè ṣohun tó tọ́.

    O ṣèlérí fún un pé wàá ṣèfẹ́ rẹ̀.

    Ó dájú pé yóò máa ràn ọ́ lọ́wọ́.

    (ÈGBÈ)

    Ó fẹ̀jẹ̀ Jésù rà ọ́;

    ti Jèhófà ni ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,

    yóò fún ọ lágbára.

    Yóò máa tọ́ ẹ sọ́nà,

    yóò sì máa dáàbò bò ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,

    yóò fún ọ lágbára.

  2. 2. Ọlọ́run fọmọ rẹ̀ rúbọ nítorí rẹ,

    Torí Ó fẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí.

    B’Ọ́lọ́run kò ṣe fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dù ọ́,

    Kò ní ṣàì fún ọ lókun tóo nílò.

    Yóò rántí ìgbàgbọ́ àtìfẹ́ rẹ;

    Ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ó fẹ̀jẹ̀ Jésù rà ọ́;

    ti Jèhófà ni ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,

    yóò fún ọ lágbára.

    Yóò máa tọ́ ẹ sọ́nà,

    yóò sì máa dáàbò bò ọ́.

    Yóò fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,

    yóò fún ọ lágbára.