Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 6

Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run

Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run

(Sáàmù 19)

  1. 1. Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà táà ńrí

    Kéde ògo rẹ̀ gan-an

    lójú òfuurufú.

    Ojoojúmọ́ ni wọ́n ńfìyìn fún ọ,

    Ìràwọ̀ ń fagbára rẹ hàn,

    Ìfẹ́ àtọgbọ́n rẹ.

  2. 2. Òfin rẹ pé, ó ń mú káyé wa dára.

    Tọmọdé tàgbà ni

    o sì ń fi ṣamọ̀nà.

    Ìṣàkóso rẹ tọ́, òdodo ni.

    Òfin rẹ mọ́, Ọ̀rọ̀ rẹ ń ṣẹ,

    Wọ́n ńṣe wá láǹfààní.

  3. 3. Àwọn òfin rẹ máa wúlò títí láé.

    Tí a bá ń pa wọ́n mọ́,

    wọ́n máa dáàbò bò wá.

    Èyí ń fi hàn pé a níbẹ̀rù rẹ.

    Ògo, iyì, ọlá yẹ ọ́;

    A gbórúkọ rẹ ga.