Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 68

Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà

Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà

(Mátíù 13:4-8)

  1. 1. Ọ̀gá wa ń pè ọ́ pé kóo máa bọ̀,

    Kó o wá ṣe nínú iṣẹ́ rẹ̀.

    Fọkàn balẹ̀, yóò tọ́ ẹ sọ́nà,

    Ó sì tún máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́.

    Inú ọkàn àwọn onírẹ̀lẹ̀

    Nirúgbìn òótọ́ ti máa ń hù.

    Torí náà, rí i pé o sa gbogbo ‘pá rẹ

    Kó o lè ṣiṣẹ́ tá a yàn fún ọ yìí.

  2. 2. Tíṣẹ́ rẹ bá máa sèso rere,

    Nígbà míì, ọwọ́ rẹ ló wà.

    Fìfẹ́ kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ

    Kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òtítọ́.

    Kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa kojú ‘ṣòro

    Àt’àdánwò tó bá yọjú.

    Inú rẹ máa dùn tó o bá rí bí wọ́n ṣe

    Ń fi òótọ́ tí wọ́n ń kọ́ yìí sílò.