Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì kò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù Kristi fún wa ní pàtó, àwọn ìwé tá a tọ́ka sí náà fi hàn bẹ́ẹ̀:

  •   “Kò sí ẹni tó mọ ọjọ́ tí wọ́n bí Kristi.”—Ìwé New Catholic Encyclopedia.

  •   “Kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n bí Kristi.”—Ìwé Encyclopedia of Early Christianity.

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò dáhùn ìbéèrè náà, ‘Ìgbà wo ni wọ́n bí Jésù?’ ní tààràtà, síbẹ̀, ó sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì kan tó bá ìgbà tí wọ́n bí Jésù rìn tó jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé oṣù December 25 kọ́ ni wọ́n bíi.

Kì í ṣe ìgbà òtútù

  1.   Ìforúkọsílẹ̀. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n bí Jésù, Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ kan pé kí àwọn èèyàn ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé forúkọ sílẹ̀.” Ńṣe ni olúkúlùkù á lọ forúkọ sílẹ̀ ní ‘ìlú tirẹ̀,’ èyí á sì gba ìrìn-àjò ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Lúùkù 2:1-3) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí ètò owó orí àti bí wọ́n ṣe máa rí àwọn èèyàn kó sẹ́nu iṣẹ́ ológun ni wọ́n ṣe pàṣẹ yìí, àwọn kan sì lè má fara mọ́ ọn, kò sì dájú pé Ọ̀gọ́sítọ́sì á fẹ́ ṣe ohun táá túbọ̀ bí àwọn èèyàn nínú nípa fífi tipátipá mú ọ̀pọ̀ lára wọn rin ìrìn-àjò ọ̀nà jíjìn nígbà òtútù.

  2.   Àwọn àgùntàn. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn “ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” (Lúùkù 2:8) Ìwé Daily Life in the Time of Jesus sọ pé ìta gbalasa ni àwọn agbo ẹran máa ń wà láti “ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrékọjá [ìparí oṣù March]” sí àárín oṣù November. Ìwé náà tún sọ pé: “Abẹ́lé ni àwọn agbo ẹran máa ń wà nígbà òtútù; kókó yìí nìkan ti tó láti fi mọ̀ pé ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọdún Kérésìmesì, nígbà òtútù, kò lè tọ̀nà, níwọ̀n bí ìwé Ìhìn Rere ti sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà ní pápá lákòókò yẹn.”

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìwọ́wé

 A lè fojú bu ìgbà tí wọ́n bí Jésù tá a bá ka ọjọ́ orí rẹ̀ sẹ́yìn láti ìgbà tó kú, ìyẹn ní ọjọ́ Ìrékọjá, nígbà ìrúwé Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Jòhánù 19:14-16) Ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ni Jésù nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó fi ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ ṣe. Torí náà, ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìwọ́wé ọdún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bíi.—Lúùkù 3:23.

Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe Kérésìmesì ní December 25?

 Nígbà tí kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé oṣù December 25 ni wọ́n bí Jésù, kí wá nìdí tí wọ́n fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì ní December 25? Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ló yan December 25 kó lè “bọ́ sí ọjọ́ ayẹyẹ àwọn ará Róòmù abọ̀rìṣà tí wọ́n fi ń sàmì sí ‘ọjọ́ ìbí oòrùn tí a kò lè ṣẹ́gun,’” tí wọ́n máa ń ṣe nígbà òtútù. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Encyclopedia Americana ṣe sọ, ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé ìdí táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé “kí ẹ̀sìn Kristẹni lè túbọ̀ nítumọ̀ sí àwọn abọ̀rìṣà tó di Kristẹni.”