Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Èṣù Ló Ń Fa Gbogbo Ìjìyà?

Ṣé Èṣù Ló Ń Fa Gbogbo Ìjìyà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì Èṣù wà lóòótọ́, ó dà bí olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó lágbára, ó sì ń lo ‘àwọn àmì irọ́’ àti “ẹ̀tàn” láti mú àwọn èèyàn ṣe ohun tó fẹ́. Kódà Bíbélì sọ pé, ó máa ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 11:14) Àwọn nǹkan tí Èṣù ń bà jẹ́ la fi mọ̀ pé ó wà lóòótọ́.

 Àmọ́, Èṣù kọ́ ló ń fa gbogbo ìjìyà tó ń bá aráyé. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi lè yan ohun tá a máa ṣe, yálà búburú tàbí rere. (Jóṣúà 24:15) Bí a bá sì ṣe ìpinnu tí kò dára, ohun tí kò dára ló máa yọrí sí.—Gálátíà 6:7, 8.