Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn Wọn?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn Wọn?

 Ọ̀pọ̀ èèyàn ka àgbélébùú sí àmì tó wà fún ẹ̀sìn Kristẹni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ Kristẹni, a kì í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wa. Kí nìdí?

 Ìdí kan ni pé Bíbélì ò sọ pé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí, àmọ́ ohun tó sọ ni pé orí òpó igi ló kú sí. Ohun míì ni pé Bíbélì kìlọ̀ gidigidi fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “sá fún ìbọ̀rìṣà,” ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn.—1 Kọ́ríńtì 10:14; 1 Jòhánù 5:21.

 Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tòótọ́ la máa fi dá ojúlówó ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀, kì í ṣe àgbélébùú, àwòrán tàbí ère èyíkéyìí.