Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Èmi àti Bàbá Mi Pa Dà Rẹ́

Èmi àti Bàbá Mi Pa Dà Rẹ́
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1954

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: Philippines

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Mo jìnnà sí bàbá mi torí ìwà ipá tí wọ́n ń hù sí wa

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Omi kan wà tó máa ń tú yàà nítòsí ìlú Pagsanjan lórílẹ̀-èdè Philippines. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọbẹ̀, wọ́n sì máa ń fẹ́ wá gbafẹ́ níbẹ̀. Ibẹ̀ ni bàbá mi, Nardo Leron, dàgbà sí, wọn ò sì ní lọ́wọ́. Ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n rí láàárín àwọn tó ń ṣèjọba, àwọn ọlọ́pàá àti níbi iṣẹ́ wọn ká wọn lára gan-an, ó sì bí wọn nínú.

 Àwa mẹ́jọ làwọn òbí mi bí, wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ wá. Wọ́n sábà máa ń fi àwa nìkan sílẹ̀ nílé fọ́pọ̀ ọjọ́, wọ́n á lọ máa bójú tó oko tí wọ́n dá sáwọn àgbègbè olókè. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé èmi àti Rodelio ẹ̀gbọ́n mi la máa bójú tó ara wa, ebi sì sábà máa ń pa wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ṣì kéré, a kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè ṣeré bíi tàwọn ọmọdé yòókù. Àtọmọ ọdún méje ni ìkọ̀ọ̀kan àwa ọmọ ti ń ṣiṣẹ́ lóko, àá di àgbọn kún inú àpò, ó sì máa ń wúwo gan-an. Àá wá máa gbé e gba àwọn ọ̀nà olókè. Tí ẹrù kan bá ti wúwo ju ohun tá a lè gbé lọ, ó di dandan pé ká máa wọ́ ọ.

 Ó máa ń dùn wá pé dádì wa máa ń lù wá, àmọ́ a máa ń mú un mọ́ra. Ṣùgbọ́n kì í dùn wá tó ìgbà tá a bá rí i tí wọ́n ń lu mọ́mì wa. A gbìyànjú pé kí wọ́n má lù wọ́n mọ́, àmọ́ apá wa ò ká wọn. Èmi àti Rodelio ẹ̀gbọ́n mi wá gbìmọ̀ pọ̀ pé tá a bá ti dàgbà, ṣe la máa pa dádì wa. Ó wù mí gan-an pé kó jẹ́ bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa la ní!

 Ìwà ipá tí dádì mi ń hù múnú bí mi gan-an débi pé mo kó kúrò nílé lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14). Ìta ni mò ń sùn láwọn àkókò kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í mugbó. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wa ọkọ̀ ojú omi, mo fi ń gbé àwọn tó wá gbafẹ́ lọ síbi omi tó ń tú yàà nílùú wa.

 Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, mo wọ yunifásítì nílùú Manila. Àmọ́ torí pé mo máa ń rìnrìn àjò pa dà sílùú Pagsanjan lópin ọ̀sẹ̀, mi kì í sábà ráyè kàwé. Ìgbésí ayé mi ò tiẹ̀ wá nítumọ̀ rárá, igbó tí mò ń mu ò sì kápá àìbalẹ̀ ọkàn tí mò ń ní. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oríṣiríṣi oògùn olóró, bíi kokéènì àti heroin. Oògùn olóró tí mò ń lò sábà máa ń tì mí sí ìṣekúṣe. Ipò òṣì ń bá àwọn tó wà láyìíká mi fà á, wọ́n ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, ìyà sì ń jẹ wọ́n. Inú ìjọba máa ń bí mi torí mo gbà pé àwọn ló fà á. Mo máa ń bi Ọlọ́run pé, “Kí ló dé táyé rí báyìí?” Àmọ́ mi ò rí ìdáhùn kankan nínú oríṣiríṣi ẹ̀sìn tí mo ti lọ wádìí. Mo bá tún tẹra mọ́ oògùn olóró tí mò ń lò kí n lè fi pàrònú rẹ́.

 Lọ́dún 1972, àwọn ọmọ iléèwé lórílẹ̀-èdè Philippines ṣètò láti wọ́de torí wọn ò fara mọ́ ohun tíjọba ń ṣe. Èmi náà bá wọn wọ́de lọ́jọ́ kan, la bá fìjà pẹ́ẹ́ta níbẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá kó ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ yẹn, nígbà tó sì dẹ̀yìn ọ̀pọ̀ oṣù, àwọn ológun fi òfin lọ́lẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

 Bí mo tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sùnta nìyẹn, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹ̀rù àwọn aláṣẹ ń bà mí torí bí mo ṣe bá àwọn èèyàn dìtẹ̀ síjọba. Kí n lè máa rówó ra oògùn olóró tí mò ń lò, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jalè, nígbà tó sì yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn olówó àtàwọn àjèjì ṣiṣẹ́ ibi. Ẹ̀mí mi ò tiẹ̀ wá jọ mí lójú rárá.

 Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ mọ́mì mi àti àbúrò mi ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú bí dádì mi gan-an, wọ́n sì dáná sun ìwé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ àwọn méjèèjì ò jáwọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá, wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá dádì mi sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé lọ́jọ́ iwájú, ìdájọ́ òdodo máa gbilẹ̀ kárí ayé. (Sáàmù 72:​12-​14) Ohun tí wọ́n sọ yẹn wọ dádì mi lọ́kàn gan-an débi pé wọ́n pinnu pé àwọn máa wádìí bóyá òótọ́ ni. Nígbà tí wọ́n wonú Bíbélì fúnra wọn, wọ́n rí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ìjọba rere máa wà, àmọ́ kò mọ síbẹ̀, wọ́n tún rí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn ọkọ àtàwọn bàbá máa ṣe. (Éfésù 5:​28; 6:4) Kò pẹ́ sígbà yẹn tí àwọn àti gbogbo àwọn àbúrò mi yòókù àti ẹ̀gbọ́n mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí pé ọ̀nà tèmi ti jìn sílé, mi ò mọ gbogbo ohun tó ń lọ rárá.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Nígbà tó di ọdún 1978, mo kó lọ sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Nǹkan ń lọ bó ṣe yẹ lórílẹ̀-èdè yẹn, ọrọ̀ ajé sì ń lọ dáadáa, àmọ́ síbẹ̀ ọkàn mi ò balẹ̀. Mi ò jáwọ́ nínú ọtí àti oògùn olóró tí mò ń lò. Lápá ìparí ọdún yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé mi. Mo fẹ́ràn ohun tí wọ́n fi hàn mí nínú Bíbélì pé àlàáfíà máa jọba láyé lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí àtibá wọn da nǹkan pọ̀.

 Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí mo lọ lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan lórílẹ̀-èdè Philippines. Àwọn ọmọ ìyá mi ròyìn fún mi pé dádì wa ti sapá gan-an, wọ́n sì ti yíwà sí rere, àmọ́ ọgbẹ́ tó ti wà lọ́kàn mi ò tiẹ̀ jẹ́ kí n fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú wọn rárá.

 Àbúrò mi obìnrin fi Bíbélì ṣàlàyé fún mi nípa ìdí tí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ tó báyìí láyé. Ó yà mí lẹ́nu pé ọmọ tí ò tíì pé ogún ọdún, tí ò tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ bílé ayé ṣe rí, lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Kí n tó kúrò lọ́dọ̀ wọn, dádì mi fún mi níwèé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. a Wọ́n ní: “Fira ẹ lọ́kàn balẹ̀. Ìwé yìí máa jẹ́ kó o rí nǹkan tó ò ń wá.” Wọ́n rọ̀ mí pé tí mo bá ti pa dà sí Ọsirélíà, kí n wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ.

 Mo ṣe ohun tí dádì mi ní kí n ṣe, mo sì rí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítòsí ilé mi ní Brisbane. Mo gbà kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, irú bíi Dáníẹ́lì orí keje àti Aísáyà orí kẹsàn-án jẹ́ kí n rí i pé ìjọba Ọlọ́run, tí ìwà ìbàjẹ́ kankan ò sí nínú ẹ̀, ló máa ṣàkóso lórí wa lọ́jọ́ iwájú. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé a máa gbádùn Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Mo fẹ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà mí, àmọ́ mo rí i pé àfi kí n máa ṣàkóso bí nǹkan ṣe máa ń rí lára mi, kí n jáwọ́ nínú ọtí àti oògùn olóró tí mò ń lò, kí n má sì ṣèṣekúṣe mọ́. Bí èmi àti ọmọbìnrin tá a jọ ń gbé ṣe pín yà nìyẹn, mo sì jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tí mò ń hù. Bí mo ṣe túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, mo gbàdúrà sí i pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá kù.

 Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé òótọ́ ni pé ohun tí mò ń kọ́ lè yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà pátápátá. Bíbélì sọ pé tá a bá sapá, a lè gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀. (Kólósè 3:​9, 10) Bí mo ṣe ń gbìyànjú láti ṣe é, mo rí i pé ó lè jẹ́ òótọ́ lohun tí mo gbọ́ pé ìwà dádì mi ti yí pa dà. Dípò bí mo ṣe kórìíra wọn, tínú wọn sì ń bí mi, ṣe ni mo fẹ́ kí àárín wa pa dà gún. Nígbà tó yá, mo dárí ji dádì mi, mo sì fa ìkórìíra tí mo ti ní sí wọn láti kékeré tu kúrò lọ́kàn mi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo sábà máa ń tẹ̀ lé àwọn míì lọ hùwà burúkú. Ohun tí Bíbélì sì kì wá nílọ̀ nípa ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi, torí pé àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tí mò ń bá rìn kó mi ṣìnà. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́ mo ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti tún ayé mi ṣe. Àárín wọn náà ni mo ti rí Loretta, ìyàwó mi àtàtà. Àwa méjèèjì jọ ń kọ́ àwọn míì nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Èmi, ìyàwó mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ ń jẹun

 Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì tó yí ìgbésí ayé dádì mi pa dà, mi ò rò ó pé wọ́n lè di irú èèyàn báyìí, wọ́n ti di ọkọ rere fún mọ́mì mi, wọ́n nírẹ̀lẹ̀, Kristẹni ẹlẹ́mìí àlàáfíà sì ni wọ́n. Nígbà tá a ríra lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, tí mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1987, ṣe ni dádì mi dì mọ́ mi. Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi nìyẹn láyé mi!

 Ó lé ní ọdún márùndínlógójì (35) báyìí tí dádì mi àti mọ́mì mi ti jọ ń fi ìrètí tó wà nínú Bíbélì han àwọn míì. Dádì mi wá dẹni tí kì í fiṣẹ́ ṣeré, wọ́n láàánú èèyàn, àwọn èèyàn sì mọ̀ wọ́n sí ẹni tó máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Láwọn ọdún yẹn, mo kà wọ́n sí gan-an, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ohun àmúyangàn ló jẹ́ fún mi pé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ọmọ wọn! Àmọ́ wọ́n ṣaláìsí lọ́dún 2016. Àárò wọn sọ mí gan-an, torí mo mọ̀ pé ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì mú kí èmi àtiwọn ṣe àyípadà tó lágbára sí ìwà wa. Kò sí ìkórìíra kankan mọ́ lọ́kàn mi, bó ti wù kó kéré mọ. Mo sì dúpẹ́ gan-an pé mo wá mọ Bàbá mi ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run, tó ṣèlérí pé òun máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa wàhálà nínú ìdílé káàkiri ayé.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.